Sunday Igboho: Agbẹjọ́rò DSS wọ ọkọ̀ "One Chance" làwọn adigunjalè bá jí fáìlì ẹjọ 'Igboho' gbé lọ́wọ́ rẹ̀?

Awọn ọmọlẹyin Sunday Igbohun tawọn DSS mu ni ile rẹ.

Oríṣun àwòrán, others

Agbẹjọro fun ajọ ọtẹlẹmuyẹ Naijiria DSS to n ṣẹjọ pẹlu ajafẹtọmniyan Sunday Igboho ti sọ fun adajọ pe iwe faili ẹjọ awọn amugbalẹgbẹ Igboho ti di awati.

Agbẹjọro Idowu Awo sọ pe awọn adigunjale lo gba faili naa lọwọ akẹgbẹ oun to wọ mọtọ akero awọn oni One Chance.

O sọ fun adajọ Obiora Egwuatu to n gbẹjọ naa pe awọn nkan ini rẹ mii to fi mọ iwe ipẹjọ ni awọn olubi wn yi ji gbe lọ.

Ọkan lara awọn agbẹjọro fun awọn mejila ti awọn agbofinro DSS ko nile Oloye igboho naa, Amofin Pẹlumi Ọlajẹmgbesi to fi idi iroyin yii mulẹ fun BBC News Yoruba pe ohun ti agbẹjọro fun DSS sọ niwaju ile ẹjọ naa jẹ kayefi nla gba ti o si doju tini gan ni.

O ni bi awọn ole ba lee digun ja awọn oṣiṣẹ DSS ni ilu Abuja tii ṣe olu ilu Naijiria, ireti kekere lo wa fun mẹkunu ni eyi tumọ si.

"ohun ti awọn oṣiṣẹ DSS sọ pe awọn adigunjale kọ luwọn ti wọn si ja wọn lole debi pe iwe ẹjọ si sọnu lasiko ti wọn n bọ nile ẹjọ jẹ idojuti gbaa."

Àkọlé fídíò, Lóòtọ́ orin mi àti Lagbaja jọra ṣùgbọ́n ìyàtọ̀ díẹ̀ wà níbẹ - Labule

Ẹjọ ti wọn n ṣe lori ọrọ to wa nilẹ yi ni eleyi to ni ṣe pẹlu fifi ẹtọ awọn amugbalẹgbẹ Igboho ti DSS fẹ tẹju rẹ mọlẹ rinlẹ fun wọn.

Lẹyin alaye to ṣe fun adajọ, o wa beere fun isunsiwaju ẹjọ naa.

Ninu awọn amugbalẹgbẹ Igboho tio DSS mu, mẹwaa ni wn ti tu sil lẹyin ti ile ẹjọ gba beeli wọn.

Ṣaaju ni ile ẹjọ wọgile ẹbẹ ti DSS bẹ pe ki wọn da awọn mẹrin ninu awọn amugbalẹgbẹ wọnyi pada si ahamọ.