Sunday Igboho aides: Adájọ́ kọ̀ láti dáwọn ọmọlẹ́yìn Igboho mẹ́rin padà s'látìmọ́lé DSS

Sunday Igboho ati awọn ọmọlẹyin rẹ

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

Ile ẹjọ giga ijọba apapọ niluu Abuja ti fagile ẹgbẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS to ni ki wọn dawọn ọmọlẹyin Sunday Igboho to ṣẹṣẹ gbomina pada si atimọle.Adájọ́ pàṣẹ ìtúsílẹ̀ mẹ́rin lára 12 ọmọlẹ́yìn Igboho tó wà ní àhámọ́ DSS l'Abuja

Ni ọjọ Iṣẹgun ni adajọ Obiora Egwuatu yi ẹbẹ DSS yii danu lẹyin ti agbẹjọro DSS, Ọgbẹni Idowu Awo, yọwọ kuro ninu ẹjọ naa.

O ya gbogbo eeyan to wa nile ẹjọ pe bi wọn ṣe fẹ ka ẹjọ ni agbọjọro ajọ DSS kede pe oun ko ni le tẹsiwaju pẹlu ẹjọ naa mọ.

Ọgbẹni Awo sọ fun ile ẹjọ pe oun ti pẹjọ kotẹmilọrun lori beeli ti ile ẹjọ giga fawọn mẹrin ọmọlẹyin Igboho.

Awo ni o san foun lati tẹsiwaju igbẹjọ ọhun nile ẹjọ kotẹmilọrun.

Àkọlé fídíò, Ondo Jos clash: Èmi nìkan ló padà dé nínú àwa márùn ún tí a jọ lọ ìpàdé àdúrà ní Jos- Bell

Ṣugbọn adajọ yi ẹbẹ agbẹjọro DSS danu lẹyin ti agbẹjọro awọn ọmọlẹyin Igboho, Sunday Adebayo sọ tako ibeere DSS lati dawọn pada si atimọle.

Oru ọjọ kinni oṣu keje ni wọn DSS ko awọn eeyan mejila naa nigba ti wọn ṣe ikọlu si ile Igboho lagbegbe Soka n'Ibadan.

Àkọlé fídíò, Unijos students victims: Àwọn Fulani yabo 'hostel' wa, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn Sọ́jà tí gómìnà ìpí

Ẹwẹ, ni ibẹrẹ oṣu kẹjọ ni ile ẹjọ giga kan niluu Ibadan paṣẹ pe agbẹjọro agba ati minisita eto idajọ ni Naijiria, Abubakar Malami, ko gbọdọ mu Igboho fun ra rẹ lẹyin ti wọn ṣe ikọlu si ile rẹ.

Ile ẹjọ tun paṣẹ pe ajọ DSS ati Malami ko gbọdọ gbẹsẹ le apo ikowosi Igboho.

Koda ile ẹjọ naa tun kilọ fun Malami ati DSS pe wọn ko gbọdọ dunkoko mọ Igboho, wọn o si gbọdọ ṣe ohun buburu kan fun un.

aworan Igboho atawọn eeyan mejila naa

Adájọ́ pàṣẹ ìtúsílẹ̀ mẹ́rin lára 12 ọmọlẹ́yìn Igboho tó wà ní àhámọ́ DSS l'Abuja

Adajọ Obiora Egwuatu ti ile ẹjọ giga ijọba apapọ l'Abuja ti buwọlu iwe aṣẹ itusilẹ mẹrin lara awọn ọmọlẹyin Sunday Igboho mejila ti wọn ko nigba ti wọn ṣe ikọle si ile rẹ niluu Ibadan

Àkọlé fídíò, Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí

Eyi waye lẹyin tawọn eeyan naa ti lo ọjọ mẹtalelaadọta ni ahamo ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS niluu Abuja.

Iroyin kan sọ pe niṣe ni adajọ kọ eti ikun si gbogbo awijare agbẹjọro DSS, Idowu Awo, o si buwọlu lu iwe aṣẹ naa.

Awọn mẹrin naa ni Amudat Babatunde, Abideen Shittu, Jamiu Oyetunji, ati Bamidele Sunday.

Agbẹjọro fawọn eeyan naa, Pelumi Olajengbesi lo fidi ọrọ yii mulẹ fawọn akọroyin.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Ààrẹ ẹgbẹ VOR sọ pé kí ọmọ Yorùbá di ààrẹ Naijiria kọ́ ni ọ̀nà àbáyọ

Olajengbesi ṣalaye pe adajọ ko le buwọlu iwe aṣẹ lati tu awọn mẹjọ yoku silẹ tori mẹta ninu awọn oniduro ti lọ ki awọn ohun ti ileẹjọ n beere fun beeli wọn to pe.

Awọn mẹjọ ọhun ni Abdullateef Onaolapo, Tajudeen Irinloye, Dikeola Ademola, Ayobami Donald, Uthman Adelabu, Olakunle Oluwapelumi, Raji Kazeem, ati Taiwo Tajudeen.

Amọ, agbẹjọro Olajengbesi ni awọn oniduro mii yoo rọpo awọn to ti lọ, adajọ yoo si paṣẹ itusilẹ ti wọn naa.

Àkọlé fídíò, Babatunde Gbadamosi: Mo ta gbogbo dúkìá mi lásìkò kan kí ń tó padà di eèyàn lónìí

Olajengbesi ko ṣai rọ ile ẹjọ pe ko paṣẹ itusilẹ awọn eeyan naa.

Agbẹjọro DSS ni awọn mẹrin ti ile ẹjọ tu silẹ yii gan an lo mọ nipa ẹsun kiko nkan ogun pamọ sile ti wọn fi kan Igboho.

Àkọlé fídíò, Oba Ogboni Abalaye n fẹ́ kí wọ́n o má a fi ẹ̀sìn àbáláyé búra fún àwọn olóṣèlé Naijiria

Lati ọsẹ to lọ lawọn oniduro ti wa nilẹ, ṣugbọn adajọ ni ko si nile.

Oru ọjọ kinni oṣu keje ni wọn DSS ko awọn eeyan mejila naa nigba ti wọn ṣe ikọlu si ile Igboho lagbegbe Soka n'Ibadan.

Àkọlé fídíò, Eegunjobi Omotanbaje Ajobiewe- Èébú ní wọ́n kọ́kọ́ ń bù mí nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ ẹ̀ṣà pípé ní