New York governor: Kathy Hochul gómìnà obìnrin ìpínlẹ̀ New York àkọ́kọ́

Oríṣun àwòrán, Fcaebook/Kathy Hochul
Ipinlẹ New York lorilẹede Amẹrika ti ni gomina obinrin fun igba akọkọ ninu itan ipinlẹ naa.
Wọn bura fun Kathy Hochul loru ọjọ Aje si ọjọ Iṣẹgun lẹyin ti Andrew Cuomo kọwe fipo silẹ lọri ẹsun ifipa dẹnu ifẹ kọ awọn obinrin.
Adajọ agba ipinlẹ naa, Janet DiFiore lo dari eto ibura Hochul gẹgẹ bi gomina ipinlẹ New York tuntun.
- Gómìnà ìpínlẹ̀ New York ní America kọ̀wé fipò sílẹ̀!
- Secondus, alága PDP ní òun kò bẹ̀rù àṣẹ ilé ẹjọ́, kí ẹgbẹ́ má bàjẹ́ ni tòun
- Èèyàn márùn ún kú, ọ̀pọ̀ míì farapa lásìkò rògbòdìyàn àwọn ọmọ onílẹ̀ l'EKo
- Wo ìgbà mẹ́ta tí Olusegun Obasanjo ti fi ìdọ̀bálẹ̀ nàá fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ níwájú àwọn oríadé
- Aya adarí ìjọba ológun Naijiria tẹ́lẹ̀rí, Victoria Aguiyi-Ironsi ti jáde láyé
Lẹyin ti wọn bura fun Hochul tan lo sọ loju opo Twitter ati Facebook rẹ pe iyi nla lo jẹ foun lati di gomina kẹtadinlọgọta ipinlẹ New York.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Agbẹjọro agba ni New York, Letitia James ti mi Hochul ku oriire pẹlu bi o ti di gomina obinrin akọkọ ipinlẹ naa.
James ni ọjọ nla lọjọ Iṣẹgun ti wọn bura fun Hochul jẹ ninu itan New York.
O gbadura fun Hochul pe yoo ruu, yoo si sọọ re bi o ṣe bẹrẹ si ni tukọ ipinlẹ New York.
Cuomo ti sọ tẹlẹ pe o tẹ oun lọrun lati kọwe fipo silẹ ju kawọn aṣofin dibo yọ oun nipo lọ.
Ọjọ Aje ọjọ kẹtalelogun oṣu kẹjọ ni Cuomo kuro ni ọfiisi gomina ipinlẹ New York patapata.












