Victoria Aguiyi-Ironsi ti fi ayé sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, IMSG
Iyawo adari ijọba ologun Naijiria nigba kan ri, Victoria Aguiyi-Ironsi ti jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgọrun un.
Iroyin ni arabibirin ọhun fi aye silẹ ni aarọ ọjọ Aje, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2021.
Ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kọkanla, ọdun 2021 ti a wa yii lo yẹ ki ologbe naa pe ẹni ọdun mejidinlọgọrun un loke eepẹ ki ọlọjọ to de.
- Àwa nìkan ni ọ̀nà àbáyọ sí ìṣoro tó ń dojúkọ Naijiria- Àwọn Oníṣẹ̀ṣe
- Afurasí tó gbé oògùn olóró lọ sílé ìjọsìn ní ọwọ́ NDLEA bá tẹ̀ẹ́ kó tó ké Hallelujah
- Ìtàn ayé Ọba Seriki Abass ti Badagry, tó ní aya 128, ọmọ 144
- Tinubu lẹ́tọ̀ọ́ láti dupò ààrẹ lẹ́gbẹ́ APC gẹ́gẹ́ báwọn ọmọdé náà ti lẹ́tọ̀ọ́ - Jandor
- Àjọ SERAP gbé Buhari lọ sílé ẹjọ́ lórí N106bn tí wọ́n ló d'àwátì láwọn ilé iṣẹ́ ìjọba
- Àwọn jàndùkú afẹ̀mí-ṣòfò ṣekúpa èèyàn 24 ní Kaduna àti Katsina lọ́jọ́ kan ṣoṣo
Ọkọ oloogbe ọhun, Aguiyi-Ironsi ni adari ijọba ologun Naijiria fun oṣu mẹfa ki wọn to gab ijọba lọwọ rẹ lọdun 1966.
Asiko iditẹgbajọba naa ni wọn ṣekupa Aguiyi-Ironsi atawọn ologun mii ti wọn jọjọ n ṣejọba lọdun naa lọhun.
Lẹyin iku ọkọ rẹ, arabinrin Victoria Aguiyi-Ironsi kọ lati ṣe igbeyawo pẹlu ọkunrin miran.
Ọmọ mẹjọ lo wa laarin awọn lọkọ-laya naa ki iku aitọjọ to pin awọn mejeji niya.








