Nigeria doctor's strike 2021 / Saudi recruit: Saudi Arabia ti bẹ̀rẹ̀ ètò ìgbanisíṣẹ́ nílùú Abuja láti kó àwọn dókítà Naijiria lọ

Saudi

Ogunlọlọgọ awọn dokita ọmọ Naijiria ti korajọ niluu Abuja lati kopa ninu eto igbanisiṣẹ kan lati ilẹ Saudi Arabia.

Ileeṣẹ kan lati Saudi lo n ṣagbatẹru eto naa lati fun awọn dokita nikan ni iṣẹ lorilẹ-ede awọn.

Eto igbanisiṣẹ awọn dokita yii lo n waye lasiko ti awọn dokita Naijiria ti yanṣẹ lodi lori ẹsun ti wọn fi kan ijọba apapọ pe o n fi ẹtọ awọn dun wọn.

Lẹyin akoko diẹ ti awọn doki Naijiria da iṣẹ silẹ ni ijọba apapọ dukoko mọ wọn pe oun yoo fi iya jẹ eyikeyi ninu wọn to ba kọ lati pada sẹnu iṣẹ.

Adajọ John Targema ti ile ẹjọ to n si ri ọrọ awọn oṣiṣẹ paṣẹ ṣaaju pe ki awọn dokita ọhun fopin si iyanṣẹlodi wọn.

Bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn eeyan lo n fi erongba wọn lori eto igbanisiṣẹ ọhun, eto naa ṣi n tẹsiwaju ninu gbọgan Ladi Kwali to wa ninu ile itura kan l'Abuja.

Àkọlé fídíò, Senato francis Fadahunsi: Ká ni wọ́n fún Buhari ladún mẹ́wàá sẹ́ypin ní, bóyá kò bá rí i ṣ

Lara awọn dokita to n kopa ninu eto igbanisiṣẹ naa ni awọn to n maa n ṣiṣẹ abẹ, atawọn mii ti iṣẹ wọn jọ mọ gbigba ẹmi eeyan la.

Awọn kan lara awọn dokita naa to ba BBC sọrọ ṣalaye pe awọn n kopa ninu eto igbanisiṣẹ naa nitori bi ijọba Naijiria ko ṣe naani awọn dokita ati bo ṣe maa n fi ẹtọ awọn dun awọn.

Àkọlé fídíò, Rape survivor: Ìyá mi ni ń kò gbọdọ̀ sọ̀rs kí ilé má bà á dàrú- Oluwatobi Raji

Wọn ṣalaye pe owo gọbọi ni ileeṣẹ ilẹ Saudi fi n lọ awọn, idi ree ti awọn ṣe fẹ lọ niwọn igba ti ijọba Naijiria ti kọ lati mọ riri awọn.

Àkọlé fídíò, Ondo Jos clash: Èmi nìkan ló padà dé nínú àwa márùn ún tí a jọ lọ ìpàdé àdúrà ní Jos- Bell

Aarẹ apapọ fun ẹgbẹ awọn dokita nile iwosan ijọba ni Naijiria, NARD, Uyilawa Okhuaihesuyi ṣalaye fun awọn akọroyin pe oun ko da awọn akẹgbẹ oun to fẹ salọ si Saudi lẹbi nitori ko yẹ ki eeyan duro pẹ nibi ti wọn ko ba ti riri rẹ.

Àkọlé fídíò, Unijos students victims: Àwọn Fulani yabo 'hostel' wa, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn Sọ́jà tí gómìnà ìpí

O ni ti ijọba ba ṣe itọju awọn dokita bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ irufẹ nnkan bayii ko ni ṣẹlẹ.

Dokita

Oríṣun àwòrán, @Digicom

Ìjà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni o, àwọn dókítà NARD tó ń yanṣẹ́lódì fárígá pẹ̀lú ìjọba.

Awọn dokita nilewosan ẹkọṣẹ isegun lorilẹede Naijiria NARD ti wọn daṣẹ silẹ lọwọ bayii ni awọn kọ lati buwọlu iwe adehun pẹlu ijọba apapọ nitori pe ni iwoye awọn bi igba ti ijọba apapọ fẹ fi iya jẹ awọn nitori ijakulẹ ijọba funrararẹ.

Bakan naa ni wọn seleri pe iyanṣẹlodi ti awọn gunle ṣi n tẹsiwaju.

Aarẹ apapọ ẹgbẹ awọn dokita nilewosan ẹkọṣẹ iṣegun NARD, Dokita Okhuaihesuyi Uyilaea lo sọ eyi di mimọ lẹyin ipade wọn pẹlu ẹgbẹ awọn dokita ni Naijiria (NMA), awọn alẹnulọrọ lẹka iṣehun oyinbo ati ijọba apapọ.

Ipade naa waye nipasẹ aṣẹ ti aarẹ Buhari pa fun minista f'ọrọoṣiṣẹ, Chris Ngige lati yanju gbogbo ohun to ba n fa wahala lori iyanṣẹ lodi naa.

Lẹyin ọpọlọpọ wakati ti wọn fi ṣe ipade naa ẹgbẹ awọn dokita ileewosan ẹkọṣẹ isegun NARD naa ni awọn yoo tẹsiwaju pẹlu ẹjọ ti wọn pe nile ẹjọ ọrọ oṣiṣẹ, NIC.

Amọṣa o, ninu ọrọ tirẹ, minisita f'ọrọ osisẹ, Chris Ngige ṣalaye ṣaaju fawọn akọroyin pe gbogbo koko ọrọ ti mejila ti wọn joko lori rẹ ni wọn ti fohun ṣọkan le lori pẹlu ẹgbẹ awọn dokita NMA, ti ijọba yoo si bẹrẹ iṣẹ le lori lẹyẹ-o-ṣọka.

Àkọlé fídíò, Ohun ti Yorùbá ń pè ní Èṣù yàtọ̀ sí Sátánì nítorí Èṣù ní iṣẹ́ rere lọ́wọ́