Funke Akindele Bello: 'Jenifa' ní ìjákulẹ̀ ìgbéyàwó òun àkọ́kọ́ fẹ́rẹ́ gbẹ̀mí òun ṣùgbọ́n òun kò gbà fún un

Jenifa

Oríṣun àwòrán, @Jenifa

Orí ayélujára ni mo ti gbọ́ pé ìgbéyàwó mi àkọ́kọ́ ti foríṣánpọ́n - Funmi Akindele Bello

Gbajumọ oṣere Funkẹ Akindele ti ọpọlọpọ eeyan mọ si Jẹnifa ti ṣalaye ohun to kooyọ lọwọ wahala ipenija to la kọja nigba ti igbeyawo rẹ akọkọ foriṣanpọn.

Ninu ifọrọwerọ kan Funkẹ Akindele Bello gba awọn ọlọmọge niyanju lati tẹlẹ jẹjẹ lori ọrọ igbeyawo. O ni bi wọn ba fi girigiri wọ inu igbeyawo, girigiri naa ni wọn yoo fi jade.

O ni ori ayelujara ni igbeyawo oun akọkọ ti forijale agbọn ati peori ayelujara gan loun ti mọ pe igbeyawo oun ti tuka.

"Mo n ya sinima kan lọwọ ni eeyan kan pe mi sọ fun mi. Mo sunkun titi bi ẹni maa ku"

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Mo faramọ́ àtúntò 'Restructuring' tí kò lọ́wọ́ ìṣèlú nínú- Oba Ahmed Adeku

Bakan naa lo fi kun un pe ọpọ awọn iṣẹ olowo iyebiye loun padanu pẹlu igbeyawo naa.

Amọṣa o Jẹnifa ṣalaye pe oun ko jẹ ko da oun wolẹ.

O dupẹ lọwọ iya rẹ to se atọna imulọkanle fun oun lati gbaju mọ iṣẹ oun ki oun si tẹsiwaju.

Àkọlé fídíò, Babatunde Gbadamosi: Mo ta gbogbo dúkìá mi lásìkò kan kí ń tó padà di eèyàn lónìí