Mass burial Ghana: Tètè wá gbé òkú eèyàn rẹ bí bẹ́ẹ̀ kọ́ a ó sìn wọ́n papọ̀ mọ́ tí 200 lópin ọ̀sẹ̀- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá

Oku

Oríṣun àwòrán, @Jubilee House

E wo lo ṣẹlẹ ti ileeṣẹ ọlọpaa fi fẹ sinku oku 200 lẹẹkan ṣoṣo?

Kere o! ẹyin ti ẹ ba ni oku lọdọ wa, ẹ wa ko wọn bi bẹẹ ko, a o sin wọn papọ.

Ikede yi lo n jade lati ọdọ ileesẹ ọlọpaa lorileede Ghana eyi ti wọn ni awọn yoo sinku igba oku ti awọn ko mọ mọlẹbi wọ́n.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi sita lọjọ Aje ni wọn ti n kesi araalu bẹẹ.

Wọn ni ki onikaluku wa yọju lati ṣe idanimọ oku ti o ba jẹ ti wọn.

A n fi asiko yi rọ araalu pe ki wọn ma gbagbe isinku awọn oku igba yi ta ti n tẹnumọ lati oṣu Keje lọna ti mu adinku b iye oku to wa ni ile ikokupamọsi ile iwosan wa''

Wọn tẹsiwaju pe igbakeji ree tawọn fẹ se isinku alapapọ fun awọn oku ti mọlẹbi wọn ko yọju.

Àkọlé fídíò, Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí

Wọn tun ni: "Yoo dunmọ wa ti awọn araalu ba le kan si ẹka ikokupamọ wa bẹrẹ lati ọjọ Kẹtalelogun oṣu yi lati le tọka si oku ti o ba jẹ tiwọn ki wọn si gbe wọn lọ ki a ma ba ko wọn papọ mọ awọn oku mii lọ sin.''

Àkọlé fídíò, Babatunde Gbadamosi: Mo ta gbogbo dúkìá mi lásìkò kan kí ń tó padà di eèyàn lónìí

DSP Yaw Nketia to buwọlu atẹjade yi ni awọn nilo ki araalu pawọpọ pẹlu awọn lori ọrọ yi.

Ileeṣẹ ọlọpaa lorileede Ghana ni awọn yoo fẹ ki awọn eeyan wa ṣaaju isinku tawọn fẹ se lopin ọsẹ yi lati mu adinku ba iye oku tawọn ko si ile ikokupamọ.