Self defence Gómìnà Katsina ṣàlàyé ìdí tó fi ní káwọn èèyàn máa di ìhámọ́ra ogun

Gomina Masari ati awọn agbebọn

Oríṣun àwòrán, other

Gomina ipinlẹ Katsina, Aminu Bello Masari ti ṣalaye idi to fi ni ki araalu maa di ihamọra ogun lati daabo bo ara wọn lọwọ awọn janduku afẹmi ṣofo.

Masari ni awọn eeyan ko kan le maa kawọ gbera ki awọn janduku maa pa wọn ni ipakupa.

Gomina Katsina ṣalaye pe awọn ẹṣọ eleto abo ko to lati pese abo to peye fawọn araalu.

Masari ni bi ijọba ṣe n gbiyanju agbara rẹ to lati pese abo fun araalu, ojoojumọ lẹmi awọn alaiṣẹ n ṣofo lọwọ awọn ajinigbe.

Awọn ti wọn ko ba pa, niṣe ni awọn ajinigbe pawo n gbe wọn lọ.

Àkọlé fídíò, Babatunde Gbadamosi: Mo ta gbogbo dúkìá mi lásìkò kan kí ń tó padà di eèyàn lónìí

''Ijọba gbiyanju lati jiroro pẹlu awọn janduku afẹmi ṣofo yii, ṣugbọn pabo ni gbogbo rẹ ja si.

Ohun to jẹ ko ri bẹẹ ni pe awọn janduku yii ko ni olori kankan ti wọn le gbọran si lẹnu.

Oriṣiiriṣii ẹgbẹ janduku afẹmiṣofo lo wa ninu igbo ti wọn n ṣọṣẹ kaakiri.

Àkọlé fídíò, Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí

Awọn ẹṣọ alaabo naa ko to nkan, sọja meloo lo wa nipinlẹ Katsina gan an?

Wọn o pọ nitori ọrọ eto abo to mẹhẹ gbogbo Naijiria lo kan.

Eyi gan an lo ṣakoba fun wa ni Katsina tori awọn eeyan ko kan le maa ka ọwọ gbera ki awọn janduku ṣi maa pa wọn.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Mo faramọ́ àtúntò 'Restructuring' tí kò lọ́wọ́ ìṣèlú nínú- Oba Ahmed Adeku

Nibo ni wọn fẹ sa lọ, ti wọn ba sa kuro labule wọn?

O ṣe pataki fawọn araalu lati dide bayii, ki wọn si sa apa wọn lati gbaruku ti ijọba lori eto abo to mẹhẹ.

Àkọlé fídíò, Oba Ogboni Abalaye n fẹ́ kí wọ́n o má a fi ẹ̀sìn àbáláyé búra fún àwọn olóṣèlé Naijiria

Nkan ti yatọ si ti ọdun to lọ ṣugbọn alaafia ko tii jọba tan nipinlẹ Eko.

Inu mi ko le dun gẹgẹ bi adari ipinlẹ Katsina ti awọn janduku ba tẹsiwaju si ni fẹmi awọn eeyan ṣofo tabi ki wọn maa ji wọn gbe pawo,'' Masari ṣalaye.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Ààrẹ ẹgbẹ VOR sọ pé kí ọmọ Yorùbá di ààrẹ Naijiria kọ́ ni ọ̀nà àbáyọ