Ṣé lóòtọ́ ni pé ilé ẹjọ́ sọ pé kí Lizzy Anjorin san 9.5m fún ẹni tó pé lẹ́jọ́ nítorí ọ̀rọ̀ ọkọ rẹ̀?

Oríṣun àwòrán, lizzy anjorin/ dorcas adeyinka
Gbajugbaja agbohunsafẹfẹ lori ayelujara Facebook, Dorcas Adeyinka ti jawe olubori ninu ẹjọ kan ti gbajugbaja osẹrebinrin, Lizzy Anjorin pe e ni orilẹ-ede United Kingdom.
Oṣu kẹfa, ọdun 2021 ni Lizzy gbe Dorcas Adeyinka ati eeyan mẹta miran lọ si ile ẹjọ lorilẹ-ede UK, fun ẹsun ibanilorukọ jẹ.
Lizzy sọ pe wọn ba orukọ oun jẹ ni ọpọ igba lori ayelujara.
- Tètè wá gbé òkú eèyàn rẹ bí bẹ́ẹ̀ kọ́ a ó sìn wọ́n papọ̀ mọ́ tí 200 lópin ọ̀sẹ̀- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá
- Kò sí ọmọ Zambia kan tó má sùn pẹ̀lú ebi mọ́ lásìkò tèmi gẹ́gẹ́ bíi Aàrẹ- Hichilema ṣèlérí
- Mẹ́fà nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ Islamiyya Tegina ti kú, àwọn ajínigbé ṣì ń bèèrè N200m
- Ẹgbẹ́ ọmọ bíbí Gúúsù Kaduna ní ìkọlù àwọn agbébọn sí NDA kìí ṣe ìyàlẹ́nu
Ninu ikede to fi sita lori ayelujara Facebook rẹ, pẹlu abajade iwe ile ẹjọ, Adeyinka sọ pe Onidajọ Spearman QC paṣẹ pe ki Lizzy san ẹgbẹrun mẹtadinlogun Pọun fun Dorcas laarin ọjọ mẹrinla pere.
Bakan naa ni ile ẹjọ da ẹjọ naa nu, to si kọ lati paṣẹ fun Dorcas pe ko ma sọrọ nipa Lizzy Anjorin ati ọkọ rẹ, Ọgbẹni Lawal.
Kilo pilẹ ija laarin Lizzy Anjorin ati Dorcas Adeyinka?
Lati ọdun 2019 ti Lizzy Anjorin ti ṣe igbeyawo pẹlu ọkọ rẹ, Ọgbẹni Lawal, ni oriṣiriṣi awuyewuye ti n waye lori igbeyawo naa.
Ọpọ igba ni iroyin jade pe ọkọ ọlọkọ ni Lizzy gbà.
Ko si pẹ lẹyin igbeyawo naa ni obinrin kan, Fola Tinubu, jade si ori ayelujara pe oun ni obinrin ti Lizzy gba ọkọ rẹ.
O sọ ninu awọn fidio kan to fi si ori ayelujara pe ọmọ mẹrin ni Lawal fi silẹ fun oun nikan lati ma a tọju, to fi ko lọ si ile Lizzy, ti wọn si ṣe igbeyawo.
Botilẹ jẹ pe Lizzy sọrọ nigba naa pe o ti to ọdun mẹẹdogun ti oun ti mọ Lawal, o jẹ alaanu oun, ti oun ko si gba a lọwọ obinrin kankan.
Dorcas Adeyinka to ma n sọrọ nipa awọn nkan to n lọ laarin ilu, lori ayelujara Facebook, to si tun ma n pe ara rẹ ni ajafẹtọ ọmọniyan, da si ọrọ naa, to si ṣe ileri lati gbeja Fola.
Lati asiko naa si lo ti ma n gbe oriṣiriṣi iroyin ati 'asiri' nipa Lizzy ati Lawal jade.
Lẹyin asiko diẹ, Lizzy ko le gba awọn ọrọ naa mọra mọ, o si pe Dorcas ni ẹjọ si ile ẹjọ kan ni United Kingdom, nibi ti Dorcas n gbe.
Kini Lizzy sọ lori idajọ ile ẹjọ naa?
Lizzy Anjorin fi fidio kan sita lori ayelujara Instagram rẹ ni Ọjọru pe irọ ni jijawe olubori ti wọn sọ pe awọn jawe olubori. Botilẹ jẹ pe ko darukọ ẹni to n ba a wi
O ni nkan ti ile ẹjọ sọ ni pe ki oun pe wọn lẹjọ ni Naijiria, niwọn igba to jẹ pe Naijiria ni oun n gbe.
"Wọn win lori irọ... Wọn ni ki a pe wọn lẹjọ lati Naijiria, niwọn igba to jẹ pe Naijiria ni a n gbe. Oun gan-an lo pe wa ju."
Lizzy ṣalaye pe igbẹjọ gan-an ko ti i bẹrẹ lori ẹsun ti oun fi kan ẹni naa. O ni ile ẹjọ lati fi ofin de wọn lori ọrọ oun ni awọn ṣi lọ.
Bakan naa lo sọ pe oun yoo ṣi sọrọ lori idajọ ile ẹjọ naa.
- Ǹkan mọ́kànlá tí o ni láti mọ̀ nípa Sẹnatọ Biyi Durojaiye tó d'Ólògbé
- Wo ìgbésẹ̀ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Plateau gbé lẹ́yìn ìkọlù tó wáyé lónìí
- Wo ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn márùn ún tí àwọn èèyàn ilú Eko fi kan àwọn òṣìṣẹ́ LASTMA
- Ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé yóò wáyé ní Eko, Oyo, Ogun, Ondo àti ìpínlẹ̀ 30 míì láàrín ọjọ́ mẹ́ta- NiMet
- Wo ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ fún àgbà nọ́ọ̀sì tó ta ọmọ ọdún mẹ́fà ní N200,000
Ninu ọrọ to pada sọ lori fidio to ṣe ni owurọ oni pe oun ko ni i sinmi ogun lori ọrọ naa. O ni idi ni pe awọn nkan to jẹ idunnu fun oun lo fẹ ẹ bajẹ.
O ni kii ṣe pe ile ẹjọ da ẹjọ nu. O ni ile ẹjọ sọ pe kii ṣe agbegbe oun ni ẹjọ naa ti waye.

















