Sale of children: Àgbá nọ́ọ̀sì dèrò ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tó ta ọmọ ọdún mẹ́fà ní N200,000

Ganiyat

Oríṣun àwòrán, others

Yoruba bọ, wọn ọjọ gbogbo ni ti ole, ọjọ kan bayii ni ti olohun.

Agba nọọsi kan ti ri ẹwọn he lẹyin ti aṣiri owo kata kara ọmọde to n ṣe tu, ti o si n ka boro boro.

Ile ẹjọ giga niluu Uyo nipinlẹ Akwa Ibom dajọ ẹwọn ọdun mẹwaa fun Gertrude Akpan lẹyin to jẹbi ẹsun kata kara ọmọde.

Adajọ Okon Okon dajọ ju Akpan si ẹwọn ọdun mẹwaa lai fun un lanfaani fun lati san owo itanran,

Akpan ni ile ẹjọ fi idi rẹ mulẹ pe o ra ọmọdekunrin ọdun mẹfa niluu Uyo ti o si ta ọmọ naa fun ẹnikan ti orukọ rẹ n jẹ Kate Ogbonna niluu Owerri.

Àkọlé fídíò, Ondo Jos clash: Èmi nìkan ló padà dé nínú àwa márùn ún tí a jọ lọ ìpàdé àdúrà ní Jos- Bell

Akpan, ẹni ọdun mẹtadinlaadọta jẹ ọmọbibi ilu Ikot Eyo ni ijọba ibilẹ Nsit Ibom ni ipinlẹ Akwa Ibom.

Akpan, iya ọmọ mẹta, jẹwọ pe oun ti ti n ṣe owo kata kara ọmọde lati ọdun 2008.

Àkọlé fídíò, Unijos students victims: Àwọn Fulani yabo 'hostel' wa, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn Sọ́jà tí gómìnà ìpí

Bakan naa lo sọ pe oun ti ṣiṣẹ ri gẹgẹ bi nọọsi ni ile iwosan Immanuel Hospital niluu Eket nibi ti oun ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi olori awọn nọọsi lọdun 2015.

Lẹyin wi pe o jẹwọ, o tan ran awọn ọlọpaa lọwọ lati ri ọmọdekunrin to ta gba lọwọ ẹni to ta ọmọ naa fun niluu Owerri.

Adajọ ni o ṣeni laanu pe Akpan ti oun fun ra rẹ naa jẹ abaimọ le maa fi ọmó ọlọmọ ṣe owo kata kara.

Adajọ Okon nin iwa buruku gbaa ni agba nọọsi naa hu nitori ko jẹ ki awọn ọmọde to n fi ṣowo jẹ anafaani ifẹ ati didagba labẹ obi wọn.

Àkọlé fídíò, Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí