NDA Kaduna attack: Ìkọlù NDA sàfihàn pé ààrẹ Buhari ń gbìyànjú láti sọ Nàìjíríà di Afganistan ni- SOKAPU

NDA Kaduna attack: Ìkọlù NDA sàfihàn pé ààrẹ Buhari ń gbìyànjú láti sọ Nàìjíríà di Afganistan ni- SOKAPU

Oríṣun àwòrán, SOKAPU

Agbarijọpọ awọn ọmọ bibi apa guusu ipinlẹ Kaduna,SOKAPU ti bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ ikọlu awọn agbebọn si ibudọ ikọnilẹkọ awọn ọmọ ogun Naijria NDA.

Ninu atẹjade ti wọn fi sita, ẹgbẹ naa ni ikọlu yi fi han pe aarẹ n gbiyanju lati sọ orileede Naijiria di bi Afghanistan ti se ri ni.

Agbẹnusọ ẹgbẹ naa Luka Binniyat sọ fun ileesẹ iwe iroyin Naijiria The Punch pe ọna aibikita tawọn ọdaran yi fi doju ija kọ ibudo awọn ọmọ ogun ti eeyan kankan ko si farapa ninu wọn n tọka si eewu nla gidi to n koju oselu awarawa ni Naijiria.

Ẹgbẹ naa sọ pe ti wọn koba ṣe nkankan si ikọlu yi, o ṣeeṣe ki ''ijọba Buhari maa palẹmọ ohun ti yoo ṣẹlẹ mi to n bọ ni''

O ni ''Ipaniyan awọn ọmọ ogun meji yi ati ijinigbe ọgagun kan ko ya awa ọmọ ẹgbẹ SOKAPU lẹnu rara.Idi ni pe iru ikọlu bẹ ti waye lẹẹmeelo kan ni bareke awọn ọmọogun to wa ni ile ẹkọ Command and Staff College, Jaji to wa laarin Zaria ati Kaduna.Ninu ikọlu yi wọn ji maalu ati nkan ini miran lọ''

Binniyat wa kilọ pe ti wọn ko ba gbe igbesẹ ni kiakia ki wọn si mu awọn ọdaran yi,o ṣeeṣe ki iru nkan to waye ni Afghanistan ṣẹlẹ ni Naijiria.

"Ọrọ ẹnu aarẹ latẹyinwa ati iṣeṣi rẹ fi han pe ko bikita lati gbe agbara fawọn alakatakiti''

''Boya iṣẹlẹ aburu yi yoo ta gbogbo eeyan ji yatọ si aarẹ Buhari ati awọn agbodegba rẹ nitori ero wọn si ọmọ Naijiria ko sunwọn rara''

O wa kesi gbogbo ọmọ Naijiria alti bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ yi ki wọn si pe Gomina Kaduna Nasir El Rufai ati aarẹ Buhari si akiyesi lati gbaju mọ ojuṣe wọn ki Naijiria to tẹri sinu ọọfin ti awọn ko lero rara.

Bi a ko ba gbagbe lowurọ kutu ọjọ Iṣẹgun lawọn agbebọn yawọ NDA ti wọn si pa ọmọ ogun meji ki wọn to ji ọgagun kan gbe salọ.

Titi di ba ṣe n ṣakojọ iroyin yi, a ko ti mọ pato ibi ti wọn gbe lọ ṣungbọn ijọba gba ẹnu ileeṣẹ ologun sọrọ pe awọn yoo sawari awọn ọdaran yi.

NDA Kaduna attack: Ǹkan márùn mí tó yẹ kí o mọ̀ nípa ilé ẹ̀kọ́ ológun táwọn jàndùkú kọlù ní Kaduna rèé

Awọn ọga ologun

Oríṣun àwòrán, Nigeria Defence Academy

Lowurọ ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrinlelogun lawọn janduku ajinigbe afẹmi ṣofo kọlu ọkan lara ile ẹkọ ologun NDA to wa niluu nipinlẹ Kaduna.

Ọmogun meji ni yinbọn pa nibẹ, koda wọn tun ji ọmogun to ti gboye Major lọ.

Lẹyin iṣẹlẹ naa ni iroyin kan sọ pe awọn ijinigbe ọhun n beere igba miliọnu naira owo itusilẹ fun ọmogun ti wọn jigbe lọ.

Iroyin mii to lu ori ayelujara pa bayii tiẹ tun sọ pe awọn janduku yii ti ṣekupa ọmogun ti wọn jigbe lọ.

Ohun koko marun un to yẹ ki o mọ nipa ile ẹkọ ologun NDA tawọn ajinigbe ṣe ikọlu si ni Kaduna ree.

  • Ile ẹkọ ologun yii ti wa ṣaaju ki Naijiria to gba ominira.

koda Royal Military Forces Training College (RMFTC) ni wọn n pe orukọ ile ẹkọ naa nigba naa.

Lẹyin ominira Naijiria ni wọn yi orukọ rẹ pada si Nigerian Military Training College ki o to di Nigeria Defence Academy, NDA ti wọn n pe lonii.

Àkọlé fídíò, Unijos students victims: Àwọn Fulani yabo 'hostel' wa, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn Sọ́jà tí gómìnà ìpí

2. Ile ẹkọ ologun NDA yii lo dara julọ lapa iwọ oorun Afirika

Ile ẹkọ ologun NDA yii fasiti ologun akọkọ iruẹ lapa iwo oorun Afirika.

Awọn orilẹede to wa lapa iwọ oorun Afirika ko ko iyan ilẹ ẹkọ NDA yii kere.

Àkọlé fídíò, Babatunde Gbadamosi: Mo ta gbogbo dúkìá mi lásìkò kan kí ń tó padà di eèyàn lónìí

3. Awọn akẹkọọ maa n gboye akọkọ ni fasiti jade nibẹ

Ile ẹkọ ologun nikan lawọn akẹkọọ ti maa n gboye akọkọ fasiti jade ti wọn ba ṣetan ẹkọ wọn.

Ọdun marun lawọn akẹkọọ maa n lo ni ile ẹkọ yii, mẹrin fun igbẹkọ, nigba ti ọkan yoku wa fun ẹkọṣẹ ologun.

4. Awọn ọbinrin ọmogun naa kẹkọọ gboye ni fasiti NDA yii

Ṣaaju ọdun 2011, awọn ọkunrin nikan lo maa kẹkọọ jade nile ẹkọ NDA yii ni Kaduna.

Lọdun 2011 ni lawọn ọmogun obinrin bẹrẹ si ni kẹkọọ jade ni ile ẹkọ ologun naa.

Àkọlé fídíò, Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí

5. Awọn akẹkọọ n gboye keji ati ẹkẹta fasiti ni NDA yii

Ọpọ eeyan ni ko mọ pe awọn ọmogun n gboye keji ati ẹkẹta fasiti ni fasiti ologun to wa ni Kaduna yii.

Koda awọn akẹkọọ ti wọn kii ṣe ologun naa lanfaani lati kẹkọọ gboye ni ile ẹkọ NDA yii to fi de ipele Ọmọwe lẹnu ẹkọ.