Nigerian defence academy attack: Ìkọlu sí ìṣọ̀kan Naijiria ni ìkọlù sí ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà, NDA, jẹ́

Nigerian defence academy

Oríṣun àwòrán, Nigerian Scoop

Agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kaduna, Yusuf Zialani ti juwe ikọlu awọn janduku sile ẹkọ awọn ọmọ ogun Naijiria ni Kaduna, NDA, gẹgẹ bii ikọlun si iṣọkan Naijiria lapapọ.

Zailani lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi lede lati ọwọ olubadamọran rẹ lori iroyin, Ibrahim Danfulani.

O ni ijọba apapọ ko gbọdo fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ikọlu naa, ki wọn si tun ṣe iwadii to peye lori iṣẹlẹ ọhun.

Agbẹnusọ ile igbimọ aṣofin Kaduna naa juwe NDA gẹgẹ bii ile ẹkọ awọn ologun to dantọ eyii ti awọn ologun nilẹ Afrika fi n yangan ti ko si yẹ ko la irufẹ ikọlu bẹẹ kọja.

O ni ikọlu ọhun ko gbọdọ lọ lai ṣe pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọmọ ogun ṣe iwadii to tọ lori ọrọ ọhun.

Zailani sọ pe "O ṣeni laanu, o si bani ninu jẹ gidi pe irufẹ ikọlu bẹẹ le waye si ile ẹkọ awọn ọmọ ogun, ti awọn ẹṣọ alabo ilẹ ẹkọ naa ko si kofiri pe iru nnkan bẹẹ yoo waye."

Àkọlé fídíò, Unijos students victims: Àwọn Fulani yabo 'hostel' wa, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn Sọ́jà tí gómìnà ìpí

Bo tilẹ jẹ pe Zailani gboriyin fun ileeṣẹ ọmọ ogun lori akitiyan rẹ lati yanju awọn janduku to n da alaafia Naijiria laamu, o rọ wọn ki wọn maṣẹ jẹ ki ikọlu da omi tutu siwọn laya.

O ba ẹbi awọn to padanu ẹmi wọn kẹdun, o si gbadura pe ki Eledua tẹ wọn si afẹfẹ rere.

Lẹyin naa lo ni inu oun dun pe awọn alaṣẹ NDA ti ṣeleri pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ lati ṣawari gbogbo awọn to lowọ ninu ikọlu ọhun.

Àkọlé fídíò, Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí

Ki lo tin ṣẹlẹ sẹyin?

Bí àwọn jàndùkú ṣe kọlu ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà (NDA)

Latest news in Nigeria: Bí àwọn jàndùkú ṣe kọlu ilé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ọmọogun

Oríṣun àwòrán, NDA

Àwọn jàndùkú kọlu ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́sẹ́ ọmọogun Nàìjìríà (NDA) ni bákérè Afaka nípinlẹ̀ Kaduna ni Nàìjíríà.

Ìròyìn sọ pé àwọn agbébọn pa àwọn ọmọogun méjì ti wọ́n sì gbé ọ̀kan lọ

Ọ̀kan nínú àwọn ti ọ̀rọ̀ náà sojú rẹ̀ nílé ẹ́kọ́ ọ̀hún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ fun BBC

Àwọn mííràn ti ọ̀rọ̀ náà tún sojú wọn ṣàlàyé pé ó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ lówùrọ̀ ọjọ́ Iṣẹgun nígbà tí àwọn sójà náà kò ròò.

Ọ̀kan nínú àwọn òṣìṣẹ́ NDA náà fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ pé :

Àwọn jàndukú yabo ọgbà ilé iṣẹ́ ẹ̀kọ́ṣẹ́ ọmọogun , wọ́n pa ènìyàn, bákan náà ni wọ́n ji ènìyàn gbé lọ.

Ilé ẹ̀kọ́ NDA náà ti fi àtẹ̀jáde tí wọn síta pé àwọn pàdánù ènìyàn méjì ti wọ́n sìjá ẹnìkan gbé lọ.

Àkọlé fídíò, Babatunde Gbadamosi: Mo ta gbogbo dúkìá mi lásìkò kan kí ń tó padà di eèyàn lónìí

Gẹ́gẹ́ bi òṣìṣẹ́ náà ṣe sọ , ìṣẹ̀lẹ̀ náàwáyé n nǹkan bi aago mẹ́ta òrumójú ọjọ́ Isegun .

Ó ní àwọn kan n gbọ iró ibọ̀n sùgbọ́n àwọn rò pé àwọn ọmọogun to n gba ẹ̀kọ́ lọ́wọ́ ni, sùgbọ́n ìgbà ti ilẹ̀ mọ ni a tó mọ nǹkan ti ó ṣẹlẹ̀.

"Nàkan bi aago mẹ́ta ìdájí la gbọ́ ìró ìbọn ni ọkàn mí, níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé, inú NDA ni a wà, ó ṣeéṣe kí o jẹ́ àwọn tó n kọ́ iṣẹ́ ọmọogun"

Ó fi kun pé lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí àwọn elétò ààbò ti yi agbègbè náà ká lati wádìí nǹkan ti o ṣẹlẹ̀.

Ikọlù tó wáyé ní ilé ẹ̀kọ́ NDA: Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀

Àwọn alákoso nilé ẹ̀kọ́ náà NDA fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn agbébọn kọlu inu bárékè àwọn

Agbẹnusọ fún ilé ẹ̀kọ́ náà Méjọ̀ Bahir Muhd Jajira , sọ pé orú mọ́jú ọjọ́ Isẹgun ni iṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ.

" Orísun ààbò orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni o rí ìkọlù lówùrọ́ òní láti ọwọ́ àwọn agbẹ́gbọn àìmọ̀rí tí wọ́n rápálá wọ àgbègbè ibi ti àwọn ènìyàn ńgbé ni agbègbà Afaka.

Àkọlé fídíò, Ondo Jos clash: Èmi nìkan ló padà dé nínú àwa márùn ún tí a jọ lọ ìpàdé àdúrà ní Jos- Bell

"Lásìkò tí iṣẹ̀lẹ̀ aburú yìí, a pàdánù ènìyàn wa méjì ti wọ́n sì jí ènìyàn kan."

" Ilé iṣẹ́ ọmọogun orílẹ̀ àti ojú ofururfu ló jọ n ṣe iṣẹ́ pọ̀ nílé ẹ̀kọ́ náà ní ìpińll Kaduna , sùgbọ́n gbogbo àwọn elétò ààbò to ku ló ti n lépa àwọn ọ̀daràn náà láti le ri ẹni ti wọ́n ji gbe gbà padà"

Àláfíà ni gbogbo àwọn ọmọ ilé ẹka náà wà nílé ẹ̀kọ́ wọn , a si n fi ọkàn gbogbo ará ilú balẹ̀ pé láìpẹ́ yìí a o ri wan mú ti a ó si gba ẹni ti wọ́n ji gbá padà.