Open Grazing Ban: Gómìnà Akeredolu ní darandaran tó bá da ẹran nígboro yóò fojú winá òfin

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gomina ipnlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti kllọ fun ẹgbẹ awọn darandaran, Myetti Allah pe wọn ko gbọdọ tafa si ofin to de dida ẹran ni ipinlẹ Ondo.
Gomina Akeredolu ninu atẹjade to fi lede ni ẹnikẹni to ba tapa si ofin ki wọn ye e da ẹran kaakiri igboro yoo fi oju wina ofin.
O ni ofin naa yoo mulẹ ju bi wọn ṣe lero lọ, ti ẹnikẹni ba rufin naa.
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko buwọ́lu òfin máfi ẹranjẹko láàrín ìlú àti VAT
- Kílódé tí Sheikh Gumi fi ṣe àbẹ̀wò sí Igboho nínú gbogbo ìlú tó wà nílẹ̀ Yorùbá?
- Àwọn jàndùkú agbébọn jí òṣìṣẹ́ ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo mẹ́ta lọ
- Ẹ wo ǹkan tí a mọ̀ nípa Sheik Gumi tó ń dúnà-dúrá pẹ̀lú àwọn agbébọn ní Nàìjírìá
- Ọ̀run àpáàdì ń dúró de gbogbo ẹ̀yin aláìní ìrònúpìwàdà- Fani Kayode sí Gumi
- Alàgbà Gumi, ẹ lọ mèṣọ́nu lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó lè máa ki àwọn agbébọn láyà- Iléeṣẹ́ Ológun Nàìjíríà
- Àwọn jàndùkú agbébọn jí èrò ọkọ̀ 18 tó ń lọ sí ìlú Eko láti Ondo lọ
''Ko ni si aye fun awọn ọdaran lati lo ọnakọna to wu wọn lati ṣiṣẹ ibi ni ipinlẹ Ondo.''
''Ijọba ipinlẹ Ondo ri fidio kan ti ẹgbẹ awọn darandaran Myetti Allah fi lede, gba ọwọ akọwe ẹgbẹ naa, Saleh Hassan.
''Ninu fidio naa ni wọn ti fi lede pe awọn darandaran n hu iwa ọdaran nitori iya ati iṣẹ to n ba awọn eniyan wọn finra.''
''Wọn sọ ninu fidio naa pe awọn gaju ofin ipinlẹ kankan lọ, to fi mọ ti ijọba apapọ''
Amọ ijọba ipinlẹ Ondo ninu esi wọn sọ wi pe ko si ẹya kan tabi ede kan to gaju ofin lo, nitori naa ẹnikẹni to ba rufin, yoo jẹ iya rẹ.
''A ko ni fi aye gba ki awọn onilẹ di ẹru ni ilẹ baba wọn nitori awọn ọdaran darandaran ti ko ni ifẹ si gbigbe pẹlu awọn eniyan ni alaafia.''
''Awọn ara ipinlẹ Ondo fẹran alejo, amọ wọn ko ni fi aye gba ki awọn darandaran gbakoso ilẹ wọn, ki wọn si ma a fi iya jẹ awọn agbẹ.''
Ọjọ Kini, Oṣu Kẹsan ni gomina ipnlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu buwọlu ofin to dena dida ẹran kaakiri ipinlẹ Ondo.












