Gumi: Tani Sheik Gumi tó ń dúnà-dúùrá pẹ̀lú àwọn agbébọn ní Nàìjírìá?

Oríṣun àwòrán, Google
Ọpọlọpọ eniyan lo tako bii Sheik Ahmad Abubakar Gumi ṣe dide gẹgẹ bi ẹni to n duna-dunra laarin ijọba ati awọn agbegbọn to n ji awọn eniyan gbe ni iha ariwa orilẹede Naijiria.
Eyi ko ṣẹyin bi Sheik Gumi lo di ilumooka lẹyin ti ijọba apapọ ni awọn nilo eniyan to mọ awọn agbebọn naa lati le ba wọn sọrọ.
Gumi lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ tako bi wọn ṣe n pe awọn agbẹbọn ni ọdaran,ko dara to ati wi pe awọn gan an ni ọdaran naa.
- Francis Olusola Alao: Wọ́n ti ti ọ̀rọ̀ òṣèlú bọ ọ̀rọ̀ Sunday Igboho, ṣùgbọ́n....- Oba Olugbọn
- Ẹ tú ìgbéyàwó wa ká, níṣe n'ìyàwó mi máa ń gbá mi létí- ọkùnrin kan sọ fún iléẹjọ́
- Irọ́ ni o! A kò tíì rí àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin tó lé ní 300 tí wọ́n jí gbé ní GGSS Jangebe - Ìjọba Zamfara
- Èèyàn 240 míràn ló ṣẹ̀ṣẹ̀ tún lùgbàdì Covid-19 ní Nàìjíríà
Bakan naa ni o fi lede wi pe awọn ọdọbinrin ọọdunrun ti wọn jigbe ni ileewe wọn ni Zamfara, ko si ni ọdọ awọn agbebọn ti oun ba sọrọ ni Kagara.
Sheik Gumi ni o tumọ si pe awọn ikọ agbebọn miran lo gbe awọn ọmọbinrin naa.
Ẹ wo ohun ti a mọ nipa iru eniyan ti Sheik Gumi jẹ.
- Onimọ nipa ẹsin Islam ni Sheik Ahmad Gumi jẹ, oun si ni akọbi Shaykh Abubakar Gumi, ti wọn bi ni ilu Kano,
- Oun ni Mufti ati Mufassir Mọsalasi gbogboogbo ni ilu Kaduna
- Fulani ni ni Gumi, to si jẹ onimọ ati ajagun tẹlẹ pẹlu ileeṣẹ ologun Naijiria,
- Ọmọ ọdun mọkanlelọgọta ni Ahmad Abubakar Gumi, to si lo si ileewe Sadauna Memorial College ati fasiti rẹ ni Ahmadu Bello University to ti kọ iṣẹ gẹgẹ bi dokita,
- Lẹyin naa lo darapọ mọ ileeṣẹ ọmọọogun Naijiria, Nigeria Defence Academy to si ṣiṣẹ de ipo Captain pẹlu ikọ ọmọogun Naijiria ko to fẹyinti lẹnu iṣẹ,
- Oun lo fi apeja ọrọ ''My Vote, My Pride'' ni ọdun 2014.
















