Kwara Brutal Flogging: Ìgbìmọ̀ olùwádìí ní ikọ̀ alákósó iléẹ̀kọ́ Kéú nìkan ló le fìyà jẹ ẹlẹ́ṣẹ̀

Oríṣun àwòrán, facebook/screen shot
Ijoba ipinlẹ Kwara, laipẹ yii gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣewadii iṣẹlẹ bi wọn ṣe lu awọn akẹkọọ ile Keu kan lori ẹsun pe wọn lọ si ile ijo ni agbegbe Ganmo, ni ipinlẹ Kwara.
Igbesẹ ọhun ko ṣẹyin fidio kan to da ori ayelujara ru, nibi ti awọn akẹkọọ kan ti gba aṣẹ lọwọ olukọ agba lati na awọn akẹkọọ bi ẹni lu bara lori ẹsun pe wọn lọ si ile ijo ni agbegbe Ganmo, ni ipinlẹ Kwara.
Igbimọ ẹlẹni mọkanla ti ijọba ipinlẹ Kwara gbe kalẹ naa lati ṣewadii ifiyajẹni lọna aitọ ni ileẹkọ Keu naa, ti wa gbe esi iwadii wọn kalẹ.
Lasiko ti igbimọ naa n fi iwadii wọn han, Alaga igbimọ naa, Adajọ Agba Idris Haroon ni lara imọran ti awọn fun ijọba ipinlẹ Kwara ni lati gbe igbimọ kalẹ, ti yoo ma ṣamojuto awọn ileẹkọ Keu ati oye ẹsin Islam.
''Ti gomina ba gbe igbimọ alakoso awọn ileẹkọ yii kalẹ, ayipada yoo de ba bi wọn ṣe n da ijọba ara wọn ṣe ni awọn ileẹkọ yii.''
''Nitori naa, ero tiwa ni pe ọna abayọ ni kiakia ni agbekalẹ igbimọ alamojuto awọn ileẹkọ imọ ẹsin musulumi yii.''
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara dá ọ̀gá ilé Keu tí wọ́n ti lu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bí i bàrà dúró
- "Èmi ni mo sọ fáwọn ọ̀gá ilé Keu pé kí wọ́n lu ọmọ mi bí ẹran"
- Ilé aṣòfin Kwara dá sí ọ̀rọ̀ iléẹ̀kọ́ Kéú tó fìyà jẹ àwọn akẹ́kọ̀ọ́
- Wo ọmọ Nàíjíríà tó wà nínú Mùsùlùmí 500 tó lààmì laaka lágbàáyé
- Kéére o! Ìjọba tú òbìnrin kan ṣoṣo amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Sunday Igboho tó kù láhàmọ́ DSS silẹ̀
''Bakan naa ni wọn bu ẹnu atẹ lu iru ifiyajẹni ni awọn ileẹkọ yii, eleyii ti wọn ni igbesẹ gbọdọ waye lati ṣe atunṣe lori ijiya to yẹ ti wọn le fun awọn akẹkọọ ni ileẹkọ.''
Igbimọ to n ṣewadii naa dupe lọwọ gomina ipinlẹ Kwara fun bo ṣe tete da si iṣẹlẹ naa, to si gbe iwadii kalẹ ni kiakia, ti awọn naa si jara mọ iṣẹ lati fi di otitọ iṣẹlẹ naa han fun awọn araalu.
Wọn fikun un pe lasiko iwadii, wọn ba awọn olukọ sọrọ, awọn akẹkọọ ko gbẹyin nibẹ to fi mọ awọn obi awọn akẹkọọ wọnyii.
- Naijiria yóò dàrú tí ìjọba àpapọ̀ bá le kéde àwọn jàndùkú gẹ́gẹ́ bíi agbésùmọ̀mí - Sheikh Gumi
- Ṣé lóòtọ́ ni Iskilu Wakili, Balógun Fulani wà lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó sálọ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Abolongo l'Oyo?
- Gbẹgẹdẹ fẹ́ gbiná láàrín Oluwo àtàwọn ìgbìmọ̀ Ìmáàmù àti Àlfáà ilẹ̀ Yorùbá, wọ́n ní Oluwo ń kọjá àyè rẹ̀
Ninu ọrọ tirẹ, Gomina ipinlẹ Kwara gboriyin fun awọn to wa ninu igbimọ iwadii naa nitori wọn ko kọ iṣẹ ilu silẹ.
O ni awọn yoo wo amọran igbimọ naa finifini to fi mọ igbimọ alakoso fun awọn ileẹkọ imọ ẹsin Islam.
Gomina ni awọn ri iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi ohun ẹlẹgẹ ni awọn se pe awọn onimọ lati ṣewadii iṣẹlẹ naa finifini.












