Kwara Brutal Flogging: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mu ‘Yogurt’ níbi ayẹyẹ, Àáfà rò pé ọtí ni ló bá ṣètò ìyá fún wọn

Awọn akẹkọọ ti wọn n lu

Oríṣun àwòrán, facebook/screen shot

Àkọlé àwòrán, Akẹkọọ ile Keu bi i mẹrin lo na ikọọkan awọn akẹẹgbẹ wọn to ṣẹ̀

Ijọba ipinlẹ Kwara ti da Ọga Agba ile ẹkọ Kuraani kan to wa nilu Ganmo duro, lẹyin fidio to ṣafihan bi wọn ṣe fi iya jẹ awọn akẹkọọ wọn kan ti wọn lo ru ofin.

Kọmisanna eto ẹkọ nipinlẹ naa, Sa'adatu Modibbo Kawu lo sọ bẹ ni ọjọ Aiku.

Ṣaaju ni fidio naa ti jade, eyi to ṣafihan bi awọn akẹkọọ bi i mẹrin ṣe fi ẹgba lu awọn akẹẹgbẹ wọn(ọkunrin mẹrin, obinrin kan) ni ilukulu.

Awọn alaṣẹ ile Keu naa lo paṣẹ fun wọn lati ṣe bẹẹ. Eyi ko ṣẹyin ẹsun ti wọn fi kan awọn akẹkọọ naa pe wọn lọ si ayẹyẹ ọjọ ibi nile ijo, ti wọn si tun mu ọti.

Kọmisanna eto ẹkọ nipinlẹ Kwara, awọn to lọ fun abẹwo, ati awọn alfa ile keu

Oríṣun àwòrán, Kwara State government

Àkọlé àwòrán, Kọmisanna eto ẹkọ nipinlẹ Kwara, awọn to lọ fun abẹwo, ati awọn alfa ile keu

Kọmisaana naa sọ pe aṣoju ijọba lọ sile Keu naa, ti wọn si ti da Ọga ibẹ duro.

O ni botilẹ jẹ pe awọn obi awọn ọmọ naa sọ pe awọn fọwọ si ijiya ọhun, ijọba koro oju si iru ibawi to han ninu fidio naa.

Bakan naa lo sọ pe ijọba ti gbe igbimọ kan kalẹ lati wadii iṣẹlẹ naa.

Awọn akẹkọọ naa si ti n gba itọju nileewosan nitori ọgbẹ ara wọn.

Bawo ni iṣẹlẹ naa ṣe lọ?

Awuyewuye ti n waye lori awọn fidio kan to gba ori ayelujara, eyi to ṣafihan awọn ọmọkunrin ile Keu kan to n lu akẹẹgbẹ wọn to jẹ ọkunrin ati lobinrin ni ilukulu nipinlẹ Kwara, nitori pe o lọ sibi ayẹyẹ.

Ninu awọn fidio naa, lati ri awọn gende ọkunrin to yi ọmọbinrin kan to wa lori ikunlẹ ka, ti wọn si n ko ẹgba bo o.

Bẹẹ ni wọn tun ṣe si awọn ọmọkunrin naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ileeṣẹ iroyin ori ayelujara Fresh Insight TV, to fi fidio naa sita sọ pe Maliimu (Alfa) ile Keu Madrasah Musbaudeen, to wa ni agbegbe Ganmo, nipinlẹ Kwara, lo paṣẹ pe ki awọn ọmọkunrin naa lu akẹẹkọbinrin naa nitori pe o lọ sibi ayẹyẹ.

Àkọlé fídíò, Jawahir Roble:Hijab tí mò n lò kó jẹ́ kọ́kọ́ jẹ́ ìyàlẹ́nu fún àwọn agbábọ́ọ̀lù mi

Bakan naa ninu fidio naa ti a ri, niṣe ni awọn olukọ ile Keu naa n sọrọ labẹlẹ pe ki awọn to n lu awọn akẹẹkọ naa lu wọn daadaa.

A gbọ pe ọrẹ wọn kan lo n ṣe ọjọ ibi, ti wọn si fi awọn aworan ti wọn ya nibi ayẹyẹ naa si ori ayelujara.

Amọ, olukọ wọn ri awọn aworan naa, to si ro pe ọti ni wọn n mu, laimọ pe yugọọti ni wọn n mu.

Fidio naa mu ki awọn eeyan ma a sọ oriṣiriṣi nkan, ti ọpọ si koro oju si iru iwa bẹẹ.

Ọpọ lo sọ pe iru ibawi ti wọn fun awọn akẹkọọ naa ko ba ẹsin Islam mu, to si tun tako ẹtọ ọmọniyan.

Kini awijare awọn alaṣẹ ile Keu naa?

Amọ ninu fidio miran to tun jade, awọn alaṣẹ ile Keu Madrasah Musbaudeen naa ti sọrọ.

Àkọlé fídíò, Africa Eye wádii àwọn tó wà nídìí ìgbésùmọ̀mí ni Mozambique

Ninu fidio naa, lẹni to ṣeeṣe ko jẹ olori ileewe naa, ti n ba awọn akẹkọọ ilu Keu naa sọrọ, to si sọ pe nitori ki aye awọn ọmọ naa le dara ni awọn ṣe ba wọn wi.

O sọ pe"awọn obi wọn lo kọkọ sọ fun wa pe awọn ọmọ ti awọn fi sọdọ wa ki aye wọn le ni itumọ rere, lọ si ibi ayẹyẹ, ti wọn si n mu ọti nibẹ:"

O ni nigba ti awọn naa ri awọn aworan ti awọn ọmọ naa fi si ori ayelujara, awọn ri i pe ile ijo 'club' ni wọn ti lọ fun ayẹyẹ, ti wọn si n mu oriṣiriṣi ọti, koda wọn tun n da ọti le ara wọn lori.

O ṣalaye pe nkan ti awọn ọmọ naa ṣe tako ẹkọ ti wọn n kọ nile Keu.