Tunde Bakare: Bí ọ̀pọ̀ ẹ̀yà ṣe ń lọgun láti kúrò ní Nàíjíríà fihàn pé a nílò àtúntò

Oríṣun àwòrán, Presidency
Adari ijọ ati pasitọ agba ijọ, Citadel Global Church, Pasitọ Tunde Bakare ti kesi Aarẹ Buhari lati fagile iwe ofin ọdun 1999 nitori ohun lo n ṣokunfa ifaṣẹyin fun Naijiria.
Bakare sọ eyi lasiko isin ni ile ijọsin rẹ to pe akori iwaasun ọhun ni ''Bi o ṣe n lọ lorilẹede Naijiria'', ''The state of the Nation''.
Isin naa waye ni gbagede ile ijọsin rẹ to wa ni olu ile ijọsin naa ni ipinlẹ Eko.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Gómìnà Yoruba, ẹ dúró lé ìjọba àpapọ̀ lọ́rùn pé kó fi Sunday Igboho sílẹ̀ - Gani Adams
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara dá ọ̀gá ilé Keu tí wọ́n ti lu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bí i bàrà dúró
- Ìdí rèé tí mo fi gbà kí ọkọ mi má a ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìyá àti àbúrò mi
- Ohun tí ojú mi rí rèé lọ́wọ́ àwọn amojúẹ̀rọ lásíkò yíya sinimá - Adunni Ade
- "Ó ṣeéṣe ká ta gáàsì 12.5kg ní ₦10,000 kó tó di December ọdún yìí"
- Wo ìtàn ayé Sunday Igboho, gbajúmọ̀ ajìjàgbara fún ilẹ̀ Yorùbá
- Ìgbagbọ́ mi nínú Nàíjíríà kò yinjẹ, ìrètí mi nípa ọjọ́ ọ́la wa sì le koko - Obasanjo
- N kò lẹ́bọ lẹ́rù lórí ilé Tinubu ní London tí ìwé Pandora gbé jáde pé mo ba rà á - Oyetola
Pasitọ Bakare ni awọn idojuko to n ba orilẹede Naijiria finra ko ṣẹyin eto oṣelu to mẹhẹ lati ibẹrẹ wa, eleyii ti awọn ijọba ologun doju rẹ bolẹ nigba ti wọn gbakoso iṣejọba Naijiria.
Bakare ni ija ẹlẹyamẹya, ẹlẹsin mẹsin to fi mọ awọn ẹkun to n lọgun pe wọn fẹ kuro lorilẹede Naijiria, eleyii ti ko yọ ẹkun kankan silẹ, fihan pe Naijiria nilo atunto.
Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, ohun to ṣe pataki kọ ni ibi ti aarẹ orilẹede yoo ti wa, to ba jẹ pe orilẹede Naijiria duro ire.
''O dami loju pe iwe ofin ọdun 1999 ko so eso rere kankan fun Naijiria, iku lo mu wa fun orilẹede yii.''
Bakan naa lo kesi aarẹ Buhari lati ṣe ojuṣe rẹ ki o si ye e gbe iṣẹ fun Ile Igbimọ Aṣofin ti Naijiria.
''Aarẹ Buhari, ya iwe ofin ọdun 1999 ko si ṣe atuntọ ati atunṣe orilẹede Naijiria pada.''
''Aibikita ni ki awọn kan ma a lọgun idibo gbogboogbo ọdun 2023 lai kọkọ wa wọrọkọ fi ṣe ada lori ọrọ atunto orilẹede Naijiria.
Pasito Tunde Bakare wa kilọ fun aarẹ Buhari pe ti ko ba tun orilẹede Naijiria to, akọsilẹ yoo wa wi pe o kuna gẹgẹ bi aarẹ nigba to wa ni ipo.
Bakare to jẹ amofin ati agbẹjoro naa ti fi igba kan dije dupo igbakeji aarẹ pẹlu aarẹ Buhari ni idibo si ipo aarẹ ni ọdun 2011.

Ìgbagbọ́ mi nínú Nàíjíríà kò yinjẹ, ìrètí mi nípa ọjọ́ ọ́la wa sì le koko - Obasanjo

Oríṣun àwòrán, The Presidency
Aarẹ tẹlẹ fun orilẹede Naijiria, Oloye Olusegun Obasanjo ti rọ awọn ọmọ Naijiria lati mase sọ ireti nu nipa orilẹede yii.
Obasanjo ni ẹpọn agbo kan n mi lasan ni, ko ni ja nitori awọn isoro to n ba Naijiria finra ko kuku ni gbe mi.
Oloye Obasanjo fi ọwọ idaniloju yii sọya lasiko to n sọrọ nibi eto kan to waye pẹlu ilẹ Amẹrika nile iyawe-kawe rẹ nilu Abeokuta.
Nigba to n sọrọ apilẹkọ nibi eto naa, Obasanjo ni mimi kankan ko mi igbagbọ ti oun ni nipa orilẹede yii pe ọjọ ọla yoo dara, ti ilẹ yii yoo si duro re.
- Wo àìsàn tí Ààrẹ Nààijíríà tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo ń bá fínra láti ọdún 35 sẹ́yìn
- Ẹpọ̀n àgbò kàn ń mì lásán ni lórí ètò ààbò Nàíjíríà tó mẹ́hẹ, kò ní já - Obasanjo
- Wo ìgbà mẹ́ta tí Olusegun Obasanjo ti fi ìdọ̀bálẹ̀ nàá fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ níwájú àwọn oríadé
- Ọ̀rọ̀ díẹ̀ ati ìgbésẹ̀ akin lá máa gbé báyìí lórí ọ̀rọ̀ Nàíjíríà - Obasanjo
- Obasanjo ṣàbẹ̀wò s'ọ́jà tí wọ́n fi sọrí rẹ̀ n'Ibadan, ó ṣèlérí ìrànwọ́ fáwọn ọlọ́jà
- Obasanjo fèsì lórí báwọn ọmọ Nàìjíríà kan ṣe ń pe ààrẹ Buhari ní Jubril ti Sudan
- Mi o tíì rí olórí tó fẹ́ràn Naijiria tó Baba Obasanjo- Yoruba Council of Elders
Obasanjo, ẹni ti igbakeji alakoso ile iyawe-kawe rẹ, Kayode Aderinwale soju fun fikun pe isoro yowu ti kii ba maa koju Naijiria lọwọ kii se isoro ikọlu bikose isoro ipadasẹyin.
"Igbagbọ mi ninu Naijiria ko yinjẹ, ireti mi nipa ọjọ ọla si le koko, bi o tilẹ jẹ pe ọpọ lo n kọminu nipa baa se doola ọjọ ọla wa."
"Mo ri ireti ninu ipinnu ọkan, itiraka ati iwa aikaibọnu awọn ọmọ Naijiria, mo si ri ireti ninu atako wọn nigba ti wọn ba sun wọn kan ogiri.
Mo ri ireti ninu ilakaka, ifọkansin ati igboya lasiko ti iyapa ba n koju wọn, mo si tun ri ireti nipa ọpọ ipinnu ọkan awọn ọdọ Naijiria lati se rere.
Mo tun ri ireti ninu bawọn ọdọ ati agbaagba ọmọ Naijiria se n fi gbogbo agbara wọn tako iwa ibi to n gbinlẹ lorilẹede yii.
Lakotan, mo tun ri ireti ninu ihuwasi ati igbesẹ awọn ọmọ Naijiria lati beere fun isejọba alagbada pẹlu ọgbọn atinuda wọn nipa orilẹede yii."
Olusegun Obasanjo ni ireti tun wa fun oun pe ọjọ ọla Naijiria yoo dara, ta ba wo iyapa ati ojulowo asa wa laarin iran ọmọniyan.






















