Sunday Igboho: Gani Adams ní ìjìjàgbara Yoruba Nation kò le di àpatì, àwọn kò ní dákẹ́

Oríṣun àwòrán, NewsDay Nigeria
Aarẹ Ona kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams ti ki Oloye Sunday Igboho ku oriire ayẹyẹ ọdun kọkandinlaadọta rẹ loke eepẹ.
Ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa, ọdun 1972 ni wọn bi Sunday Igboho, to si jẹ ọmọ ilu Igboho, ni ijọba ibilẹ Oorelope, nipinlẹ Oyo.
Adams wa rọ awọn gomina mẹfẹfa to wa nilẹ Yoruba lati duro le ijọba apapọ lọrun ko le fi Igboho lọrun silẹ ninu ọgba ẹwọn to wa lorilẹ-ede Benin.
- Ààrẹ Ògbóni sọ òkò ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí Gani Adams torí bó ṣe tàbùkù Ọba Ogboni tó ṣe ìwọ́de Yorùbá Nation
- Gani Adams kọ lẹ́tà sí àjọ UN, AU, US lórí ààbò tó mẹ́hẹ àti ìpànìyàn darandaran
- Àwọn ọ̀tá kan ń lo ìwà akọni Sunday Igboho láti bà mí lórúkọ jẹ́ - Gani Adams
- Oluwo, tí wọ́n bá rán ọmọ níṣẹ́ ẹrú, kó fi t'ọmọ jẹ - Gani Adams
- Ẹ̀yin Fulani, ẹ yàgò fún ilẹ̀ Yorùbá lásìkò yìí- Iba Gani Adams
- Ọ̀rọ̀ Yorùbá Nation ń fa aáwọ̀ láàrin Gani Adams àti Sunday Igboho
- Olóṣèlú ti tọwọ́ bọ ọrọ Igboho àti ìṣòro Fulani, mo gbọdọ̀ ṣọ́ra - Gani Adams
Aarẹ Gani Adams lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjada kan loju opo Instagram rẹ, eyii ti agbẹnusọ rẹ, Kehinde Aderemi buwọlu.
Iba tun ke si ijọba ilẹ Benin lati tu Igboho silẹ ninu ọgba ẹwọn naa to wa lai fọta pe.
O ni bayii ajigbara naa ti pe ẹni ọdun mọkandinlaadọta, eyii tumọ si pe kii ṣe ọmọde mọ, ọna kan ṣoṣo ti awọn eeyan si le gba mọ riri iṣẹ Ọlọrun ninu aye rẹ ni ko maa ja fun ẹtọ araalu bo ṣe n ṣe tẹlẹ.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, nibi ti ọrọ Naijiria de duro bayii, ijijagbara Yoruba Nation ko le di apati, awọn to si n pe fun idasilẹ orilẹ-ede tuntun naa ko ni dakẹ titi di igba ti wọn yoo jajabọ lọwọ ijọba aninilara.
Aarẹ sọ pe "Boya Sunday Igboho wa laarin wa ni o tabi o wa ni Benin Republic, igbagbọ temi ni pe ojuṣe gbogbo wa ni lati ba ṣe ajọyọ ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ."
"Ijijagbara fun ominira Yoruba ko le ku lailai, ko sì sí bi ijọba apapọ ṣe le dukoko mọ wa to a ko ni boju wẹyin ninu ojusẹ wa titi ti a fi maa gba ominira ilẹ Yoruba."
"Nitori naa, mo wa fi akoko yii rọ gbogbo awọn gomina mẹfa to wa nilẹ Yoruba lati gbogun ti ijọba apapọ ko tu Sunday Igboho silẹ, ohun kan ṣoṣo ti wọn le ṣe ree pẹlu ipo wọn lati fi han pe ojulowo ọmọ kaarọ oojire niwọn jẹ."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara dá ọ̀gá ilé Keu tí wọ́n ti lu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bí i bàrà dúró
- Ìdí rèé tí mo fi gbà kí ọkọ mi má a ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìyá àti àbúrò mi
- Ohun tí ojú mi rí rèé lọ́wọ́ àwọn amojúẹ̀rọ lásíkò yíya sinimá - Adunni Ade
- "Ó ṣeéṣe ká ta gáàsì 12.5kg ní ₦10,000 kó tó di December ọdún yìí"
- N kò lẹ́bọ lẹ́rù lórí ilé Tinubu ní London tí ìwé Pandora gbé jáde pé mo ba rà á - Oyetola
- Ilé Sunday Igboho ń gbàlejò ọ̀pọ̀ ọmọ Yorùbá tó fẹ́ sàmì ayẹyẹ ọjọ́ ìbí lẹ́yìn rẹ̀
- Wo ewu tó wà fún ìyálamọ tó ń jẹ olúbi ọmọ lẹ́yìn ọjọ́ ìkúnlẹ̀
- Wo ìtàn ayé Sunday Igboho, gbajúmọ̀ ajìjàgbara fún ilẹ̀ Yorùbá
- Ẹ múra o, ọ̀wọ́n gógó epo bẹntirolú bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Ajé nílẹ̀ Yorùbá
Gani Adams ni oun naa ti fi awọn akoko kan ṣe ọjọ ibi oun ninu ahamọ ri, Eledumare nikan ni oun si gbojule lakoko naa ti oun si gbagbọ pe ni igbẹyingbẹyin, ododo ni yoo bori eke.
O pari ọrọ rẹ pe bo tilẹ jẹ Igboho n koju irufẹ nnkan ti oun ti fi awọn akoko kan koju ri, yoo gba itusilẹ laipẹ bi oun naa ṣe gab itusilẹ.





















