Fuel Crisis and Strike: Ẹgbẹ́ àwọn awakọ̀ àtẹgbẹ́ òǹtàjà epo aládani wọ́gilé ìyanṣẹlódì tó yẹ kó bẹ̀rẹ̀ lónìí

Epo bentiroolu

Oríṣun àwòrán, PA Media

Ẹgbẹ awọn awakọ epo pẹtirolu PTD awọn alagbata epo aladani atawọn alagbata epo to da duro ti kede pe awọn ti wọgile iyanṣelodi wọn to yẹ ko bẹrẹ lonii kaakiri ilẹ Yoruba.

Igbesẹ yii ni abọ ipade ti wọn ṣe pẹlu awọn adari ajọ NNPC niluu Ibadan lọjọ Aiku.

Wọn tun sọ pe awọn yoo ṣe ipade mii lọla ọjọ kejila, oṣu Kẹwaa niluu Abuja lati mọ igbesẹ ti awọn yoo gbe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu atẹjade kan ti akọwe apapọ ẹgbẹ naa, Afolabi Akporeha fi lede, o ni wọn wọgile iyanṣelodi ọhun nitori igbagbọ awọn pe ijọba apapọ yoo mu ileri rẹ ṣẹ lẹyin ti awọn ṣepade niluu Ibadan, ati lẹyin ipade ti yoo waye niluu Abuja lọjọ Isegun.

Àkọlé fídíò, Olota Of Ota: N kò fara mọ́ ìyapa Nàíjíríà, ìṣèjọba ẹlẹ́kùnjẹkùn ní ọ̀nà àbáyọ

Akporeha sọ pe, kii ṣe pe awọn fẹ mọọmọ fiya jẹ awọn araalu pẹlu iyanṣẹlodi ọhun, ṣugbọn awọn n fẹ ki eto abo to peye wa fun awọn oṣiṣẹ ti wọn ba n gbe epo lati ilu kan si omiran loju popo ni.

O ni bo tilẹ jẹ pe igbesẹ awọn yoo ni ipa to lagbara lara awọn ọmọ Naijiria, awọn ko ni la oju awọn silẹ ki ẹka eto epo rọbi dibajẹ.

O wa pari atẹjade ọhun pe awọn ko ni fa ṣẹyin ninu gigunle iyanṣẹlodi naa lakọtun, ti ijọba ko ba ṣe awọn ohun ti wọn n beere fun.

Amin iyasọtọ kan

ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Ẹ múra o, ọ̀wọ́n gógó epo bẹntirolú bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Ajé nílẹ̀ Yorùbá

Ọwọn gogo epo bẹntirolu

Ọwọn gogo epo petrirolu n bọ nilẹ Yoruba nibayii ti ẹgbẹ awakọ epo pẹtirolu PTD awọn alagbata epo aladani atawọn alagbata epo to da duro gbe asẹ tuntun sita.

Asẹ naa ni pe ki awọn ọmọ ẹgbẹ wọn dẹkun gbigbe epo eroja epo rọbi lati oni ọjọ ni ẹkun guusu Naijiria.

Igbesẹ naa lo waye lẹyin gbedeke ọjọ mẹta ti awọn ẹgbẹ yii fun ileesẹ to n se akoso eroja epo rọbi PPMC, eyi to wa sopin lọjọ karun osu kẹwa ọdun 2021.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ajọ PPMC ni wọn fẹsun kan pe o n mu ko nira fun awọn alagbata epo lati ri awọn eroja epo rọbi ra lori atẹ.

Tẹlẹ tẹlẹ, awọn ontaja yii lo ni akọsilẹ katakara epo, ti onikaluku wọn si mọ akọsilẹ igba to yẹ ki ikọọkan wọn gbe epo amọ ti wọn ti sọ di ipinnu lati Abuja bayii.

Àkọlé fídíò, Sen Francis Fadahunsi sọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lórí kíkó ẹ̀rù wọlé láti ẹnubodè Nàìjíríà báyìí

Bakan naa ni wọn tun ni ileesẹ to wa fun eto eroja epo rọbi DPR tun se alekun owo isọdọtun iwe asẹ okoowo wọn atawọn owona miran amọ DPR ti yi ohun pada lori igbesẹ yii.

Gẹgẹ bi alaye ti osisẹ alarina fun ajọ IPMAN lẹkun iwọ oorun Naijiria ti wi, ileesẹ PPMC ko tii pahunda lori ipinnu rẹ lati sọ epo dọwọn fun awọn.

O ni idi ree ti awọn ẹgbẹ yii se pinnu lati gunle iyansẹlodi ti wọn kede rẹ bẹrẹ lati oru oni lọ.

"Igbesẹ ijọba yii ti n wọnu ere kekere ta n jẹ tẹlẹ, miliọnu meje ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹrin naira (N4.7m) la n gbe ọkọ lita epo ẹgbẹrun lọna mẹtalelọgbọn.

Amọ nibayii, Abuja ni ajọ PPMC ti n se akoso awọn ti yoo ri epo ra, ti wọn si tun se alekun iye ontaja epo ti yoo maa ra epo naa ati owo igbepo.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola ní àìsí ẹ̀kọ́ ń mú káwọn òṣèré tíátà ó máá ṣe oun tí kò tọ́.

Gbese ti pa ọpọ alagbata epo nitori aitete ri owoya banki da pada, ti ọpọ si n tun epo naa ra lati ọdọ awọn alagbata mii ni owo to wọn.

Ohun ta si mọ ni pa iyansẹlodi nikan ni ede ti ijọba gbọ, a ko si ni yẹsẹ kuro lori ipinnu lati yan isẹ lodi."