Kabul Make-up Artists: Wo ewu tó ń bẹ fáwọn obìnrin aṣaralóge ní Afghanistan

Oríṣun àwòrán, Nilab Adelyar
Lọjọ ti awọn ikọ Taliban wọ olu ilu orileede Afghanistan, gbogbo awọn ile aṣaraloge ti wọn ya aworan obinrin si ni wọn fi ọda kun.
Koda lọjọ yii, wọn ti gbogbo awọn ile onidiri naa pa ni.
Bo ti lẹ jẹ pe awọn ileeṣẹ kan ni awọn yoo ṣi maa ba iṣẹ wọn lọ, awọn miran ni nṣe ni ẹru n ba awọn fun aabo ẹmi wọn.
- Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Taliban àti bí wọ́n ṣe gbàjọba ní Afganistan
- Àwọn adájọ́bìnrin tó sọ Taliban sẹ́wọ̀n tẹ́lẹ̀ rugi oyin
- "Tí Taliban bá rí mí, ikú ní yóò gbẹyìn mi, kò sí ìdáríjìn fún mi"
- "Taliban kò gbà kí obìnrin wọlé padà sílé ẹ̀kọ́, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ọjọ́ ọ̀la mi"
- Taliban ti sọjí o, wo ohun tí wọ́n kìí ṣe tẹ́lẹ̀, tí wọ́n ń ṣe báyìí
- Ẹni orí yọ, ó di ilé ni ọ̀rọ̀ dì fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Afghanistan nítorí wàhálà tó n wáyé láàrin Taliban àti ìjọba
- Fá irungbọ̀n rẹ, kòó forí kó ìyà lọ́wọ́ ìjọba Afghnistan - Taliban
- Taliban ní òún ti gba ẹkùn Panjshir ní Afghanistan
- 'Ẹ má rí àwọn Taliban gẹ́gẹ́ bí ìjọba orílẹ́èdè Afghanistan,' ẹgbẹ́ alátakò pariwo
Afsoon (kii ṣe orukọ rẹ gangan ree) jẹ aṣojuloge to fori pamọ, to si ṣe apejuwe bi ẹka iṣaraloge ti ṣe pataki si fawọn obinrin Afghanistan ninu apilẹkọ yi.
Ọjọ Kẹẹdogun oṣu Kẹjọ ọdun 2021 ni nkan bi ago mẹwaa aarọ ni Afsoon gba ipe lati ọdọ alabaṣiṣẹ pọ rẹ kan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi iṣẹ se dopin lojiji fawọn asaraloge ni Afghanistan:
''Ma wa si ibi iṣẹ loni'' ni ẹni naa sọ fun. ''A ti palẹmọ ṣọọbu. O ti pari.''
Afsoon joko wọ si ori ibusun rẹ, to si n yẹ oju ẹrọ ibaranisọrọ rẹ wo.
Kia, o bẹrẹ si ni wo awọn atẹjiṣẹ to wa nibẹ. Nkan ẹyọ kan ni gbogbo wọn n sọ.
Taliban ti wọ olu ilu ilẹ wọn, Kabul. Laarin ọjọ mẹẹdogun, awọn ikọ ologun ilẹ okere ati awọn aṣoju wọn ti ko ẹru wọn sa kuro.
''O pari'' lọrọ ti Afsoon ṣa n tẹnumọ. Asiko ti to lati wa ibi foripamọ si.
Afsoon ti o jẹ ẹni ogun ọdun, ri ara rẹ gẹgẹ bi obinrin igbalode.
O nifẹ lati maa wo awọn oju opo ikansiraẹni lori ayelujara, fiimu, bẹẹ si ni o mọ ọkọ wa, to si ni afojusun fọjọ iwaju.
Afsoon ko ranti nkan to ṣẹlẹ ni nkan bi ọdun meloo kan sẹyin ti Taliban gba ijọba nitori lasiko yii ni wọn bi sile aye.
Amọ o dagba sorilẹede Afghanistan, ti ile aṣaraloge ati awọn nkan mere mere mii jẹ nkan tawọn araalu n gbadun.
Laarin ogun ọdun ti ikọ ologun Amẹrika n ṣe akoso ilu, wọn ti sedasilẹ o kere ju, ileesẹ iṣaraloge bii igba silẹ ni Kabul nikan, ti ọkẹ aimọye si wa kaakiri orileede naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi Afsoon se bẹrẹ isẹ asaraloge:
Afsoon nifẹ si gbogbo igbadun tawọn obinrin n gbadun lasiko yii, ti wọn si maa n kun eekanna, ti awọn miran yoo si kun oju pẹlu..
Orisirisi irun oge igbalode ni awọn obinrin maa n ṣe, ti aye si dun fun wọn lasiko yii.
Aṣẹyinwa aṣẹyinbọ, Afsoon ribi sọ afojusun rẹ di imuṣẹ, ti o si di aṣaraloge to gbajumọ. Nkan to wu ọkan rẹ ree.
Gẹgẹ bi awọn ile aṣaraloge mii ni Kabul, ile iṣaraloge rẹ naa ni gilaasi ti wọn ya aworan awọn obinrin si lati fi polowo iṣẹ wọn.
Bakan naa, awọn ''window'' yi kii jẹ ki awọn ọkunrin to ba n kọja lọ ri nkan to n ṣẹlẹ ninu awọn ile aṣaraloge ọhun.
Ọja wọn n ta witiwiti. Bo ba jẹ igbeyawo ni tabi ayẹyẹ miran to fi mọ ajọdun bi ọdun Ileya, awọn onibaara a maa forukọsilẹ, ki wọn ba le ribi dawọn lohun.
''Mo nifẹ awọn obinrin. O si wu mi lati ṣiṣẹ laaye tawọn obinrin yoo fi ni agbega, ti ko ni si idiwọ tabi ibẹru kankan''
Amọ gbogbo rẹ ja si pabo nigba ti awọn Taliban gba ijọba ipo aarẹ lọjọ Kẹẹdogun oṣu Kẹjọ ọdun 2021.
Bayi ni gbogbo wahala ti Afsoon ti n ṣe lati ọpọ ọdun sẹyin ja si asan lọjọ kan ṣoṣo.
Bi Afsoon se ba ileesẹ iroyin BBC sọrọ lori ewu to n koju awọn osisẹ asaraloge:
Ago mejila oru fẹ ẹ lu tan ki Afsoon to pe wa lori ago.
N ṣe lo n rọra sọrọ ki awọn eeyan baa ma gbọ ohun rẹ. O kuro ni ile rẹ lọ si ibomiran ni lati ba wa sọrọ lori ago.
"Awọn obinrin to n ṣiṣẹ lẹka aṣaraloge bi temi wa ninu ewu.''
Lẹyin to gba ipe lati ọdọ ọrẹ rẹ pe ki o ma wa si ibi iṣẹ, Afsoon gbọ pe awọn olugbe Kabul n fi ibẹrubojo kun aworan to ṣafihan obinrin lawọn aaye iṣaraloge.
Ọrẹ rẹ kan sọ pe oun fi ọwọ ara oun kun aworan obinrin aṣaraloge, ki awọn Taliban ma baa binu.
''Ko si bi wọn yoo ti ṣe gba lati ri aworan to fi obinrin ti ko bori han tabi eleyi to ṣafihan ọrun obinrin.''
''Lati ilẹ ni wọn ti fidi eyi mulẹ lara nkan ti wọn fẹ. Opin ti de ba iṣaraloge bayi ni Afghanistan''
Afsoon ko ni iwe irinna kankan to le jẹ ko bawọn wọ baalu kuro ni Kabul.
Ko si ọna abajade kankan fun.
Loju opo Whatsapp loun ati awọn akẹgbẹ rẹ ti maa n sọrọ.
Lọjọ Kẹrinlelogun oṣu Kẹjọ ni wọn ri owo iṣẹ gba kẹyin. Wọn ti ti ṣọọbu ti wọn ti n ṣiṣẹ pa. Ọna ti di mọ wọn bayi.
Afsoon sọ pe oun ko le sọrọ nipa afojusun ọjọ iwaju.
O ni oun ko ti ronu bi oun yoo ṣe mura jade tabi igba toun yoo jade sita.
''Bi mo ti ṣe maa wa laye nikan lo jẹ mi logun. Ẹru iku ko ba mi ṣugbọn bi ti pe ki n wa ku bayi kọ''
Gbogbo igba lọkan mi maa n sọ pe awọn Taliban ti n bọ wa mu mi.



















