Taliban take-over: Ẹgbẹ́ alátakò ní Taliban kìí ṣe ìjọba Afghanistan

Aworan awọn ọmọ ogun taliban kan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ẹgbẹ alako lorilẹ ede Afghanistan ti ke pe gbogbo pe lati ma rí awọn Taliban gẹgẹ bi ijọba ilẹ naa.

Ijọba ilẹ Amerika ti bu ẹnu atẹ lu ijoba ti awọn Taliban fi lọlẹ eleyii ti ko sí obinrin kankan ninu wọn.

Awọn ọmogun to n kọju sí awọn Taliban lẹkun Panjshir naa sọ pe ijọba Taliban lodi sofin.

Amẹrika kọminu lori iru awọn eeyan to wa ninu ijọba Taliban.

Orilẹ-ede Amerika ṣalaye pe awọn eeyan bii Mullah Mohammad Hassan Akhund ati Sirajuddin Haqqani wa lara awon afurasi ti Amerika ati ajọ FBI n ṣe iwadii lori wọn.

Aworan an igbi i#seba Taliban ni Afghanistan

Oríṣun àwòrán, Screenshot/bbc

Ẹgbẹ alatako NRF sọ pe ikede ijọba Taliban ṣiṣe ọta pẹlu awọn eeyan Afghanistan.

Ẹgbẹ Taliban ní awọn ti ṣẹgun NRF lẹkun Panjshir, amọ NRF ni ìjà si n lọ lọwọ.

Aworan an igbi i#seba Taliban ni Afghanistan

Oríṣun àwòrán, Screenshot/bbc

Ninu atẹjade kan ti orilẹ-ede ti Amerika fi sita, o ni oun n kọminu iru awọn eeyan ti ẹgbẹ Taliban kò sí ijọba rẹ.

Ajọ EU naa tako ijọba ti Taliban kéde, o ni ko mu ileri rẹ ṣẹ lori awon to sọ pé yóò wà ni ijọba rẹ.

Ní bíi ọsẹ mẹta sẹyin ni Taliban gba ijọba orilẹ-ede Afghanistan.

Amọ, oríṣìíríṣìí ipenija lo n doju kọ ijoba wọn lori ọrọ ajé ati lórí bí ọpọ ko ti faramọ bi wọn ṣe gbajọba.