Àwọn òjíṣẹ́ Ọlọrun tako ọ̀rọ̀ ọ̀gá àjọ NDLEA tó ní òògùn olóró ló n tú ìgbéyàwó ká

Oríṣun àwòrán, AFP
Awọn ojiṣẹ Ọlọrun kan ti sọ pe kii ṣe oogun oloro nikan lo maa n da idile ru.
Wọn ni iwa buburu ati ailẹkọọ ile lo maa n fa lọpọ igba.
Awọn ojiṣẹ Ọlọrun naa lo sọ ọrọ ọhun nigba ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ lori ọrọ kan ti alaga ajọ to n gbogun ti egbogi oloro ni Naijiria, NDLEA, Mohamed Buba Marwa ati aya rẹ sọ pe o yẹ ki awọn afẹsọna maa ṣe ayẹwo egboogi oloro ṣaaju igbeyawo.
Agba ẹlẹsin Musulumi kan, Alfah Lukman Muktar Isalẹkoto, sọ pe ìpìnlẹ̀ igbeyawo ti ko dara ati ailẹkọọ ile lo n da ọpọ idile ru laye ode oni.
O ni "Ọmọ miran ko mu igbo tabi egboogi oloro kankan, ṣugbọn agidi inu rẹ ko le jẹ ko rile ọkọ gbe tabi ki iyawo pẹ lọọdẹ rẹ."
Imaamu agba ọhun ṣalaye pe o yẹ ki awọn afẹsọna ni ẹkọ to dantọ ki wọn to wọ inu igbeyawo lọ.
O sọ siwaju si pe ẹlomiran bẹrẹ si n mu egboogi oloro nitori aṣifẹ ọkọ tabi aya.
Alfa naa ni o yẹ ki awọn afẹsọna ṣe iwadii ni kikun lori ẹnikẹni ti wọn ba fẹ gbe sile ki wọn to ṣe igbeyawo naa, kii kan n ṣe ki wọn gbe ara wọn sile tan, ki wọn to ṣẹṣẹ maa kọ ẹkọ.
O pari ọrọ rẹ pe ẹbun akọkọ ti eeyan yoo fun awọn ọmọ rẹ ni irufẹ ẹni to ba fẹsile, eyii ti yoo di baba tabi iya irufẹ awọn ọmọ bẹẹ nitori ayaba lasan ni imukumu fun awọn miran jẹ ninu igbeyawo.
Ẹwẹ, pasitọ Isaac Ajifowowe naa da si ọrọ ọhun, ti oun naa si sọ pe kii ṣe gbogbo awọn ti igbeyawo wọn tuka lo n lo ogun oloro, ṣugbọn iwa lo ju.
Pasitọ naa sọ pe idile ẹni ti ko ba mọ Ọlọrun ko le ṣe lai daru.
O ni "Ẹlomiran n lo oogun oloro lati pa ironu rẹ lẹyin ti ile rẹ ko toro mọ."
"Ṣiṣe ayẹwo oogun oloro kọ ni yoo mu ki idile layọ bikoṣe ki tọkọ-taya mọ Ọlọrun."
Pasitọ naa pari ọrọ rẹ pe "Eṣu lo n gbe inu idile ti wọn ko ba mọ Ọlọrun, ko ni nnkan ṣe pẹ oogun oloro lilo.
Lílo oògùn olóró lè yọrí sí ìwà ipá àti ikú àìtọ́jọ́ nínú ilé - NDLEA
Alaga ajọ to n gbogun ti egboogi oloro lilo ni Naijiria, Mohamed Buba Marwa ati aya rẹ ti sọ pe ṣiṣe ayẹwo egboogi oloro lara awọn ti wọn ba fẹ ṣe igbeyawo ṣe pataki fun alaafia idile.
Marwa lo sọ ọrọ naa nibi eto ti ajọ kan ti kii ṣe ti ijọba, Coal to Diamond Support Network, ṣe onigbọwọ rẹ niluu Abuja.
Iyawo Marwa, toun naa wa nibi eto naa sọ pe igbesẹ ọhun ṣe koko lode oni nitori akaimoye idile ni oogun oloro ti tu ka liapẹ si akoko ti wọn gbe ara wọn sile gẹgẹ bii lọkọ laya.
- Buhari, dẹ́kun àwọn gómìnà tó ń ṣe òfin tako fífi ẹran jẹko- Miyetti Allah
- Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ọ̀gágun Mahamady Doumbouya tó dìtẹ̀ gbàjọba lọ́wọ́ Ààrẹ Alpha Condé ní Guinea
- Pásítọ̀ Enoch Adeboye ṣàlàyé ìdí tó fi jọ́sìn ní C&S Wòlíì Esther Ajayi
- Ìgbẹ́jọ́ yóò tẹ̀síwájú lórí ẹjọ́ tí Sunday Igboho pe DSS àti Malami
Marwa, ti Shehu Dankolo, to jẹ ọkan gboogi lara awọn oṣiṣẹ NDLEA ṣoju fun sọ pe yatọ si igbeyawo, oniruru iṣoro ni egboogi oloro maa n fa ninu igbe aye awọn to n lo.
O ni "Irufẹ igbe aye ti awọn eeyan n gbe maa n sọ bii ọjọ ọla agbegbe tabi orilẹ-ede wọn yoo ṣe ri."
"Yatọ si pe oogun oloro maa n tu igbeyawo ka, o le fa oniruru aisan si eeyan lara, o tun maa n fa iwa ipa lawujọ, to fi mọ iku aitọjọ."
Nigba to n sọrọ, iyawo Marwa, Hajia Munirat Marwa sọ pe awọn ọdọ gbọdọ mu ṣiṣe ayẹwo oogun oloro fun ẹnikẹni ti wọn ba fẹ gbe sile ni ọkan pataki lara awọn imurasilẹ eto igbeyawo naa.
O ṣalaye pe iyatọ wa laarin ayẹyẹ ọjọ igbeyawo ati gbigbe papọ gẹgẹ bii lọkọ-laya lẹyin ayẹyẹ igbeyawo ọhun.
Munirat Marwa pari ọrọ rẹ pe awọn afẹsọna gbọdọ ṣe ayẹwo ẹnikẹni ti wọn ba fẹ gbe sile lọna ati wọgile awọn iṣoro igbeyawo kan bii lilu nilu bara, ija ojoojumọ ati bẹẹ bẹẹ lọ..



















