Oba Ogboni: Bí ìwọ́de Yoruba Nation bá tún wáyé, màá bá wọn kópa níbẹ̀
Ọba Ogboni Abalaye, Tajudeen Bakare ti kede pe ahamọ ti oun wa, awọn alalẹ lo fi oun pamọ nitori ibi to le fẹ sẹlẹ si ohun, ka ni oun ko si ni ahamọ ni.
Bakan naa lo ni Sunday Igboho to wa ni ahamọ ni Cotonou, awọn alalẹ lo fi pamọ sibẹ, ko le wa laaye, ki ọpọ ewu si le re kọja lori rẹ lo se wa nibi to wa.
Ọba Ogboni lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ tun kede pe, kii se pe oun yi awọn ọrọ ti oun sọ lasiko iwọde pada lẹyin ti awọn ọlọpaa mu oun tan gẹgẹ bi awọn kan se n sọ kiri.
O fikun pe ohun to sẹlẹ laarin ọjọ kẹta si ikẹrin osu Keje ọdun yii tawọn ọlọpaa mu oun pe oun se iwọde, to ba sẹlẹ si ẹlomiran, yoo ti ku.
- Ẹ dẹ́kun lílo Kurani àti Bibeli nìkan láti fi búra fún àwọn olóṣèlú wa, ẹ jẹ́ ká fí ńkan ìṣẹ̀mbáyé kún un- Oba Ogboni Iwase
- Kò tíì tó àsìkò pé kí Nàìjíríà pín ṣùgbọ́n...- Olowu ilẹ̀ Kuta
- Oṣù mẹ́ta ni mo lò nílé ìwòsàn lẹ́yìn tí 'Mopol' fọ́ ìgo 'Coke' lórí mi ní LASU- Babatunde Gbadamosi
- Kò sí bí wọ́n á ṣe máa ka ọta ìbọn fún Sọ́jà tí a maa lè borí Boko Haram- Olagunsoye Oyinlola
- Ǹkan kò lè dẹ̀rọ̀ ní Nàìjíríà láì ṣe pé á ní ìjọba míì nítorí Buhari ti dàgbà jù- Senato Fadahunsi
- Ọkùnrin mẹ́wàá ló ti fipá bá mi lòpọ̀ rí, àbúrò ìyá mi lálákọ́kọ́- Oluwatobi Raji
Nigba to n fesi lori iwoye awọn araalu pe ojo ni ati pe o yẹ ko poora mọ awọn ọlọpaa lọwọ ni, to ba jẹ pe lootọ lo jẹ Ọba Ogboni, Bakare ni ootọ ni ohun ti wọn sọ.
Amọ o ni eeyan mẹfa lo wa ninu mọto pẹlu oun lasiko ti ọlọpaa mu awọn, ti awọn eeyan naa kii si se ọmọ ẹgbẹ awo Ogboni.
O ni ti oun ba wa poora, ti awọn yoku si wa ni ahamọ ọlọpaa, ki ni yoo jẹ ipin wọn, idi si ree ti ohun ko fi poora lọna ati daabo bo awọn eeyan ti wsn mu pẹlu oun.
Ọba Ogboni ni oun ko mọ ohunkohun nipa ẹsun ipaniyan tawọn ọlọpaa pada fi kan oun nitori wọn ko ba ibọn lara oun lọjọ naa.



