Blind Couples: Pẹ̀lú ìpèníjà ojú, tọkọtaya bímọ mẹ́ta, tí wọn sì tún ń ṣiṣẹ́ olùkọ́
Ọrọ Oluwa ẹdẹ ni, bẹẹ si ni ni awamaridi ni pẹlu nitori ero rẹ kọja ti ẹda.
Ẹ wo tọkọtaya yii, Malaam Sulaiman Abdulquadri ati aya rẹ, Mujidat ni wọn ni ipenija oju, amọ ti wsn pinnu lati fẹ ara wọn.
Nigba ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ, tọkọtaya Abdulquadri ni ọpọ ikorira, idẹyẹsi ati aropin lawọn n koju lọdọ awọn eeyan awujọ, ti wọn ro pe awọn ko le se rere laye.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- 'Níbo lo ti gbé ọmọ aràrá wa ni bàbá mi kò bá bi ìyá mi' - Aràrá adájọ́
- Mo fẹ́ ọkọ mi torí bó se ń kọrin, kìí se torí owó - Ìyàwó Aràrá
- 'Ojú inú mi ni mo fi ń rí àwọn irinṣẹ́ tí mo fi ń ṣe mọkálíìkì'
- Ìpèníjà ojú kò ní kí ń má ṣiṣẹ́ ‘DJ’ - Etu Sodiq Omotayo
- Wo ìṣẹ̀lẹ̀ márùn-ún tí kò bá pín Nàíjíríà sí yẹ́lẹ-yẹ̀lẹ
- Eji Gbadero, ọmọ Ibadan àti jayé-jayé ọmọ ónílẹ̀ ti wọn yẹgi fun l'Eko
- Lisabi Agbongbo Akala rèé, ẹni tó fi ìfẹ́, ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ gba ilẹ̀ Ẹ̀gbá lọ́wọ́ ìmúnisìn
- Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò kó tó jọba
Ọkọ ni awọn obi oun bi oun ni afọju ni nigba ti aya salaye pe, arun ẹfọju oju Glaucoma lo fọ oun loju.
Lọwọ lọwọ bayii, ọmọ mẹta ni Ọba Oke fi jinki wọn, ti wọn si tun n sisẹ olukọ.
Awọn mejeeji wa n rawọ sawọn ẹlẹyinju aanu ọmọ orilẹede yii, lati dide iranwọ owo fun wọn ki wọn le pari ile wọn ti wọn n kọ lọwọ.