Guinea coup: Mọ̀ si nípa ọ̀gágun Mahamady Doumbouya tó dìtẹ̀ gbàjọba lọ́wọ́ Ààrẹ Alpha Condé*

Oríṣun àwòrán, EPA
Ọjọ karun un, oṣu Kẹsan an, ọdun 2021 ni awọn ọmọ ogun gbajọba lọwọ Aarẹ Alpha Condé ti orilẹ-ede Guinea lẹyin ti wọn ti kọkọ ṣina ibọn bolẹ nile rẹ.
Lẹyin naa ni ọgagun Mahamady Doumbouya kede lori ẹrọ amohunmaworan ilẹ naa kan pe awọn Ologun ti gbajọba lọwọ alagb ada.
O si sọ pe awọn ọmọ ogun yoo gbe ijọba fun ẹlomiran wọọrọwọ ti akoko ba to.
- Wo awọn ‘Apps’ to le e ṣe akoba fun ẹni to ba ni si ori foonu rẹ
- Bó o bá fí ''Earpiece" sétí lásìkò tó ǹ wakọ̀, ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà ni
- Wo bí wọ́n ṣe le mọ́ irú èèyàn to jẹ́ àti àìsàn tó ń ṣe ọ́ láti pasẹ̀ ‘Handwriting’ rẹ
- Ìsoro ńlá ló ń kojú Arsenal lọ́wọ́ yìí, eléyìí kò ṣẹlẹ̀ rí o- Arteta pariwo
- Okele yin réè o, Mo dúpẹ kò sí nkán tó ṣé mí!
- Whitemoney, Queen, Pere, Angel, Boma kọjú ìjà sí ara wọn nínú ilé Big Brother Naija
Agbegbe Forecariah, to wa ni iwọ oorun Guinea ni ọgagun naa n gbe ki iṣẹlẹ iditẹgbajọba naa to waye.
O kawe gboye nile ẹkọ "War College" ni France, o si ni iriri iṣẹ ogun jija fun ọdun marundunlogun lẹyin to ti lọ foju wina ogun ni Afganistan, Cote d'Ivoire, Djibouti ati Central African Republic.
Doumbouya ṣiṣẹ ni France pẹlu ileeṣẹ ọmọ ogun rẹ titi di ọdun 2018 ki Aarẹ Condé to fiwe pe wale lati wa dari ikọ "Special Forces" ilẹ ọhun ti wọn n pe ni GFS.
Aarin ọdun 2018 yii kan naa ni awọn ileeṣẹ iroyin kan ni Guinea ti bẹrẹ si n kọ awọn iroyin kan nipa ọgagun ọhun lori awọn iwa aṣemaṣe kan ti wọn fi kan an.
Ninu oṣu Karun un ọdun 2021 yii, Doumbouya wa lara awọn eeyan marundinlọgbọn ti ajọ EU fi ẹsun titẹ ẹtọ ọmọniyan loju kan ni Guinea, koda iroyin kan tilẹ sọ pe wọn ti mọle ni saa kan lori ọrọ kan naa.
Ninu oṣu Kẹjọ ọdun 2021 yii kan naa, iroyin ni wọn wọgile iwe ẹbẹ Doumbouya lati gba iwe irinna gẹgẹ bii ọmọ orilẹ-ede France nitori awọn iwa to n wu ti ko ba ti orilẹ-ede naa mu.
Bẹẹ naa ni awọn kan n sọ pe ọwọ ọgagun naa ko mọ nitori awọn dukia to jẹ tirẹ, eyii to kọja iye owo to n gba loṣu lọ.
Apa ila oorun ẹkun Kan ni Ọgagun Mamady Doumbouya ti wa lorilẹede Guinea.
Doumbouya lọ sí ilé ìwé awọn ọm'ogun War College niluu Paris lorilẹ ede France.
Iriri ọdun mẹẹdogun ni Doumbouya ti ni lẹnu iṣẹ ologun.
Ọgagun Doumbouya ṣe iṣẹ apẹtu sija lorilẹ ede Afghanistan, Ivory Coast, Djibouti, CAR.
O tun ti ṣiṣẹ ri ni Israel, Cyprus, UK ati orileede Guinea ri.
Ọgagun Doumbouya tuntun ṣiṣẹ pẹlu ile iṣẹ ologun France lọdun 2018 nigba ti Ààrẹ Conde ni ko wa da ẹgbẹ ológun GFS silẹ ní Guinea.
Ki lawọn eeyan Guinea n sọ nipa Mamady Doumbouya?
Oríṣìíríṣìí iroyin lo ti n jade nipa Ọgagun Doumbouya lorilẹ ede Guinea.
Iroyin kan jade lọdun 2021 pe Doumbouya ko ri iwe ọmọ onilu orilẹ-ede France gba nitori ihuwasi rẹ lodi sí ìlànà ileeṣẹ ologun France.
Bakan naa tun ile iṣẹ Friaguinee tun sọ pe bi o ti ni ọrọ rẹ kò hàn sí ọpọ èèyàn.
Friaguinee béèrè pé nibo ni Ọgagun Doumbouya ti ri owo ti o fi kọ oríṣìíríṣìí ile nigba ti owo oṣu rẹ kò ju $500 lọ.
Doumbouya wa lara awọn ọgagun mẹẹdogun ti wọn kede fún ijiya EU lori ẹsun titẹ ẹtọọ ọmọniyan mọlẹ.
Ẹwẹ, ajọ iṣọkan ilẹ Afrika, AU, to fi mọ ajọ EU at ECOWAS ti bu ẹnu atẹ lu iditẹgbajọba naa, wọn si ti sọ fun Doumbouya atawọn ẹmẹwa rẹ ki wọn da ijọba naa pada fun awọn alagbada lai fọta pe















