Babatunde Usman: Òṣèré tíátà Okele ṣé fídíò síta,ẹ gbọ́ nkán tó sọ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Instagram/okele_2bali
Osere tiata Yoruba nii, Babatunde Usman ti gbogbo eeyan mọ si Okele ti fi ọrọ idupẹ ranṣẹ sawọn ololufẹ rẹ lori aarẹ to de mọlẹ laipẹ.
Ninu fọnran fidio kan to fi si oju opo rẹ ni Instagram lo ti fi ikini yi ranṣẹ.
O ni ohun dupẹ pupọ paapa lọdọ awọn to pe tabi ti wọn fi ọrọ ikini ranṣẹ lasiko toun wa lori aarẹ.
Lọjọ Aiku to kọja yi lo ṣe fidio naa sita ti o si jọ pe ko si nkankna to ṣe ninu fidio naa.
''Fun awuyewuye orisirisi to n lọ lori ayelujara pe ki ẹ gbadura fun Okele.Okele ree, ko si nkankan to ṣe mi''
Babatunde ṣe ọrọ naa lowelowe to si ni ''mo dupẹ pe awọn to gbe koto ko gbẹ jin, ẹni to ko si naa Ọlrun ko ni ko da lapa''
O ni oun ni lati ṣe fọnran fidio naa sita lati dupẹ lọdọ awọn eeyan ati lati fi han ko si nkankan to ṣe oun.
Ọmọ bibi ipinlẹ Kwara ni adẹrinposonu ẹni ọdun mejilelogoji yi to si ti n ba ere tiata bọ to nkan bi ogun dun sẹyin.

Oríṣun àwòrán, okele_2/Instagram
Àìsàn wo ló ń bá Okele, òṣèré tíátà finra, tó fi dèrò ilé ìwòsàn?
Gbajugbaja adẹrinposonu nni, Babatunde Usman ti ọpọ eeyan mọ si Okele, lo ti di ero ile iwosan bayii nitori aidape ara.
Osere tiata miran, to jẹ ọrẹ timọtimọ si Okele, eyiun Saliu Gbolagade ti awọn eeyan tun n pe ni Ogboluke lo kede bẹẹ ninu fidio kan to fi soju opo Instagram rẹ.
Ogboluke, ẹni to n fi fidi naa fi ọrọ ransẹ si awọn eeyan kan lagbo tiata salaye pe kii se pe Okele mọọmọ fara pamọ lati mase yọju sibi ere sinima kan ti wọn pe si ni.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Wàhálà lẹ̀ ń wá tẹ́ ẹ̀ bá tú Sunday Igboho àtàwọn èèyàn rẹ̀ mẹ́rin sílẹ̀ ní àhámọ́ - Ọmọ Nàíjíríà lókè òkun
- Ẹ wo àtúpalẹ̀ bí Bobrisky ṣe ná ₦500m péré láti ṣe ọjọ́ ìbí mi
- Àwọn tó lu ₦6trn owó àjọ NDDC ní póńpó rugi oyin - Buhari fọnmú
- Kí ló dé tí Oluwo àti ìyàwó rẹ̀ àná ń sòkò ọ̀rọ̀ síra wọn lórí ayélujára?
- "Ojú mi rí màbo lásìkò tí mo lọ gbé N2.5m fáwọn jàndùkú tó jí ẹbí mi gbé"
- Wo ohun mẹ́rin tó lè mú ikú wá lásìkò ìbálòpọ̀
- Ẹ se mẹ̀dọ̀ ẹ̀yin olórí Fulani, ẹ yé tàbùkù àṣà Yorùbá nílẹ̀ wa mọ́ - YCE kìlọ̀
Amọ Ogboluke ni ko si ẹni ti kii rẹ, aidape ara lo gbe Okele sanlẹ, to si ti wa nile iwosan nibi to ti n gba itọju.
Osere tiata naa ni ti kii ba se pe oun wa sile iwosan naa lati fidi ootọ ọrọ mulẹ, oun naa ko ba ti mọ pe oun to n se Okele gbopọn pupọ.

Oríṣun àwòrán, ogboluke/Instagram
Ogboluke wa yan pe "Kii se pe mo se fidio yii lati bẹbẹ owo fun itọju Okele, amọ mo fẹ fidi rẹ mulẹ fun awọn eeyan to ni Okele n fi aisan parọ ni ko ma ba wa ya ere.
Ko yẹ ki eeyan sọ pe o fi aisan parọ, ni set ti emi naa ti n bọ, wọn lo fi aisan parọ ni, pe ko wa.
Emi dẹ mọ ẹni ti mo n pe, mo dẹ n sọ fun wọn pe o ni nnkan kan to sẹlẹ, amọ ka sa dupẹ lọwọ Ọlọrun ni.
N ko fẹ sọ pe ipo ti Okele wa critical amọ ka sa dupẹ lọwọ Ọlọrun sa."
Ogboluke wa gbadura fun Okele pe Ọlọrun ko ni jẹ kawọn sunkun lori rẹ, to si ni ọwọ aye ko ni tẹ nitori ẹni to n pa araye lẹrin ni, ko si ni sunkun lasẹ Ọlọrun Ọba.
Ninu fidio naa la ti ri Okele to sun sori ibusun, ti wọn n fa omi ati oogun si lara pẹlu rọba kan ti wọn so mọ apa ati imu rẹ.
Bakan naa ni rọba kan wa ni ọwọ isalẹ to lọ sinu ọra nla kan, ti itọ rẹ da rogun si, ti Okele si n se amin si awọn adura ti Ogboluke n se.
Sugbọn Ogboluke ko sọ pato iru aisan to n ba Okele wọya ija, to fi da wolẹ sile iwosan to ti n gba itọju.


















