Sunday Igboho: Oodua Worldwide laago ìkìlọ̀ lórí ewu tó ń bọ̀ tí Sunday Igboho bá ṣì wà láhàmọ́ọ́

Oodua

Oríṣun àwòrán, Others

Ẹgbẹ awọn ọmọ Yoruba ni oke okun, Oodua Worldwide ti kesi ijọba apapọ lorilẹede Naijiria, lati tu oloye Sunday Igboho silẹ ni ọgba ẹwọn ni Benin Republic.

Ẹgbẹ naa ni igbesẹ yii nikan ni ọna kan soso to le dena wahala to le bẹ silẹ ni Naijiria lori bi wn se mu ajijagbara Yoruba naa si ahamọ, ti wn ko si tun gba idande mẹrin lara ẹsọ rẹ.

Ẹgbẹ Oduduwa naa fi ero wọn lede ninu atẹjade kan ti wọn pe akọle rẹ ni ‘Oodua Worldwide Calls For Igboho, Others Immediate Release', eleyii to tumọ si pe ki wọn fi Igboho ati awọn oluranlọwọ rẹ silẹ ni kiakia.

Igboho wa ni ahamọ lọwọlọwọ lorilẹede Benin Republic nigba ti awọn oluranlọwọ Igboho mẹrin miran ṣi wa ni ahamọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ lorilẹede Naijiria, DSS.

Ọjọ Kini, Osu Keje, ọdun 2021 ni Ajọ DSS yabo ile Oloye Sunday Igboho to saaju ipe fun idasilẹ orilẹede Naijiria, ti wọn si ko awọn olubaṣiṣẹ rẹ mejila to wa ni ile rẹ lasiko ikọlu naa.

Àkọlé fídíò, Oba Ogboni: Bí ìwọ́de Yoruba Nation bá tún wáyé, màá bá wọn kópa níbẹ̀

Amọ ni Ọjọ Kẹrindinlogun ni wọn mu Igboho ni Cotonou, lorilẹede Benin Republic nibi to ti n gbiyanju lati rin irinajo lọ si orilẹede Germany pẹlu iyawo rẹ.

Ninu ọrọ rẹ, Aarẹ Oodua Worldwide to kalẹ si orilẹede Canada, Ọmọọba Adewale Julius Ojo rọ awọn lọbalọba lorilẹede Naijiria ati awọn adari lati maṣe sinmi lori ọrọ Igboho ati bi yoo ṣe gba itusilẹ.

Ojo ni ijọba Naijiria hu iwa buruku pẹlu bi wọn ṣe yabo ile Igboho, ti wọn si fi panpẹ mu awọn oṣiṣẹ rẹ.

Bakan naa ni wọn kesi aarẹ Buhari lati ri pe wọn tu Igboho silẹ ni kiakia ati awọn mẹrin to wa ni ahamọ DSS lẹyin ti wọn fi awọn mẹjọ ninu awọn mejila silẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ki lo de tawọn agbebọn ati alajẹbanu se n yan fanda ni Naijiria ti Igboho si wa ni ahamọ?

Ẹgbẹ awọn ọmọ Yoruba ni oke okun, Oodua Worldwide fikun pe ohun to le e ran ijọba Naijiria lọwọ ki awọn eniyan le ni igbagbọ ninu rẹ ni lati tu Sunday Igboho silẹ ko ma a lọ ni alaafia.

Ẹgbẹ naa ni ko bojumu bi Igboho ṣi ṣe wa ni ahamọ ti wọn si ti fi lara awọn oluranlọwọ rẹ mẹjọ silẹ.

Àkọlé fídíò, Kayeefi: Àdììtú tó rọ̀ mọ́ ìdí tí ìlú Okeluse ṣe fi ọmọ ọdún 16, tó wà ní JSS 2 jọba

'' A ko mọ idi ti awọn agbesunmọmi, awọn ọbayejẹ onijẹkugudujẹra fi n rin kaakiri ni Naijiria lai si nkankan, ti ijọba ṣe si wọn, amọ awọn araalu ti wọn n bere fun ẹtọ wọn ni wọn n timọle.''

''Ẹtọ awọn ọmọ Naijiria ni lati bere fun idadurio orilẹede ti wọn yan laayo, nitori naa ko yẹ ki ijọba Naijiria doju ija kọ wọn.''

Ẹgbẹ awọn ọmọ Yoruba ni oke okun, Oodua Worldwide ni igbagbọ awọn ni pe ọna abayọ ni ki ijọba gba alaafia laaye nipa titu awọn to wa ni igbekun silẹ, ki Naijiria tuntun le waye lai si wahala kankan.