YCE: Níbo lẹ ti rí Yorùbá lókè ọya tó ń gun ẹṣin kiri àdùgbò pẹ̀lú èrò lẹ́yìn?

Awọn Fulani

Oríṣun àwòrán, OYSG

Ẹgbẹ agbaagba nilẹ Yoruba, YCE ti kilọ fawọn Fulani to wa nilẹ Yoruba pe kí wọn ye bu ẹnu àtẹ lu aṣa ati iṣe Yoruba lagbegbe ti wọn ba n gbe.

Ẹgbẹ YCE ni awọn ko ni k'awọn Fulani ma ni aṣoju nilẹ Yoruba, amọ wọn ko gbọdọ tabuku aṣa awọn to gba wọn ni alejo.

Aarẹ ẹgbẹ YCE tẹlẹ rí, Dansaaki Samuel Agbede lo fidi ọrọ yii múlẹ.

Agbede ni ẹgbẹ YCE wà fún idaabobo ati igbelarugẹ aṣa ati iṣe Yoruba ti o niṣe pẹlu "ọmọluabi."

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Agbede ni lati ilẹ ni ẹgbẹ YCE kii ti ṣegbe lẹyin ẹnikan lori ọrọ oṣelu tabi ẹsin ṣugbọn kò fi ọrọ ilẹ Yoruba ṣere rara.

Nipa ti o n fesi si atẹjade kan ti ẹgbẹ kan ti orukọ rẹ n jẹ Igbimọ Apapọ Yoruba Lagbaaye fi sita, Agbede ni oni imọtara ẹni nìkan àti ọdalẹ lawọn ẹgbẹ naa.

Àkọlé fídíò, Femi Branch: Gbogbo dúkìá mi àti ti ìyá mi ni mo tà láti tọ́jú ẹsẹ̀ mi fún ọdún méjì

Ẹgbẹ YCE fidi rẹ múlẹ pe ẹgbẹ kẹgbẹ tabi ẹya kẹya to ba wa nibi kibi ni Naijiria, lẹtọọ lati ni adari.

Ṣugbọn ohun ti wọn ko gbọdọ ṣe ni ki wọn maa tabuku aṣa ati iṣe awọn to gba wọn ni alejo.

"Nibo ni ẹ ti ri ibi ti awọn Yoruba ni Oke Ọya ti n gun ẹṣin káàkiri adugbo pẹlu ero lẹyin wọn? Ṣe iru eyi le ṣẹlẹ laelae ni Oke Ọya?

Wọn ni lati tẹ ilẹ jẹjẹ, nitori bi Yoruba ṣe gb'awọn ni alejo ko tumọ si pe ọdẹ ni iran Yoruba.

"A ko sọ pé Yoruba ko le ba awọn ẹya mii gbe mọ, a ti gba ọpọ ẹya mii lalejo tipẹ.

Ṣugbọn awọn iṣẹlẹ ijinigbe pawo, ipaniyan at'awọn iwa ọdaran to ti pọ bayii ni a koro oju sí.

A ko le maa ka ọwọ gbera ki a maa wo bi awọn Fulani ṣe n ṣọṣẹ nilẹ Yoruba," Agbede ṣalaye.

Àkọlé fídíò, Oba Ogboni: Bí ìwọ́de Yoruba Nation bá tún wáyé, màá bá wọn kópa níbẹ̀