Buhari: Femi Falana ní àṣírí ti tú pé $2.1bn owó ohun ìjagun làwọn ọ̀gá ológun pín mọ́ ara wọn lọ́wọ́

Awọn ọmọ ologun

Oríṣun àwòrán, Nigeria Army

Gbajugbaju amofin agba Femi Falana ti kọ iwe si aarẹ Muhammadu Buhari lati siju aanu to awọn ọmọ ologun aadọrin ti wọn dajọ iku fun lasiko ijọba Goodluck Jonathan.

Bakan naa ni Falana tun n bẹ aarẹ pe bo se n dari jin awọn ọmọ ikọ afẹjẹwẹ Boko Haram to ronu piwada, naa ni ko dari jin awọn ologun naa.

Falana ni laarin ọdun 2013 si 2014 ti ilẹ wa n jagun Boko Haram, awọn ohun ija ti ko ba igba mu ni wọn ko le awọn sọja lọwọ lati lọ koju awọn ikọ mujẹmujẹ to dihamọra gidi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun pe awọn sọja naa lo beere fun awọn ohun ija to poju owo lati daabo bo ilẹ yii lọwọ ileesẹ ologun amọ se ni wsn sọ tiwọn di ẹbi, ti wsn si fi iya nla jẹ wọn.

"Dipo ki wọn dahun ibeere awọn sọja naa, se nileesẹ ologun fi ẹsun kan wọn pe agbẹyinbẹbọjẹ ni wọn nidi ogun ti Naijiria n gbe ti Boko Haram, ti wọn si ni ki wọn foju wina ofin.

Àkọlé fídíò, Femi Branch: Gbogbo dúkìá mi àti ti ìyá mi ni mo tà láti tọ́jú ẹsẹ̀ mi fún ọdún méjì

Mo gbẹnu sọ fun mejidinlọgọta ninu wọn, nigba ti awọn lọya mii duro fun awọn mejila to ku nile ẹjọ ologun nilu Abuja laarin osu kẹjọ si ikejila ọdun 2014.

Amọ sibẹ ileesẹ ologun dajọ iku fun awọn aadọrin sọja naa fun iwa iditẹ mọ orilẹede wọn."

Amofin agba naa tun ran aarẹ leti nipa iwadi to se nigba to gori aleefa ti fidi rẹ mulẹ pe owo to le ni biliọnu meji ati miliọnu lọna ọgọrun Dọla, to yẹ ki ileesẹ ologun Naijiria fi ra ohun eelo ijagun lawọn ọga ologun da gba ibomiran lọ.

O ni abọ iwadii yii lo wa safihan pe awọn aadọrin sọja naa ko ni ẹbi nipa ibeere wọn fun ipese ohun ijagun to poju owo lati doju kọ ikọ Boko Haram.

Falana wa rawọ ẹbẹ si Buhari pe ko fi awọn aadọrin sọja naa silẹ ki wọn maa lọ ni alaafia lai ni ẹsun kankan lọrun.

Amin iyasọtọ kan

Ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ sí gbangba òde, kóo rugi oyin lábẹ́ òfin tuntun

Eeyan kan n ṣe gaa si ita gbangba

Oríṣun àwòrán, other

Nipinlẹ Ọyọ ẹnikẹni ti idi ba yun, to wa lọ ṣegbọnṣẹ si ita gbangba, ẹgbẹrun marun 5000 owo itanran ni yoo san.

Ile aṣofin ipinlẹ Ọyọ lo buwọlu aba ofin tuntun naa to wa lori didena ṣiṣe gaa si gbangba ode.

Olori ile aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Họnọrebu Adebọ Ogundoyin ṣe apejuwe iwa ṣiṣe gaa si ita gbangba, gẹgẹ bi eyi ti ko ba igba mu mọ ti wọn gbọdọ fi opin si lawujọ, yatọ si pe o n ti igi bọ oju eto ilera lawujọ.

Họnọrebu Ogundoyin woye pe o le ni ọgọrin aba ofin ti awọn ti buwọlu lati igba ti awọn ti wọle ni nnkan bi ọdun meji o le diẹ sẹyin ṣugbọn aba ofin yii, gẹgẹ bi o ṣe sọ ṣe pataki pupọ gẹgẹ bi igba ọtun ni ipinlẹ Ọyọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Awọn eeyan wa gbọdọ dẹkun jiju imi kaakiri. Iwa yii a maa tan ajakalẹ arun kiri, idi si niyi ti ofin tuntun yii fi jade lati dẹkun iwa ibajẹ naa.

Aba ofin yii sọọ di ẹṣẹ fun ẹnikẹni lati ṣe gaa sita, ijiya to si wa fun un ni owo itanran ẹgbẹrun marun un naira tabi ijiya iṣẹ ilu fun ọsẹ kan gbako."

Àkọlé fídíò, Kola Tubosun: Ọ̀pọ̀ ọmọ òyìnbó ló ń kọ́ èdè Yorùbá, ẹ̀yin ọ̀dọ́ ẹ gbé èdè abínibí lárugẹ

Pẹlu agbekalẹ ofin yii bayii, o ti di ọranyan fun awọn ileeṣẹ ati onile gbogbo lati maa kọ ile igbọnsẹ si ile tabi ibi iṣẹ wọn.

Ẹnikẹni to ba kuna eyi bayii yoo fara gba owo itanran ẹgbẹrun lọna aadọta tabi ẹwọn oṣu mẹta bẹẹni ileeṣẹ to ba kuna ati kọ ile igbọnsẹọ yoo fara gba owo itanran ẹgbẹrun lọna igba naira.

Bakan naa lo fi kun un pe ẹnikẹni to ba ṣeto ayẹyẹ ita gbangba lai ṣe ipese fun ile igbọnsẹ alagbeka, iru ẹni bẹẹ tabi ileeṣẹ bẹl yoo fara gba owo itanran ẹgbẹrun lọna ọgọrun naira.