Covid-19 Vaccination: Bí àwọn aráàlú kan ṣe fara mọ́ ṣíse àbẹ́rẹ́ àjẹsára ní ọ̀rànyàn ní àwọn míì ta kò ó

Oríṣun àwòrán, State House
Ọkanojọkan ariwisi ti n waye lori igbẹsẹ ti ijọba fẹ gbe lati kan abẹrẹ Covid-19 nipa fun gbogbo eeyan ilu.
Laipẹ yii ni awọn ijọba ipinlẹ kan kede rẹ pe ẹni ti ko ba tii gba abẹrẹ naa ko ni lanfani lati ba awọn eeyan pejọ pọ ni awọn ile ijọsin bi i Mọṣalaṣi tabi Ṣọọṣi.
BBC Yoruba jade lọ si igboro lati gbọ ti ẹnu ara ilu lori igbesẹ naa, bẹẹ ni wọn ba akọroyin wa sọ ọpọlọpọ ọrọ ti ilẹ si kun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- "Alhaji Fatai, ti DSS pa nílé Sunday Igboho ni kò ríran"
- Wo ìpínlẹ̀ mọ́kànlá tí ìdaranjẹ̀ ti di èèwọ̀ ní gúúsú Nàíjíríà
- UK ya kúrò lára EU, Yorùbá le yapa lára Nàíjíría tí kò bá sí ìwé òfin tuntun - Gbadamosi, Ilana Omo Oodua
- Irọ́ ní, Taskforce ló ń gba owó gọbọi lọ́wọ́ awakọ̀ Eko, kìí ṣe àwa - LASTMA
- Afurasí ajínigbé dèrò ọrun, òmíràn kó sí pańpẹ́ ọlọ́pàá ní l’Ogun
- Ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ agbábọ́ọ́lù mójú lọ sọ́jà, bí kátàkárà agbábọ́ọ́lù ṣe dópin
- Ṣe ìgbọ̀nsẹ̀ sí gbangba òde, kóo rugi oyin lábẹ́ òfin tuntun
Arakunrin kan ti o ba wa sọrọ fi idi rẹ mulẹ wi pe, oun ko ti i gba abẹrẹ naa, bẹẹ si ni oun ko ni aniyan lati gbaa nitori ijọba orilẹede Naijiria n fi iya jẹ ara ilu.
O tẹsiwaju wi pe, ọrọ abẹrẹ kọ lo ku lọrọ orilẹede Naijira biko ṣe igbesẹ ti yoo mu ki ara tu gbogbo eeyan ilu.
Ọkunrin mii to ba wa sọrọ ṣe alaye wi pe, ko si ohun to buru ninu igbesẹ naa nitori irọrun igi ni irọrun ẹyẹ.
O ni gbogbo eeyan lo yẹ ki o gba abẹrẹ naa ,ti ijọba ba le fi idi ẹ mulẹ wi pe ko ni ṣe ijamba si agọ ara ẹnikẹni.
A tun ba awọn obinrin naa sọrọ lasiko ti a wa nigboro.
Ọkan ninu wọn ni ko ṣeeṣe ki ijọba ni ki awọn eeyan ma lọ si ile ijọsin nitori aigba abẹrẹ COVID-19.
O ni Iroyin ti awọn n gbọ ni pe awọn eeyan to gba abẹrẹ naa n ṣaisan, bo tilẹ jẹ pe ko si ayẹwo to fi idi ọrọ yii mulẹ.

Wàláhà ń bọ̀, tíjọba bá ní ká gba abẹ́rẹ́ Covid-19 ní tipá - NMA, JOHESU

Oríṣun àwòrán, Reuters
Obinrin ẹlẹẹkeji to ba wa sọrọ fi kun alaye naa wi pe ko tọ ki a maa gba abẹrẹ COVID-19 nitori pe ibinu Ọlọrun ni ajakalẹ aarun naa. O ni dipo ki a maa gba abẹrẹ naa, ohun ti o tọ ni ki a ra ọwọ ẹbẹ si Ọlọrun pe ki o dari ẹṣẹ jin orilẹede Naijiria.
Arabinrin naa tẹsiwaju pe ohun kan ṣoṣo to le mu ki oun gba abẹrẹ naa ni ti Pasitọ awọn ni ṣooṣi ba kọkọ gbaa.
O ṣeeṣe ki ijọba apapọ atawọn oṣiṣẹ lẹka eto ilera lorilẹede Naijiria bii NMA, JOHESU ati bẹẹ bẹẹ lọ o forigbari laipẹ lori kikan abẹrẹ ajẹsara COVID-19 nipa.
Ijọba apapọ yan an lọjọ Iṣẹgun pe o ṣeeṣe ki oun bẹrẹ si ni ba ẹnikẹni to ba kuna ati gba abẹrẹ ajẹsara naa wi lẹyin ti ijọba ba ti pese rẹ si arọwọto awọn gbogbo eeyan.
Oludari agba fun ajọ eto ilera alabọde lorilẹede Naijiria, NPHD, Faisal Shuaibu lo yan ọrọ naa, nibi ipade kan to ṣe pẹlu awọn akọroyin nilu Abuja.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kò sí ‘Constitution’ tuntun, kò sí ìbò ní Nàíjíríà ní 2023 - Afenifere
- Àṣírí tú lórí ìdí tí DSS kò ṣe fi mẹ́rin sílẹ̀ nínú amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Sunday Igboho - Amòfin Olajengbesi
- Akeredolu buwọ́lu òfín máfi ẹran jẹko láàrín ìgboro l'Ondo
- Ìmáàmú àgbà kan ní Abuja ti fi ìbínú sọ̀rọ̀ sí Buhari torí ìkọlù agbébọn
- O kò ní wọ ṣọ́ọ̀ṣì àti mọ́ṣáláṣí tó ò bá gba abẹ́rẹ́ Covid-19 - Ìjọba Ondo
- Owó ilẹ̀ òkèèrè ta yá, orí pípé la fi ya - Mínísítà
- Sunday Igboho fi ọ̀rọ̀ ìyànjú ránṣẹ́ sáwọn olólùfẹ́ rẹ̀ láti Cotonou
Bakan naa ni ile ẹjọ giga apapọ kan nilu PortHarcourt nipinlẹ Rivers, ti ka gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki lọwọ ko pe ko gbọdọ sọ gbigba abẹrẹ ajẹsara di ọranyan ni ipinlẹ naa.
Awọn ẹgbẹ dokita, NMA pẹlu ẹgbẹ apapọ awọn oṣiṣẹ lẹka eto ilera, JOHESU ti faake kọri lori ọrọ yii.
Bi ẹgbẹ awọn dokita ni Naijiria, NMA ṣe n sọ pe araalu ni ẹtọ lati kọ gbigba abẹrẹ ajẹsara naa, gẹgẹ bi ẹtọ ṣe wa fun wọn lati kọ gbigba itọju ilera.
Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Ondo naa paṣẹ lọjọ Aje pe, bo pẹ bo ya, awọn yoo fofin de gbogbo awọn ti ko ni ẹri gbigba abẹrẹ ajẹsara naa pe wọn ko gbọdọ wa si mọṣalaṣi, ṣọọṣi ati awọn ibudo ita gbangba miran.
Ni tirẹ Oludari agba fun ajọ eto ilera alabọde lorilẹede Naijiria, NPHD, Faisal Shuaibu ni awọn ti ko gba abẹrẹ naa n ṣe akoba fun awọn eeyan miran lawujọ ni.
O ni ko si igba ti ijọba ko ni tọ ipasẹ ipinlẹ Edo ati Ondo lori ọrọ naa lati lo ilana ofin lori wọn.
Amọṣa ẹgbẹ apapọ awọn oṣiṣẹ lẹka eto ilera, JOHESU ni igbesẹ ti ijọba n gbero naa ko mu ọgbọn dani rara.
Agbẹnusọ fun ẹgbẹ JOHESU, Olumide Akintayọ ni o di igba ti abẹrẹ ajẹsara naa ba pọ to fun araalu ki irufẹ igbesẹ naa to lee mu ọgbọn dani bi o ti wulẹ o mọ.


















