Anti-Open Grazing law: Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo buwọ́lu òfín máfi ẹran jẹko láàrín ìgboro

Oríṣun àwòrán, Akeredolu
Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti buwọlu ofin mafi ẹran jẹko nigboro nipinlẹ naa.
Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ọsẹ diẹ ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ ọhun buwọlu abadofin naa.
Eyii to n tumọ si pe ipinlẹ Ondo ti di ọkan lara awọn ipinlẹ ni iha guusu Naijiria to gbe ofin kalẹ tako fifi ẹran jẹ oko tabi da maalu laarin ilu.
- Àṣírí tú lórí ìdí tí DSS kò ṣe fi mẹ́rin sílẹ̀ nínú amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Sunday Igboho - Amòfin Olajengbesi
- Ìmáàmú àgbà kan ní Abuja ti fi ìbínú sọ̀rọ̀ sí Buhari torí ìkọlù agbébọn
- O kò ní wọ ṣọ́ọ̀ṣì àti mọ́ṣáláṣí tó ò bá gba abẹ́rẹ́ Covid-19 - Ìjọba Ondo
- Owó ilẹ̀ òkèèrè ta yá, orí pípé la fi ya - Mínísítà
- Sunday Igboho fi ọ̀rọ̀ ìyànjú ránṣẹ́ sáwọn olólùfẹ́ rẹ̀ láti Cotonou
- A ṣetán láti fi ojú àwọn onígbọ̀wọ́ Boko Haram ní Nàíjíríà hàn - Amẹ́ríkà
Ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna eto iroyin ni ipinlẹ Ondo, Donald Ojogo Buwọlu, o ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjo, ọdun 2021, ni Akaredolu buwọlu ofin naa.
Atẹjade ọhun ni "Ofin yii wa ni ilana adehun ti awọn gomina iha guusu Naijiria fẹnuko le lori nibi ipade ti wọn ṣe kẹyin nipinlẹ Eko, nibi ti wọn ti da ọjọ kinin, oṣu Kẹsan an, ọdun 2021 lati buwọlu ofin tuntun yii."
"Ofin yii jẹ ọna kan lati pana rogbodiyan to maa n waye larin awọn eeyan kan atawọn eeyan ipinlẹ Ondo."
Atẹjade naa tẹsiwaju pe ofin tuntun naa yoo tubọ mu ki irẹpọ to peye wa laarin awọn olugbe ipinlẹ Ondo, lai wo ti ẹya tabi ẹsin wọn.
Kọmiṣọna naa tẹsiwaju pe ijọba ipinlẹ Ondo yoo ṣe gbogbo ohun to yẹ lati ri daju pe awọn eeyan tẹle ofin tuntun naa.
O ni "Ijọba yoo ṣe gbogbo ohun to yẹ lati labẹ ofin lati ri pe ẹnikẹni ko tapa si ofin naa."
O pari ọrọ rẹ pe ijọba yoo tẹ ofin ọhun sita ki awọn araalu le ni anfaani lati kaa, to fi mọ awọn ohun miran to tọ ki wọn mọ nipa ofin tuntun naa.














