Boko Haram: Amẹ́ríkà ní ààrin òun àti Nàíjíríà dán mọ́ran ju Afghanistan lọ, kò sì le bàjẹ́

Boko Haram

Orílẹ̀-èdè Amẹrika ni àwọn tí ṣetán láti ran orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́wọ́ nípa fífi ojú àwọn onigbọwọ Boko Haram, tó ń fi ojoójúmọ́ ba nǹkan jẹ́ lórí lédè yii han fun araye.

Wọ́n sọ èyí di mímọ̀ ni ọjọ́ Ajé nígbàtí aṣojú Amẹrika ni Nàìjíríà, Mary Leonard ń ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn òníròyìn ni ilu Abuja.

Nígbà tí ìbéèrè jẹyọ lori nǹkan tí Amẹrika yóò ṣe láti fi ran Nàìjíríà lọ́wọ́ láti mọ àwọn tó ń ṣe onígbọ̀wọ́ fún Boko Haram ni Nàìjíríà, Leonard ni " Èyí gan ni àjọṣepọ̀ tí a fẹ́ bá Nàìjíríà ṣe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

" Mo ti sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí fún ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láàrin oṣù méjì sí àsìkò yii"

"Mi ò ní lé máa sọ kókó nǹkan tí à ó ṣe."

Ó ní kí àwọn ènìyàn mu ọ́kàn kúrò nínú pé bóyá ìbáṣepọ̀ tó wà láàrin Nàìjíríà àti ilẹ̀ Amẹrika yóò bàjẹ́ bó ṣe ṣẹlẹ̀ ní Afghanistan àti pé ìbáṣepọ̀ tó wà láàárín Nàìjíríà àti US dán mọ́rán ju ti Afghanistan lọ.

Àkọlé fídíò, Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí

"Mò ń gbọ́ tí àwọn kan ń ṣàpẹẹrẹ ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní Afghanistan, èyí kò jọ ara wọn rárá.

"Bí ẹ bá tẹtí sí nǹkan tí ààrẹ Joe Biden sọ nípa bí àwọn ọmọogun Amẹrika ṣe lọ sí Afghanistan lákọ̀kọ́ jẹ́ nǹkan tó lágbára, ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ló kú.

Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ bákan náà, olórí ọmọogun ojú òfuurufú ni Yúróòpù, Jeffrey Harrigian sọ fún àwọn oníròyìn pé, ríra ọkọ̀ ogun òfurufú ni ó túbọ̀ so àjọṣepọ̀ ilẹ̀ Amẹ́ríkà ati Nàìjíríà pọ̀ sí, èyí yóò sì mú wọn dìde ìrànwọ́ nípa ètò ààbò.

Ó ní Tucano A-29 super lọ fún àwọn àti ìjọba ni Nàìjíríà ni ajọsepọ si.

Ìròyìn sọ pé, orílẹ̀-èdè yii ń kojú ètò àbò tó burú jùlọ báyìí nítorí wàhálà àwọn agbésùmí, ìwà jàndùkú, ìpànìyàn tó ń lọ káàkiri Nàìjíríà.

Bi ó tilẹ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn agbésùmọ̀mí lo n kó nǹkan ìjà ogun tí silẹ, pàápàá jùlọ ni ìhà àríwá ìlà-oòrùn nítorí àwọn ọmọogun ń pa wọ́n, síbẹ̀ ètò ààbò ń burú sii ni.

Amin iyasọtọ kan

"Ọkàn mi gbọgbẹ́ lórí aya, ọmọ àti ẹbí mi márùn ún tí agbébọn pa lọ́jọ́ kan"

Awọn eeyan n daro nibi iklu awọn agbebọn ni ileto kan.

Oríṣun àwòrán, The sun nigeria

Awọn olugbe ilu Yelwa Zangam ni ijọba ibilẹ Jos North ni ipinlẹ Plateau ṣi n gbọn riri lori ikọlu awọn agbebọn nibẹ lọjọ marun un sẹyin eleyi to ran marundinlogoji ninu awọn olugbe ilu naa lọ sọrun ọsan gangan ti wọn si tun dana sun ọpọlọpọ ile nibẹ.

"Ọkan mi gbọgbẹ lori ajalu nla to ba emi atawọn eeyan mi yii. A ko reti irufẹ iṣẹlẹ bayii" ni ariwo ti olori ilu naa, Ajida Isa n pa lori aro.

Iyawo rẹ Susan, to jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgọta, atawọn mọlẹbi rẹ mẹfa ni wọn pa lasiko ikọlu awọn agbebọn naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ikọlu naa to waye ni aṣalẹ ọjọ Iṣẹgun ti sọ olori ilu naa sinu hilahilo tori bi agbebọn se pa ọmọ rẹ ọkunrin, Ishaya to jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlogun.

Bakan naa ni iyawo ọmọ rẹ Monica, to jẹ ẹni ọdun mejidinlogoji, ọmọ-ọmọ rẹ obinrin, Salvation Ishaya to jẹ ọmọ ọdun mẹtala ati ọmọ-ọmọ rẹ ọkunrin, Timura Ishaya to jẹ ọmọ ọdun mẹrin ba ikọlu naa lọ.

Àkọlé fídíò, Oba Ogboni Abalaye n fẹ́ kí wọ́n o má a fi ẹ̀sìn àbáláyé búra fún àwọn olóṣèlé Naijiria

Ko tan sibẹ o, Barnabas Hosea ọmọ-ọmọ rẹ ọkunrin to jẹ ọmọ ọdun mẹtadindinlogun ati ọmọ-ọmọ rẹ ọkunrin miran, Ephraim Hosea to jẹ ọmọ ọdun mẹsan wa lara awọn ti agbebọn to wọ ileto wọn yinbọn pa.

Ajida Isa atawọn mọllẹbi rẹ ti jẹun tan, pe ki wọn wọle sun ni wọn bẹrẹ si ni gbọ iro ibọn lakọlakọ ni ita gbangba eleyi to mu ki gbogbo awọn olugbe ileto naa bẹrẹ si ni sa kijokijo lati du ẹmi ara wọn.

Awọn kan lara wọn ti ko mọ ohun to n lo sare wa sile Ajida Isa gẹgẹ bii baalẹ wọn lati wa fara pamọ sibẹ.

Amọṣa, ko pẹ pupọ ti awọn agbebọn naa yi afin naa pẹlu ka, ti wọn si yinbọn pa gbogbo awọn to wa nibẹ ki wọn to sọ ina si ile naa.

Igbakeji baalẹ ileto Yelwa Zangam Haruna Adamu ṣalaye fun akọroyin iwe iroyin The Punch pe, yatọ si awọn ti wọn yinbọn pa, awọn agbebọn naa tun da ina sun ọpọlọpọ awọn olugbe ilu naa.

"Awọn mẹtadinlogun ni wọn dana sun, iye awọn ti wọn si yinbọn pa to ogun ni iye. Awọn miran ṣi wa ni ile iwosan."

Awọn ara ilu naa n na ika sawọn alamuleti wọn to jẹ Hausa/Fulani pe awọn lo wa nidi ikọlu naa nitori pe wọn n fẹ ki awọn fun wọn ni ilẹ wọn.

Àkọlé fídíò, Nítorí kí aafa lè máa rí iṣẹ́ ṣe ní wọ́n kò ṣe kó Alumaajiri nílẹ̀ tó fi di ohun tó dà yìí

Gẹgẹ bi ohun ti igbakeji Baalẹ naa sọ, ilẹ ileto naa kan ti awọn Hausa/Fulani alamuleti wọn naa n lo fun isinku wọn ṣugbọn ti wọn fẹ gba patapata eyi ti awọn faake kọri pe ko lee bọ si lo fa ija naa.

O ni nigba ti awọn Hausa-Fulani naa kọkọ de ni wọn ni ki wọn tẹdo si ilẹ naa ti wsn si n lo ibẹ fun isinku wọn. Lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti ẹni to ni ilẹ ni ki oun kuku ta a fun wọn ni wọn kọ pe awọn ko lee raa nitori pe ko si ẹni to ni ilẹ.

Adamu ni gbogbo foonu ibanisọrọ wọn ni wọn ko lọ pẹlu.

Nigba to n fesi, olori awọn ẹya Hausa ni ilu Yelwa Zangam, Alhaji Umaru ni awọn ko mọ ohunkohun nipa ikọlu naa ati pe wọn ti ko ọrọ aawọ lori ilẹ isinku naa lọ sọdọ ijọba ibilẹ agbegbe naa fun iyanju to yẹ.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Mo faramọ́ àtúntò 'Restructuring' tí kò lọ́wọ́ ìṣèlú nínú- Oba Ahmed Adeku