Yoruba Nation: Kunle Olajide ní àwọn gómìná òké ọya ní inú àwọn kò dún sí bí nǹkan ṣe ń lọ ní Naijiria

Yoruba Nation rally

Oríṣun àwòrán, Lagos Monitoring Team

Ẹgbẹ awọn agbagba ilẹ Yoruba, YCE, ti ke si ijọba apapọ lati kọ iwe ofin tuntun, ki nnkan le rọgbọ ni Naijiria.

Akọwe ẹgbẹ naa, dokita Kunle Olajide lo sọ bẹẹ fun BBC Yoruba ninu ifọrọwerọ kan.

Ṣaaju ni awọn gomina kan lati ipinlẹ mẹta ni oke ọya ti kọkọ ṣabẹwo si Olajide atawọn agbaagba miran nilẹ Yoruba, nibi ti wọn ti sọ pe bi Naijiria ṣe n lọ ko dun mọ awọn ninu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn gomina naa ni Mai Mala Buni lati Yobe, Abubakar Badaru lati Jigawa ati Atiku Bagudu lati kebbi.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Olajide sọ ohun ti wọn jiroro le lori nibi ọpọ ipade naa to waye nilu Ibadan, Eko, Abeokuta ati Akure.

Àkọlé fídíò, Oba Ogboni: Bí ìwọ́de Yoruba Nation bá tún wáyé, màá bá wọn kópa níbẹ̀

Olajide ni awọn gomina naa ṣabẹwo si oun nile, nibi ti wọn ti ni ki oun ba awọn ajijagbara Yoruba Nation sọrọ pe ki wọn jawọ ninu ijijagbara wọn.

Ṣugbọn o ni oun fesi pe ko jọ rara nitori ẹtọ wọn ni wọn ja fun, ati pe ti ijọba apapọ ba ṣe ohun to tọ, ko ni si ijijagbara kankan.

O ni "Wọn fara mọ ohun ti mo sọ nipa pe ki Naijiria ni iwe ofin tuntun ti yoo fun ẹlẹkunjẹkun lagbara lati ṣejọba lori ẹkun rẹ."

"Ṣugbọn wọn ni to ba ni ohun ti awa agbagba le ṣe lori awọn ajijagbara lati jawọ ninu ijijagbara wọn, pe ki a ba awọn bẹ wọn, ṣugbọn mo ni ko si nnkan ti mo le ṣe si."

O tẹsiwaju pe "Awọn ọmọ wa kori ri iṣẹ ṣe, pupọ ninu wọn lo n fẹsẹ gba titi kiri, o ti sun wọn. O tun ti sun awa agbagba kan gan paapaa".

Akọwe YCE naa tẹsiwaju pe "Mo sọ fun awọn gomina naa pe iwe ofin tuntun yẹn gan ni koko, eyi ti yoo fun onikaluku ni anfani lati maa ṣe ti ẹ lọtọtọ, wọn si ni awọn ti gbọ."

Àkọlé fídíò, Grace Oyin Adejobi: Bí mo bá tún ayé wá, ọkọ mi ni màá padà fẹ́

Mo sọ fawọn ara oke ọya pe ise ẹru ni ijọba Buhari n se wa - Ayo Opadokun

Ninu ọrọ tiẹ naa, adari NADECO tẹlẹ, Oloye Ayo Opadokun sọ pe awọn gomina naa wa si ile oun naa ni ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹjọ, ọdun 2021.

O ni wọn sọ fun oun pe awọn agbaagba ninu ẹya awọn lo ran awọn wa lati oke ọya.

O ni ṣugbọn nkan ti oun ba wọn sọ ni pe iṣe ẹrú ni ijọba to wa lode lasiko yii n ṣe ẹya Yoruba.

O ni oun ko ba wọn sọ ohunkohun nipa ọrọ ẹgbẹ oṣelu APC, tako nkan ti awọn iroyin kan sọ pe wọn fẹ ki wọn o dara pọ mọ ẹgbẹ oṣelu naa.

O tẹsiwaju pe, ni nkan to jẹ oun logun ni pe ijọba Buhari n yan ẹya Yoruba jẹ.

"Mo jẹ ko ye wọn pe wiwa wọn ti pẹ ju."

"Nkan ti Yoruba n fẹ ni pe ka pada si abẹ ofin ti a fi gba ominira. Ofin naa fihan pe gbogbo ẹya bi irinwo to wa ni Naijiria lo jọ ni ẹtọ si nkankan naa."