LASTMA: Àwọn awakọ̀ fí ẹ̀sùn kan awọn Taskforce, LASTMA pé wọ́n n gba owó gọbọi lọwọ wọn

LASTMA

Oríṣun àwòrán, LASTMA

Ileeṣẹ to n risi ọrọ oju popo nipinlẹ Eko, LASTMA ti ni awọn ko ni nkankan ṣe pẹlu ẹsun gbigba owo lọna aitọ lọwọ awọn awakọ nipinlẹ Eko.

Adari eto irina ni ileeṣẹ LASTMA, Bolaji Oreagba lo sọ bẹẹ lẹyin ti awọn awakọ da iṣẹ silẹ ni Ọjọ Aje kaakiri ipinlẹ Eko.

Oreagba lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni, ọrọ ko ri bẹẹ nitori awọn ko gba owo lọna aitọ lọwọ awọn awakọ, iṣẹ awọn ni awọn n ṣe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni LASTMA ko ni nnkan ṣe pẹlu wọn, awọn Ajọ Taskforce nipinlẹ Eko to n gba owo ode lọwọ awọn awakọ, ni wọn koju ija si.

''Lootọ ni awọn awakọ da iṣẹ silẹ nipinlẹ Eko nitori ẹsun pe awọn taskforce n gba owo gọbọi lọwọ wọn ni ojoojumọ, amọ kii ṣe awọn LASTMA ni wọn fi ẹsun kan.''

LASTMA

Oríṣun àwòrán, OTHERS

''A ti kilọ fun awọn awakọ ati Taskforce ki wọn ma da omi alaafia ipinlẹ Eko ru, nitori naa ni a ṣe dasi ọrọ wọn kii ṣe pe awa ni wọn fi ẹsun kan.''

Ohun ti awọn awakọ ati arinrinajo sọ nipa idaṣẹsilẹ awọn awakọ nipinlẹ Eko

Awọn arinrinajo ni agbegbe Ikorodu nipinlẹ Eko fi ẹṣẹ rin ọpọlọpọ mile ni Ọjọ Aje lẹyin ti awọn awakọ daṣẹ silẹ, ti wọn si wa ọkọ wọn gunlẹ ni ipinlẹ Eko.

Ẹsun ti awakọ fi kan awọn Taskforce to n gba owo ode nipinlẹ Eko ati LASTMA ni pe owo ti wọn n gba ni ọwọ wọn ti poju ni ojoojumọ, lai tilẹ ro ipalara ti awọn eniyan n la kọja.

Iroyin ni awọn eniyan rin ọna jinjin bii Jibowu, Maryland, Ikeja nitori ko si ọkọ ti awọn eniyan yoo wọ, nitori awọn awakọ naa wa ọkọ gunlẹ, ti wọn ko si jẹ ki awọn awakọ akẹgbẹ wọn kankan ṣiṣẹ.

Wọn fi ẹsun kan LASTMA pe awọn ofin oju popo ti ohun pin awọn awakọ lẹmi ni wọn ma n pa laṣẹ fun wọn ni oju popo.

Àkọlé fídíò, Kola Tubosun: Ọ̀pọ̀ ọmọ òyìnbó ló ń kọ́ èdè Yorùbá, ẹ̀yin ọ̀dọ́ ẹ gbé èdè abínibí lárugẹ