Football Market: Griezmann padà sí Barcelona, Chelsea ra Niguez, Tomiyasu darapọ̀ mọ́ Arsenal, Ronaldo padà sílé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọja kata kara ati pasipaarọ awọn agbabọọlu ti saa bọọlu yii wa sopin lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu kẹjọ.
Ọpọ ẹgbẹ agbabọọlu lo moju lọ si ọja, ti wọn si ri agbabọọlu gidi ra.
Manchester United wa lara iru ikọ agbabọọlu bẹẹ lẹyin ti wọn ẹlẹsẹ ayo, Cristiano Ronaldo pada.
Lati Man U yii naa ni Ronaldo ti darapọ mọ Real Madrid ko to lọ ṣoju ikọ Juventus naa lati ibi to ti pada wale.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Kò sí ‘Constitution’ tuntun, kò sí ìbò ní Nàíjíríà ní 2023 - Afenifere
- Wàláhà ń bọ̀, tíjọba bá ní ká gba abẹ́rẹ́ Covid-19 ní tipá - NMA, JOHESU
- Àṣírí tú lórí ìdí tí DSS kò ṣe fi mẹ́rin sílẹ̀ nínú amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Sunday Igboho - Amòfin Olajengbesi
- Akeredolu buwọ́lu òfín máfi ẹran jẹko láàrín ìgboro l'Ondo
- Ìmáàmú àgbà kan ní Abuja ti fi ìbínú sọ̀rọ̀ sí Buhari torí ìkọlù agbébọn
- O kò ní wọ ṣọ́ọ̀ṣì àti mọ́ṣáláṣí tó ò bá gba abẹ́rẹ́ Covid-19 - Ìjọba Ondo
- Owó ilẹ̀ òkèèrè ta yá, orí pípé la fi ya - Mínísítà
- Sunday Igboho fi ọ̀rọ̀ ìyànjú ránṣẹ́ sáwọn olólùfẹ́ rẹ̀ láti Cotonou
Pẹlu ọrọ aje Barcelona ti n ṣojojo, ikọ agbabọọlu ni lati da Antoine Griezmann pada si Atletico Madrid lati ya a lo fun saa bọọlu kan.
Ọdun meji sẹyin ni Barcelona ra Griezmann fun £103m.
Barca fi sinu adehun pẹlu Atletico pe wọn ni anfaani lati Griezmann pada ni ipari saa bọọlu yìí.
Àmọ́, Atletico ni awọn tun máa ya Griezmann lo ni ti saa bọọlu yìí bá gberasọ.
Ẹgbẹ agbaọọlu Chelsea naa mójú lọ sí ọjà, koda agbabọọlu gidi ni wọn rí mu wale.
Chelsea ya Saul Niguez ra lati Atletico Madrid fun saa bọọlu kan fún £3.4m.
Chelsea lanfaani lati ra Niguez patapata ni ipari saa bọọlu yìí fún £30m.
Niguez wa lára àwọn agbabọọlu ife ẹyẹ La Liga ni saa bọọlu tó lọ.
Arsenal naa ko gbẹyin, Takehiro Tomiyasu ni wọn ra lati Bologna fún £19.8m.
Arsenal ati orogun wọn, Tottenham ni wọn jọ n du Tomiyasu ki o to ja mọ Arsenal lọwọ.
Awọn agbabọọlu ti Arsenal ti ra ni ọja awọn agbabọọlu ni saa bọọlu yìí jẹ £150m.

















