Lekan Salami Stadium: Ìjọba Oyo fèsì padà lórí aríwísí pé omi wọ pápá tí Makinde fi N5.3bn tún ṣe

Papa isere Lekan Salami

Omi lórí pápá ìṣeré Adamasingba kìí ṣe tuntun, ó lè ṣẹlẹ níbi kíbi- Ìjọba OyoSeyi Makinde ṣí pàpá ìṣeré tó fi N5.3bn tún ṣe àmọ́ òjo bàá jẹ́ lọ́jọ́ ayẹyẹ ìṣíde

Ijọba ipinlẹ ti fesi lori iroyin to gba ori ayelujara nipa bi omi ṣe dagun si ori papa iṣere Adamasingba ti Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo

ṣi ni Ọjọ́rú.

Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ, akọwe iroyin fún Gomina Makinde, Taiwo Adisa sọ pe omi to dagun lori papa iṣere naa kii ṣe ohun ti oju ko riri.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọgbẹni Adisa ni "iru nkan bayii naa n ṣẹlẹ ní òkè òkun to fi mọ ninu idije Premier League gan an.

Ọpọ ìgbà ni a máa n ri bi yinyin ṣe maa n jabọ, ti o si máa n ṣakoba fun papa iṣere ti wọn ti n gbabọọlu.

Papa isere Lekan Salami

Oríṣun àwòrán, OYSG

Igba miiran gan an, wọn máa wọgile ere bọọlu ti yinyin ba ti pọju lori papa.

Bakan naa lo fikun pe iṣẹ atunse papa ere idaraya naa ṣi n lọ lọwọ, ti isẹ ko si tii pari patapata nibẹ.

"Agbaṣẹse to n se atunse papa isere idaraya naa ṣẹṣẹ gbin koriko sori papa ere bọọlu ọhún, ni nkan bi oṣu meji sẹyin.

Gomina Makinde si lo pinnu lati ṣi papa iṣere naa ki ẹgbẹ agbabọọlu Shooting Stars le lanfaani lati máa lo o fún igbaradi idije Super 8 wọn ni.

Ijebu Ode ni Shooting Stars ti n lọ gbabọọlu lati ọjọ yii wa, eleyii ti ko si bojumu to."

O wa fikun pe o buru jai ki odidi ilu Ibadan, to jẹ olu ìlú ijọba iwọ oorun guusu Naijiria tẹlẹ má ni papa iṣere ti ẹgbẹ agbabọọlu ipinlẹ Oyo le maa lo.

Idi niyii, ti ijọba fi tètè ṣi papa iṣere naa nigba ti agbaṣẹṣe ko ti pari iṣẹ lori papa iṣere naa.

Àkọlé fídíò, Seyi Makinde: Ẹ̀yin tẹ́ fẹ́ fi ọ̀rọ̀ ẹ̀sin ba Oyo jẹ́, ẹ ṣọ́ra ṣe

Kii se papa isere Adamasingba la na N5.3bn le lori:

Fún àwọn tí wọn n sọ pé ijọba na biliọnu marun o le diẹ naira (N5bn) lori papa iṣere lasan, Taiwo Adisa ni kii ṣe ori papa Adamasingba nikan ni owo wà fún o.

"Ipele mẹta ni iṣẹ lori papa iṣere Adamasingba yìí pin sí, agbaṣẹṣe ṣẹṣẹ n pari iṣẹ lọ lori ipele kinni ni iṣẹ papa iṣere naa ni.

Agbaṣẹṣe sọ fún ijọba pe o kere tan, o máa to oṣu mẹta ki ori papa iṣere Adamasingba tó ṣee lo daadaa.

Lara N5bn yìí naa ni agbaṣẹṣe yoo ti kọ oríṣìíríṣìí gbọngan ere idaraya pẹlu awọn ohun elo igbalode.

Bakan naa, agbaṣẹṣe yóò tún kọ ile itura sí papa iṣere yìí láti lè maa ri owo ṣe àtúnṣe papa iṣere yìí," Adisa lo sọ bẹẹ.

Amọ agbaṣẹṣe to n ṣiṣẹ atunse papa isere idaraya naa kọ láti bá BBC Yoruba sọrọ nigba ti a kàn sí lati gbọ tẹnu rẹ lori isẹlẹ to waye lana ọhun .

Amin iyasọtọ kan

Sé sàgbẹ̀lójúyòyò ni àtúnṣe pápá Lekan Salami tí Sèyí Makinde se ni? - Aráàlú ní N5.3bn wọgbó

Papa isere Lekan Salami

Nnkan ayọ ati itura ni wẹliwẹli ojo maa n jẹ lọpọlọpọ igba ti o ba rọ si ori ilẹ fun gbogbo ẹda alaye.

Ṣugbọn awuyewuye ni ojo to rọ l'Ọjọru nibi ayẹyẹ atunṣe papa iṣẹre Lekan Salami, to n bẹ ni Adamasingba mu lọwọ.

Saaju ni gomina Seyi Makinde ti kede pe biliọnu marun ati miliọnu lọna ọọdunrun naira (N5.3bn) ni oun naa lati se atunse papa isere idaraya naa.

Ọwọ eeyan si lo n foju soju sode lati pe wo papa isere awodamiẹnu naa, ti wọn lo ba tawọn ilẹ okeere mu, nigba to ba di sisi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lara awọn eto ti wọn si la kalẹ fun ayẹyẹ sisi papa isere idaraya naa ni ifẹsẹwọnsẹ ere bọọlu laarin ẹgbẹ agbabọọlu 3SC ati NK Tabor Sezana lati orilẹede Slovenia.

Ayẹyẹ iside naa bẹrẹ ni pẹrẹu ni nnkan bi i aago marun un irọlẹ, ohun gbogbo lo si n lọ leto-leto, ko to di wi pe ojo bẹrẹ ni papa iṣere naa.

Papa isere Lekan Salami

Lati ibẹ si ni ọpọplọpọ awọn eeyan ti o lọ wo iran ifẹsẹwọnsẹ ere bọọlu naa, ti bọ si ori itakun ayelujara lati fi aidun inu wọn han lori awọn kudiẹ-kudiẹ ti wẹliwẹli ojo naa tu sita lasiko ti ifẹsẹwọnsẹ n lọ lọwọ.

Lori opo ikansiraẹni Facebook, ẹnikan ti orukọ rẹ n jẹ Morufu Smith kọọ sibẹ pe, "Mo kọ iwe lati gbe oriyin fun Ṣeyi Makinde lori atunṣe papa iṣere Lekan Salami saaju ọjọ ayẹyẹ naa.

Mo si fi kun ọrọ mi pe laipẹ laijina a o mọ boya ojulowo ni awọn nnkan ti wọn tun se nibẹ.

O si ṣẹlẹ bẹẹ lasiko ti ifẹwọnsẹ n lọ lọwọ nitori ọpọlọpọ omi lo rogun si ori papa ti wọn ti n gba bọọlu, nitori ko si ibomii ti agbara ojo le ṣan si.

Àkọlé fídíò, Femi Branch: Gbogbo dúkìá mi àti ti ìyá mi ni mo tà láti tọ́jú ẹsẹ̀ mi fún ọdún méjì

Sé sàgbèlójúyòyò ni renovations tí Sèyí se ni?".

Ẹlomii to tun fi ọrọ lede, Adebisi Adeniyi ni "ọta ẹni ki i pa odu ọya", ti ariwo si sọ lórí omi tó kún pápá ìṣeré Lekan Salami,

O fi kun ọrọ rẹ pe awọn ọta ilọsiwaju lo n binu Ṣeyi Makinde nitori ojo to rọ nibi ayẹyẹ naa.

Ninu ọrọ ti ẹ, Godwin Onoghokere ni "Gomina Makinde(Ọyọ) na N5.3BN lati ṣe atunṣe papa iṣere ṣugbọn ojo tuna aṣiri iṣẹ to ni ọwọ oṣelu ninu".

Awọn ọkanọjọkan fọnran lo ti lu ori ayelujara pa, ninu eyii ti awọn eeyan ti n ṣe afihan ibi ti omi ti n jo labẹ orule papa iṣere naa.

Ọpọ araalu ti wa n beere pe ta lo jẹbi aṣiṣẹ naa laarin ijọba ipinlẹ Ọyọ ati kọngila ti wọn gbe isẹ naa fun?