Muhammadu Buhari: Ààrẹ Buhari ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àkànṣe tí òun ṣe yóò lérè lọ́jọ́ iwájú

muhammdau Buhari

Oríṣun àwòrán, other

Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ pe o di igba ti oun ba ti lọ tan ki awọn ọmọ Naijiria to lee mọ iyi oun.

Nigba to n sọrọ nilu Abuja lọjọru nigba to n ṣe ifilọlẹ igbimọ adari tuntun fun ajọ idokoowo owoolu, NSIA, aarẹ Buhari ni awọn iṣẹ akanṣe ti iṣejọba oun rawọle jẹ awọn ti yoo mu anfani ọlọjọ gbọọrọ wa fun orilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Aarẹ wa rọ awọn ọmọ igbimọ ajọ naa lati wa ọna ti orilẹede Naijiria le fi ri anfani ipawo wọle lati ẹka miran yatọ si ẹka epo rọbi nitori afojusun awọn onims nipa epo rọbi ni pe owo epo rọbi lọja agbaye yoo ja walẹ si ogoji dọla lori agba epo rọbi kan nigba ti a o ba fi wọ ọdun 2030.

Nigba to n sọrọ ni tirẹ, minisita feto iṣuna Zainab Ahmed ni owo ti wọn fi bẹrẹ iṣẹ okoowo ni ajọ naa nigba ti aarẹ wọle ni ọdun 2015 jẹ biliọnu kan dọla.

O ni owo naa ti mu ere biliọnu mẹta abọ dọla wọle fun un bayii.

Àkọlé fídíò, Femi Branch: Gbogbo dúkìá mi àti ti ìyá mi ni mo tà láti tọ́jú ẹsẹ̀ mi fún ọdún méjì