Phone Applications: Wo awọn ‘Apps’ to le e ṣe akoba fun ẹni to ba ni si ori foonu rẹ

Phone Applications: Wo awọn 'Apps' to le e ṣe akoba fun ẹni to ba ni si ori foonu rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọlọpọ awọn eniyan lo ni orisirisi 'Application' si ori ẹrọ igbalode alagbeka wọn, eleyii ti o si ti mu nkan rọrun fun awọn eniyan lati ṣe.

O kere tan ẹgbẹgbẹrun 'application' tuntun lo n jade ni ojojumọ, ti yoo si wa lori foonu ẹni to ba 'download' rẹ.

Ọpọlọpọ 'App' wọnyii ni wọn dara fun ere ṣiṣe, iṣẹ tabi lati nkan rọrun fun eniyan lati ṣe ni ọna igbalode.

Amọ, bi awọn 'app' wọnyii ṣe dara to naa ni wọn ni ewu ti o le koba eniyan, nitori awọn to ṣe agbatẹru 'app' wọnyii ma n ta iroyin to ba wa ni ori foonu eniyan fun awọn ile iṣẹ nla nla to ba n wa iroyin nipa awọn eniyan.

Lara awọn apps to le e ṣe akoba fun awọn eniyan ni yii;

Facebook: bi o tilẹ jẹpe ọpọ eniyan lo ri oju opo Facebook gẹgẹ bi oju opo ikansiraẹni ati ibanidọrẹ, o ni awọn ewu ti oju opo naa le e ko ba foonu ẹni to ba n lo o.

Bi o ṣe jẹ ọfẹ ni awọn eniyan n lọ, ibi ti ileeṣẹ naa ti n ri aje bu igba jẹ ni tita iroyin awọn eniyan fun awọn ileeṣẹ nla nla.

Ẹnikẹni to ba n lo oju opo yii, ni Facebook yoo ni anfaani lati mọ;

•ibi to wa ni igba gbogbo,

•Awọn to n pe lori foonu rẹ, to mi mọ atẹjiṣẹ

•Awọn aworan ati gbogbo nkan to wa lori foonu rẹ

•Camera rẹ ati ẹrọ igbohunsilẹ rẹ.

Tiktok

Oju opo yii wọpọ laarin awọn ọdọmọde nitori ibẹ ni wọn ti n wo awọn fiimu kekeeke ati awọn nkan to n lọ lori ayelujara.

Igba miran, awọn ti wọn fẹran, ti wọn si n wo awokọṣe wọn lori Tiktok, le fi ipenija sita 'challenge' lati wo ẹni to le e jo julọ,tabi ṣe ohun miran.

Nigba miran, awọn ipenija ere gele yii ti jasi iku awọn ọdọmọde, ti wọn n kopa ninu rẹ nitori wọn fẹ ṣe bi awọn akẹgbẹ wọn.

Phone Applications: Wo awọn 'Apps' to le e ṣe akoba fun ẹni to ba ni si ori foonu rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nitori naa, obi to ba ni 'app' yii sori foonu gbọdọ ko kuro nitori awọn ọmọ wọn,ti wọn ba wo o ju, o le mu wọn tiraka lati ṣe ohun ti wọn n wo.

QR code scanners

O le sakoba fun ẹnikẹni to ba n gba awọn 'app' yii silẹ lori ẹrọ ayelujara nitori gbogbo awọn iroyin to wa lori foonu ẹni ọhun lo le wa ninu ewu.

Amọ, yala di 'download' awọn 'apps' ti wọn fi n ya aworan atẹjade, eniyan le lo awọn 'apps' to ba foonu rẹ wa tabi ẹrọ camera foonu re lati fi ya ohun to wu u.

Light it up: Awọn 'apps' ti wọn ma n lo lati fi ri iran lori foonu lewu nigba miran.

Amọ, nibayii awọn eroja foonu ti wọn ṣẹṣẹ n ṣe nisinyii ni awọn ohun bii 'flashlight' ti awọn eniyan le fi ri iran.

Game, puzzle apps

Ọpọlọpọ eniyan lo fẹran lati ma a ta ayo lori foonu, amọ eleyii le ṣe ijamba fun awọn ohun to ba wa ni ori foonu eniyan.

Lọpọ igba, awọn to ma n ṣekọlu si ẹrọ ayelujara ma n fi eroja wọn si inu awọn 'apps' bii 'games' tabi 'puzzle', nitori naa eniyan gbọdọ sọ ara ṣe nipa awọn eroja yii.

CamScanner

Awọn eniyan ma n lo ẹrọ yii lati fi ya aworan awọn ohun ini wọn bii iwe ile, iwe ilẹ, iwe ẹri lai nilo lati lọ si ile itaja awọn eniyan ti wọn n ṣe owo yii.

Amọ, ni igba miran o le ṣe akoba fun eniyan to ba n lo ẹrọ yii lati fi ya aworan awọn nkan to ṣekoko yii, ni awọn ẹni ibi to ba wa ni idi 'app' naa ti maa ni anfaani ati gba a kalẹ.

Fax

Lilo ẹrọ yii lati fi atẹjiṣẹ ranṣẹ naa lewu pupọ, nitori o le mu ki awọn eniyan lanfaani lati ri gbogbo awọn nkan to ṣe koko to wa lori foonu ẹni to n fi atẹjiṣẹ ranṣẹ naa.

O le lo FaxZero lati fi atẹjiṣẹ ranṣẹ lai san owo fun igba marundinlọgbọn ni ojumọ.

Logo Creator

Lilo ẹrọ ayaworan yii tabi siso aworan papọ le ko ba ẹni to n lo nitori kete ti eniyan ba ti fi orukọ silẹ ni awọn oju opo wọnyii, ni awọn eniyan yoo ti ni anfaani lati wo gbogbo ohun to wa lori foonu ẹni to ba n lo ẹrọ yii.̣

Screen recorder:

Awọn ẹrọ gbigba ohun silẹ yii lewu pupo nitori kete ti eniyan ba ti lo awọn oju opo yii tabi ẹrọ yii ni awọn to ṣe agbekalẹ app yii ni anfaani lati gba ohun eniyan silẹ ati gbogbo ohun ti ẹni naa kọ si inu rẹ.