Graphology: Àǹfààní márùn-ún tó wá nínú ìmọ̀ nípa ‘Handwriting’ rẹ

Àkọlé fídíò, Graphology: Wo àǹfààní márùn-ún tó wá nínú ìmọ̀ nípa ‘Handwriting’ rẹ

Niwọn igba ti oju ti jẹ Ferese ara, bẹẹ naa ni ọwọ wa jẹ ferese si ọpọlọ.

Idi ree to fi rọrun lati mọ iru eeyan ti ẹda kan jẹ, iwa to le hu ati awọn aisan to n se iru ẹni bẹẹ lati ipasẹ ohun to ba kọ silẹ ta n pe ni Handwriting.

Gẹgẹ bi Dokita Oladipupo Macjob se salaye fun BBC Yoruba, imọ nipa awọn akọsilẹ yii ni a n pe ni Graphology.

Bakan naa ni Dokita Macjob ni imọ nipa awọn akọsilẹ yii ni anfaani orisi marun fun ẹda atawọn isẹ aayan laayo gbogbo.

Awọn anfaani ati iwulo Graphology:

  • Graphology wulo fun awọn to fẹ gba eeyan si isẹ lati mọ iru ẹda ti wọn jẹ ati iwa ti wọn le hu lati ipasẹ awọn nnkan ti wọn ba kọ silẹ.
  • Imọ nipa akọsilẹ ẹda yii tun wulo fun awsn olukọ lati mọ bi ọpọlọ awọn akẹkọ wọn se gbewọn si ati awọn iwa ti wọn le wu.
  • O tun le n fun awọn obi ni anfaani lati ni ẹkunrẹrẹ imọ nipa awọn ọmọ wọn, bi ọpọlọ wọn se dara si ati ihuwasi wọn.
  • Graphology tun wulo fun awọn agbofinro lati mọ nipa ọdaran kan tabi ẹni to huwa ọdaran lati ipasẹ ohun ti wọn ba kọ sinu iwe.
  • Nipari, imọ nipa akọsilẹ ẹda yii tun wulo pupọ fun awọn dokita lati le mọ iru aisan to n se onibara wọn wọn.
  • Awọn aisan ti dokita si le mọ pe o n se ẹda tabi to n bọ lọwọ iwaju lara rẹ, lati ipasẹ ohun ti onitọun kan kọ silẹ ni aisan kii ọwọ ati ara maa gbọn, taa mọ si Parkenson.
  • Bakan naa ni wọn le mọ pe ẹda kan ni aisan rọlaprọlẹsẹ taa mọ si Stroke lara pẹlu awọn arun ọpọlọ eyi ti ironu le fa, ta mọ si Depression.

Dokita Macjob wa rọ awọn onisẹ iwadii lati maa se amulo imọ nipa akọsilẹ ẹda naa, tii se Graphology lati fi mu agbega ba igbe aye ọmọniyan.