Nigerian Drone Maker: Roqeeb Aderogba ní ìgbà mẹ́fà l‘òun kùnà láti ṣe dírónù, kó tó yege
Ohun to ba n wu ni, nii pọ lọla ẹni, ologun ẹru ku, asọ rẹ jẹ ọkansoso, smọ ti yoo ba si jẹ asamu, kekere ni yoo ti maa jẹ ẹnu samusamu.
Lati igba ewe ni Roqeeb Aderogba ti maa n sewadi ninu ara rẹ pe bawo lo seese fun baalu lati maa fo lai naani bo se tobi si.
Igba yii si ni ọmọde naa ti pinnu pe imọ ẹrọ nipa baalu sise ni oun yoo lọ kọ ti oun ba dagba nile ẹkọ fasiti.
- N kò kàwé rí nílé ìkàwé àmọ́ èmi ni akẹ́kọ̀ọ́ tó pegedé jùlọ ní fásitì LASU - Sotunde
- Àwọn akẹ́kọ̀ọ́-bìnrin Naijiria fẹyin US ati China gbolẹ nidije ìmọ ẹrọ
- Ẹ wo àràmọ̀ǹdà ọmọ ọdún mọ́kànlá tó jẹ́ elégèé àrà tó dáńtọ́ jùlọ
- Ọmọ ọdún méjìlá ṣe katakata tó ń ṣiṣẹ́
- Ọmọ ọdún méjìlá ni mo ti ń ṣe bàálù, ọkọ̀, ilé àti ọkọ̀ ojú omi - Ọdọ́mọdé ‘Engineer’
- Ọmọọba 'The Buzz' Larbie rèé, ọmọ ọdún méje tí wọ́n ń pè ní Messi lágbo ẹ̀ṣẹ́ kíkàn
Lẹyin ti ọpọ igbiyanju rẹ lati wọ ile ẹkọ fasiti kan lorilẹede India kuna, nibi to ti fẹ lọ kọ ẹkọ nipa sise baalu, Roqeeb ba gba fasiti Ladoke Akintola, LAUTECH nilu Ogbomoso lọ.
Lautech si lo ti n kọ ẹkọ nipa imọ ẹrọ Chemical Engineering.
Amọ ipele eto ẹkọ ọlọdun kẹta lo wa to fi tun kuro nibẹ, to si lọ bẹrẹ eto ẹkọ nipa kikọ nipa baalu sise nile ẹkọ fasiti ipinlẹ Kwara.
Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Eji Gbadero, ọmọ Ibadan àti jayé-jayé ọmọ ónílẹ̀ ti wọn yẹgi fun l'Eko
- Lisabi Agbongbo Akala rèé, ẹni tó fi ìfẹ́, ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ gba ilẹ̀ Ẹ̀gbá lọ́wọ́ ìmúnisìn
- Ọba Lamidi Adeyẹmi, òṣìṣẹ́ adójútòfò àti Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò kó tó jọba
- Irú ẹ̀dá wo ni Lamidi Adeyemi? Aláàfin tó rí ìbẹ̀rẹ̀ àti opin sáà gómìnà mọ́kànlélógún l‘Oyo
- Wo ọ̀pọ̀ àṣeyọrí tí Aláàfin ṣe láti àádọ́ta ọdún tó ti jọba
- Kíni ìwọ mọ̀ nípa Funmilayọ Ransome-Kuti?
- Sanusi Adebisi Idikan rèé, olówó tó ń san owó orí fún gbogbo ọkunrin ilẹ̀ Ibadan
Lọwọ lọwọ bayii, Roqeeb ti se baalu kekere ayaworan dironu, taa mọ si Drone, lẹyin igba to ti kuna fun igba mẹfa ọtọọtọ lati se e.
Roqeeb Aderogba ba BBC Yoruba sọrọ nipa iriri rẹ naa, to si se afihan awọn baalu kekere to ti se.



