Pásítọ̀ Enoch Adeboye ṣàlàyé ìdí tó fi jọ́sìn ní C&S Wòlíì Esther Ajayi

Oríṣun àwòrán, Instagram/Rev Esther Ajayi
Pasitọ Agba ijọ RCCG, Enoch Adeboye ti ṣalaye idi to fi lọ si ibi ayẹyẹ ṣiṣi ile ijọsin Love of Christ Worship Centre, nilu Eko.
Ọjọ Aiku, ọjọ karun-un, oṣu Kẹsan-an, ni wọn ṣi ile ijọsin Kerubu ati Serafu ọhun, to jẹ ti gbajugbaja wolii obinrin, Esther Ajayi, ni adugbo Victoria Island nilu Eko.
Nibi ayẹyẹ naa si ni Pasitọ Adeboye ti waasu, to si rọ awọn ọmọ ijọ lati kesi Ọlọrun fun ojuutu laarin rogbodiyan aye.
Lasiko iwaasu naa lo ti sọ pe ẹnikan beere lọwọ oun ni ọjọ Satide, ti ayẹyẹ ile ijọsin naa ku ọjọ kan pe "ṣe o da yin loju pe ẹ fẹ ẹ lọ waasu niru ile ijọsin yẹn'.
Pasitọ Adeboye ni ẹni naa sọ pe o ṣoro fun oun lati gbagbọ, amọ mo sọ fun pe "o jẹ gbagbọ".

Oríṣun àwòrán, Instagram/Rev Esther Ajayi
O tẹsiwaju lati sọ ninu iwaasu rẹ pe Ọlọrun lo ni ki oun lọ fun ayẹyẹ naa.
"Ti Ọlọrun ba si ti sọ pe ki n lọ si ibi kan, o le jẹ nitori eeyan kan ṣoṣo to fẹ ẹ fun ni anfaani ikẹyin ni. O le jẹ iwọ. Mo bẹ ọ, yọnda aye reẹ fun Jesu."
Kikopa ti Pasitọ Adeboye kopa nibi eto isin ijọ C&S ọhun ti n fa oriṣiriṣi awuyewuye lori ayelujara, paapaa laarin awọn eeyan ti ko lero pe o le lọ si iru ijọsin bẹẹ.
Lara awọn eekan ilu to tun kopa nibi ijọsin naa ni Oloye Olusegun Obasanjo, Ooni Ile-Ife, Oba Adeyeye Ogunwusi, Oluwo ti Iwo, Oba Abdurasheed Adewale, Rochas Okorocha, ati awọn miran.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Rev Esther Ajayi

















