Kayeefi: Àdììtú tó rọ̀ mọ́ ìdí tí ìlú Okeluse ṣe fi ọmọ ọdún 16, tó wà ní SSS 2 jọba
Yoruba ni ori ti yoo de ade, ko ni se alai dade, ọrun ti yoo si wọ ilẹkẹ, ko ni salai wọ ọ, bakan naa ni ibadi ti yoo lo mọsaji, asọ ọba to jinna koro-koro, ko kuku ni se alai wọ.
Ni abala eto Kayeefi wa fun ti ọsu yii, bi ọrọ se ri ree pẹlu ọmọdekunrin kan to gbe ori aye waye, to tii kekere di baba ilu, ọkọ oso, ọkọ ajẹ, to si n se akoso odidi ilu fun lati ọmọ ọdun mẹrindinlogun.
Ọba Oloyede Adekoya Adeyeoba Akinrhare keji, tii se Arujalẹ Ojima tilu Okelusẹ, to wa ni kilaasi ikẹkọ agba keji tile ẹkọ girama, JSS 2, si la gbọ pe oun ni ọba ti ọjọ ori rẹ kere julọ nilẹ Yoruba lọdun 2019 to gori itẹ.
- Eyí ni àwọn arẹwà 'ẹ̀lẹ̀ Daddy', àfẹ́fẹ́ tí Aláàfin fi ń mí
- ₦35,000 ni mò ń gbà bíi Adelé ọba, kò sí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ - Adelé Olúbọ̀rọ̀pa
- Bàbá Aláàfin ìlú Ọ̀yọ́, Elérúwà àti àwọn Ọba Ilẹ̀ Yorùbá míràn tí wọ́n rọ̀ lóyè
- Mo ní ọ̀rẹ́kùnrin àmọ́ n kò le ṣe abiyamọ gẹ́gẹ́ bí Adelé - Moyinolouwa Falowo
- Láti 1978 tí Bàbá mi ti jẹ Oba Isinkan ni mo ti mọ̀ pé máà jẹ adelé- Margret Omonije
- Ṣé òótọ́ ni pé àwọn ọba kan ju ẹlẹgbẹ́ wọn l'Ekiti?
- Owa Idanre wà lórí ìtẹ́ nígbà tí wọn fìyà jẹ mí láàfin rẹ̀ - Adelé Ọba Alade Idanre
- Ọba tèmi ò ba lórí ohun gbogbo!-Taiwo Oyebola Agbona
- Àṣe ẹnu ọba lágbára ju ti pásítọ̀ lọ
BBC Yoruba lọ ba Kabiyesi naa ni alejo nilu rẹ lati mọ bi isu se ku ati bi ọbẹ se bẹ, ti ọmọde se n jọba lori awọn agbaagba to wa nilu Okelusẹ lẹba ilu Akure.
Iwadii wa si fi han lati ẹnu awọn agbaagba ilu naa pe wọn kii du ọba nilu naa, ọmọkunrin to ba dagba julọ ni oye si kan.
Ifa to ba si mu ni ọba naa yoo fi jẹ orukọ gẹgẹ bi akọbi ọkunrin, idile kansoso si lo n jẹ ọba nilu Okelusẹ.
Nigba ti BBC Yoruba beere pe ti Kabiyesi to wa lori itẹ ko ba bi ọmọkunrin bii arole nkọ, Awọn agbaagba ni awọn alalẹ yoo yi oyun inu Olori pada si ọkunrin, ko to bi ni.
Ẹ maa ba wa kalọ lati mọ kayeefi to n waye nilu Okeluse paapaa nidi eto fifi ọba jẹ.




