Ekiti: Ìtumọ̀ Pelúpelú nínú òyè ọba jíjẹ ní ìpínlẹ̀ Ekiti àti ìpele tí àwọn ọba pín sí

Oríṣun àwòrán, @iam_ademuyiwa
Itan oye awọn lọbalọba l'Ekiti ti a mọ si Pelupelu bẹrẹ lẹyin ti ogun Kiriji pari lọdun 1886.
Awọn ọba mẹrindinlogun lo si maa n wa ninu igbimọ Pelupelu ninu gbogbo ọba to wa l'Ekiti.
Awọn ọba Pelupelu ọhun ni Ajero ti Ijero, Alara ti Aramọkọ, Ewi ti Ado Ekiti, Ogoga ti Ikẹrẹ, Olomuo ti Omuo, Attah ti Ayede, Onitaji ti Itaji, Ọlọyẹ ti Ọyẹ, Arinjalẹ ti Isẹ, Ọlọgọtun ti Ọgọtun, Elemure ti Emure, Alaaye ti Ẹfọn, Ọwa Ooye ti Okemẹsi, Olojudo ti Ido Faboro, Ẹlẹkọle ti Ikọle ati Onisan ti Isan.
Awọn akọsilẹ kan sọ pe awọn oyinbo amunisin, ati awọn ijọba ologun ati oloṣelu to ti jẹ ni Ekiti ti gba awọn ọba miran wọle si igbimọ Pelupelu. Ti apapọ wọn si ti jẹ mejilelogun.
Ṣugbọn ṣa, lati bi ọdun 1999 ni ijọba oloṣelu to n jẹ ni Ekiti ti sọ ọrọ Pelupelu di ọrọ oṣelu.
Ti awọn ọba kan si n fẹsun kan pe wọn n gbe awọn ọba ga lai tẹle aṣa ati ilana ibilẹ.
Kii gan ni Pelu-pelu?
O jẹ akori ọrọ ti wọn n lo l'abẹle fun ipade awọn ọba. O tumọ si 'pipe awọn ọba si ipade'.
Asiko ijọba oyinbo amunisin ni o bẹrẹ. Awọn oyinbo alawọ funfun to ko orilẹ-ede Naijiria l'ẹru n wa ọna ti ilana iṣejọba wọn yoo fi fẹsẹmulẹ. Nitori naa, awọn ọba ni wọn lo.
Igba naa si ni igba akọkọ ti wọn ko gbogbo awọn ọba ni Naijiria papọ si oju'kan.

Oríṣun àwòrán, Ekiti state government
Awọn oyinbo naa pe awọn ọba diẹ ti wọn raaye kesi ni Ekiti, ọba mẹrindinlogun.
Ohun si ni ibẹrẹ nkan ti wọn n pe ni Pelupelu.
Awọn ọba kan binu pe wọn fi ọwọ rọ wọn sẹyin nitori pe wọn ko pe wọn si ipade naa.
Ifẹhonuhan si waye nigba naa.
Deji ti ilu Akurẹ, to ti wa ni ipinlẹ Ondo bayii, ati Owalobo ti Obo to ti wa ni ipinlẹ Kwara bayii naa wa lara awọn ọba to lọ fun ipade akọkọ.
Botilẹjẹ pe awọn itan kan sọ pe awọn oyinbo amunisin ti tu ilana Pelupelu kan l'ọdun 1958, bi oye awọn ọba Ekiti ṣe gbewọn to ni wọn pin si ipele mẹta.
Awọn to wa ni ipele A ni awọn ọba ti itan sọ pe wọn wa ninu igbimọ Pelupelu lati ibẹrẹ pẹpẹ, ati awọn miran ti ijọba ti fi kun wọn.














