Alaafin: Àwọn ọba Ekiti kò nílò alàgàta, bí wọ́n bá tilẹ̀ nílò rẹ̀, Ọọ̀ni nìkan ló láṣẹ bẹ́ẹ̀

Fayemi, Fatomilola ati Alaafin

Oríṣun àwòrán, @others

Agba oṣere tiata, Peter Fatomilọla ni ikọja aye gbaa ni igbesẹ Alaafin lati yọju si ohun to n lọ laarin awọn lọbalọba ni ipinlẹ Ekiti.

O ni Alaafin Adeyẹmi tasẹ agẹrẹ ni o. O ni Ọọni ile ifẹ nikan lo laṣẹ labẹ itan Yoruba lati da si ọrọ lọbalọba kaakiri nitori gẹgẹbi ọrọ rẹ, "Ọọni ni olori ọba lagbaye"

O ni awọn to lee ba gomina Fayẹmi wi bo ba taṣẹ agẹrẹ wa nipinlẹ Ekiti ti ko si si idi fun Alaafin lati maa da si ọrọ laarin wọn.

Fatomilọla ní Ọ̀ọ̀ni Ifẹ ní olórí aládé nílẹ̀ Yorùbá, òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti dá sí ọ̀rọ̀ ọba l'Ekiti

Ogbontagi olukọ ede ati Aṣa Yoruba, Peter Fatomilọla ti sọ pe, bi Alaafin ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi Kẹta, ṣe dasi ọrọ awọn lọba-lọba ipinlẹ Ekiti ko bojumu to.

Fatomilọla, tii se onimọ nipa asa ati ede Yoruba sọ pe, bi igba ti eeyan tasẹ agẹrẹ ni igbesẹ alaafin naa.

"Bi igba ti eniyan lọ sile onile ni. O dabi ki gomina ipinlẹ Oyo lọ si Ekiti, lọ maa da si ọrọ oṣelu wọn, yoo gba eebu ati abuku bọ ni, tori aja kii roro, ko ṣọ ojule meji."

"To ba jẹ pe Ọọni ile Ifẹ lo gbe iru igbesẹ yii, o dara, nitori pe, oun ni olori ade gbogbo ilẹ Yoruba. Oun nikan lo le dan iru rẹ wo. Igbesẹ ti Alaafin gbe yii, o fẹ tun fi da ogun silẹ laarin awọn lọba-lọba Ekiti ni. Ọdun mẹrindinlogun si ni Oyo fi ba Ekiti jagun."

Peter Fatomilọla ati Alafin ilu Ọyọ

Oríṣun àwòrán, others

Nigba ti a beere taa ba wo ọjọ ori, ṣe alaafin ko lẹtọ lati dasi ọrọ naa, Fatomilọla sọ pe, agba ko kan ọrọ yii, kii si se ti ọjọ ori pẹlu. Ti eniyan ba dagba, o yẹ ko mọ nkan to tọ lati se.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ki Fayemi paapa ma danwo lati rọ awọn ọba loye tori awọn ọba naa lẹtọ lati yari fun gomina to ba gbe ọba ti ko tọna wa fun wọn, bẹẹ si ni kii ṣe gbogbo ọba Ekiti lo wọ igbimọ Pelupelu .

"Awọn ọba to ba tọ si bi i Ẹlẹkọle ti Ikọle, Ajero ti Ijero, Alara ti Ilara, Ewi ti Ado ati awọn miran nikan lo lẹtọ si igbimọ naa lati lọ si ipade. Wọn si tun lẹtọọ lati ba Fayemi wi, ki wọn si tun gba a nimọran to ba tasẹ agẹrẹ."

Alafin tilu Oyo ati Kayode Fayemi

"Oṣelu lo ti ba nkan jẹ, oun naa lo si mu ki iru Alaafin Ọyọ maa dasi nkan to n lọ l'Ekiti. Kii ṣe pe gbogbo Ekiti ko ni baba nile, wọn wa n wa baba lọ sode."

A ti sọ fun yin saaju pe ọsẹ to kọja ni Alaafin kọ lẹta kan si Gomina Fayẹmi, lẹyin ti Fayẹmi kede pe, oun yoo rọ awọn ọba kan l'oye l'Ekiti nitori pe wọn n fapajanu lori ẹni to fi jẹ alaga awọn ọba ipinlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Coffee Painter: Adebukola ní kò sí ìrànwọ́ lẹ́yìn ẹ̀kọ́ girama lòun ṣe ń ya àwòrán

Isẹlẹ yii si lo ti n fa awuye-wuye laarin awọn ọmọ ilẹ Yoruba. Ṣugbọn lọjọ aiku ni Fayẹmi lọ si ọdọ Alaafin lati ni ijiroro pẹlu rẹ, eyi to ṣeeṣe ko jẹ lori ọrọ lẹta naa.