Oshiomole: Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn wọ́gilé ìyọnípò Oshiomole gẹ́gẹ́ bíi alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC

Oríṣun àwòrán, @marketdigestng
Ile ẹjọ kotẹmilọrunilu Abuja ti ni Adams Oshiomhole si ni alaga gbogbogbop fun ẹgbẹ oṣelu APC.
Igbimọ ẹlẹni mẹta to n gbọ ẹjọ naa, ti adajọ Abubaka Datti Yahaya ko sọdi wọgile ẹjọ ti ile ẹjọ giga ilu Abuja da ṣaaju, leyi to yọ Oshiomole nipo gẹgẹ alaga ẹgbẹ ọhun.
Ṣaaju ni oshiomole ti rọ ile ẹjọ kotẹmilọrun naa lati gbe idajọ iyọnipo rẹ naa ti ṣdegbẹ kan.
- Ilé ẹjọ́ ti sún ìgbẹ́jọ́ si Ọjọ́-Bo̩
- Wọ́n gbé òkú ọgá iléẹ̀kọ́ àti òṣìṣẹ́ méjì míì tó kú nínú ìbúgbàmù lọ sílé ìgbókùsí ológun ojú omi l‘Eko
- Ajá kìí rorò kó ṣọ́ ojú'lé méjì, kò tọ́ ọ́ sí Alaafin láti dásí ọ̀rọ̀ ọba l‘Ekiti - Peter Fatomilọla
- Ìjọba Somalia gbẹ́sẹ̀ lé ìrìn àjò òkè òkun lẹ́yìn tí Coronavirus báwọn lálejò
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, adajọ naa kilọ fun awọn ti ọrọ ọhun lati ma gbe igbeṣẹ ti yoo tako idajọ to gbe kalẹ.
Lẹyin naa lo rọ awọn ẹgbẹ oṣelu lati maa yanju awọ to ba wa laarin wọn gẹgẹ bi ọmọ iya dipo ki wọn maa yọ ile ẹjọ lẹnu.
Tinubu ni àìsàn tó rọ̀ mọ́ ìdíje òṣèlú ní 2023 ló ń yọ ọ̀tá Oshiomole lẹ́nu

Oríṣun àwòrán, Others
Eekan ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Tinubu ti sọrọ lori awuyewuye lati yọ alaga apapọ ẹgbẹ naa, Adams Oshiomole nipo.
Ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Aiku, Tinubu ni arun a ti dije fun ipo oṣelu lọdun 2023, lo n ṣe awọn ọmọ ẹgbẹ APC to fẹ yọ Oshiomole nipo alaga.
Tinubu ni igbesẹ yii n ṣakoba fun ẹgbẹ oṣelu APC, bakan naa lo n ṣe ipalara fun iṣejọba Aarẹ Muhammadu Buhari.
- Ọ̀pá afẹ́fẹ́ gáásì NNPC tó dálu ló fa ìbúgbàmù l‘Eko, ilé 50 àti ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò
- Ìpele tuntun ló kàn nínú ìrìnàjò ayé mi, ń kò pe ẹjọ́ lóri ìrọ̀lóyé - Sanusi
- Kò sẹ́ni tó fẹ́ pa Buhari o, ọkùnrin tó pakuru mọ́ ààrẹ kàn fẹ́ bọ̀ọ́ lọ́wọ́ ni - Femi Adesina
- Ọmọ ti lọ kí baba, Fayemi bẹ Aláàfin wo l‘Ọyọ, wọ́n jírórò lórí lẹ́tà
- Ẹ́ gbaradì, to bá lo jẹnẹrátọ̀ àbí tà á, ò ń fi ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá ṣeré - Sẹ́nétọ̀ ń dábàá
- Láì lo Kakulétọ̀, mo ní ọpọlọ ìṣirò, tábìlì ìṣirò wà lórí mi - Human Calculator
''Aarun a ti dupo lọdun 2023 n ṣe ọpọ lagbo oṣelu atawọn alatilẹyin wọn laarin awọn akọroyin'' Tinubu lo woye bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Asiwaju Bola Tinubu
Tinubu ni ohun to n ṣe awọn to fẹ yọ Oshiomole nipo ni pe, wọn fẹ ki gbogbo ọrọ lori ibo ọdun 2023 ko yanju tan ninu ẹgbẹ lọdun 2020 yii.
Asiwaju Tinubu fikun ọrọ rẹ pe, Oshiomole ti ṣisẹ takun takun fun ẹgbẹ oṣelu APC papaa julọ, lasiko ibo gbogbo-gbo to kọja.
O ni kii wa ṣe asiko yii lo yẹ ki awọn eeyan kan maa fẹnu tẹnbẹlu rẹ ninu ẹgbẹ.

Oríṣun àwòrán, Others
Tinubu sọ pe iwa aimore ni lati maa mọ riri ipa ti Oshiomole ko ninu ẹgbẹ oṣelu APC papaajulọ lasiko ibo to ja.
Tinubu ni ''ero awọn ti wọn n tako Oshiomole ni pe o maa dina mọ wọn lati dije fun ipo kan tabi omiiran ninu idibo ọdun 2023.''
Tinubu ṣalaye pe akoko ko tii to fun oṣelu ọdun 2023, o rọ awọn ọmọ ẹgbẹ APC lati gbaruku ti Aarẹ Buhari ko le ṣe aṣeyọri ninu ijọba rẹ.













