Lagos Explosion: Sanwo-Olu rọ olùgbé Eko láti mú ààbò ẹ̀mí ní pàtàkì

Oríṣun àwòrán, Others
Ajọ to n ri si isẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, Lasema ti kede pe eeyan mẹtadinlogun, to fi mọ ọga agba ileẹkọ kan lo ti jalaisi ninu isẹlẹ naa, nigba ti awọn mẹẹdọgbọn miran n gba itọju nile iwosan, eyi ti iroyin rẹ gbalẹ kan ni aarọ ọjọ Aiku.
Bakan naa, ko din ni aadọta ilegbe, ile ijọsin ati ileẹkọ to bajẹ kọja aala lasiko ti ọrinrin ibugbamu naa waye lagbegbe Abule Ado yii, ti ọwọja rẹ si tan de awọn agbegbe miran pẹlu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- 'Ọjọ́ lọjọ́ tí mo mọ̀ pé wọ́n bí mi láà ní ojú ara obìnrin àti ilé ọmọ'
- Ọmọ ti lọ kí baba, Fayemi bẹ Aláàfin wo l‘Ọyọ, wọ́n jírórò lórí lẹ́tà
- Coronavirus dá rúkè-rúdò sílẹ̀ ní pápákọ̀ òfurufú l‘Amẹrika, ọ̀pọ̀ ń forí gbárí
- Òṣèré tíátà Yorùbá mẹ́ta gbàmì ẹ̀yẹ pé wọ́n pegedé
- Òkú ṣùn nínú ìbúgbàmú tó wáyé l‘Eko
- Àwọn kókó ohun tó wà nínú lẹ́tà tí Aláàfin kọ sí Fayemi rèé
Koda, ọpọ mọto ti wọn gbe kalẹ si adugbo naa lo bajẹ tan pata, ti ọpọ eeyan si di alainile lori.
Sista ijọ katoliki, tii se ọga agba ileẹkọ girama Bethlehem Girls college, Henritta Alokha, to wa ladugbo naa, lo jalaisi lasiko to n gbiyanju ati doola ẹmi awọn ọmọ ileẹkọ naa.

Oríṣun àwòrán, Others
Wayi o, gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti se abẹwo si ibudo ti ọpa gaasi naa ti bu gbamu, to si ni ki wọn setọju awọn eeyan to faragba ni kiakia.
Bakan naa lo gba awọn eeyan Eko nimọran lati rin jinna sibi ti isẹlẹ naa ti waye tori ewu, ki wọn si mase mi eefin isẹlẹ naa simu.Arigbamu ti wa bayii nipa iye eeyan to ba isẹlẹ ọpa gaasi to lagbegbe Abule Ado nijọba ibilẹ Amuwo ọdọfin nipinlẹ Eko lọ.
Ọ̀pá afẹ́fẹ́ gáásì NNPC tó dálu ló fa ìbúgbàmù l'Eko, ilé 50 àti ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò
Ijamba ina to sadede bẹ silẹ lọsan ọjọ Aiku lagbegbe Ado Soba, Abule Ado nijọba ibilẹ Amuwo Ọdọfin ti mu ẹmi lọ, to si tun ba ile to le ni aadọta jẹ kanlẹ.

Ẹ wó iye àsìkò ti yóò gba ọkọ panapana kio to de ibi ti ina ti n jó
Akọroyin BBC Yoruba to wa nibi isẹlẹ naa jabọ pe deede aago mẹwa aarọ, lasiko ti awọn eeyan kan ti wa nile ijọsin ni ọpa to n pin afẹfẹ gaasi sadede bu gbamu, ti ina si sọ.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Gẹgẹ bi awọn eeyan to wa ladugbo naa, ti isẹlẹ ọhun si soju wọn ti wi, se ni oorun gaasi kọkọ gba agbegbe naa kan, ti ara si ti n fu awọn pe ewu nbọ, awọn si n wa ọna abayọ lọwọ, ni ina sọ.

"Oorun gaasi lo kọkọ ru bo wa ninu ile, ti mo si n sọ fawọn ọmọ pe ki wọn jẹ ka jade sita lati wọna abayọ, ibi ta ti n gbero lati jade, ni mo gbọ gbola lojiji, ti ohun gbogbo si pakasọ."
Bakan naa lo fikun pe ile ti ijamba naa bajẹ to aadọta niye, nigba ti ọpọ eeyan ti wọn ko tii mọ iye wọn, ti jalaisi ninu ijamba ina naa.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, alaga ijọba ibilẹ Amuwo Ọdọfin, Onimọ-ẹrọ Dotun Valentine salaye pe, awọn ara adugbo naa ni ọpa gaasi naa lo bẹ nitori ẹrọ kan to bajẹ, eyi to mu ki afẹfẹ gaasi maa tu jade, to si sadede gba ina.

"Kii se pe awọn eeyan kan lo ba ẹrọ naa jẹ, nitori awọn sọja wa nibudo naa, ti wọn n sọ awọn ọpa afẹfẹ gaasi naa, irinsẹ rẹ kan lo bajẹ, amọ o ti ya ju fun mi lati kede iye ẹmi to ba isẹlẹ naa lọ."
"A ti kesi awọn osisẹ ajọ elepo rọbi NNPC lati wa ti ẹrọ to n pin afẹfẹ gaasi wa sidi ọpa naa, ki ina ọhun lee tete jo tan, tawọn osisẹ panapana, Lasema, ọga ọlọpa ati olori ileesẹ ologun lẹkun yii si ti de sibi isẹlẹ naa."

Valentine tun salaye pe ọpọ dukia lo ti sofo nitori isẹlẹ ina ọhun, ti ileẹkọ, ilegba ati awọn ibudo ijọsin loniran nran si dawo lulẹ tabi padanu orule ile wọn.
Eyi to tiẹ se ni laanu julọ ni ti ileẹkọ Bethlehem Girls College, to wa ni gbagede ipatẹ ọja to wa ladugbo naa, tawọn akẹkọ ti n gba idanilẹkọ lọwọ, nigba ti ibugbamu naa waye, to si dawo.

Ẹgbẹ alagbelebu pupa, Red Cross, toun naa ko gbẹyin nibi isẹlẹ ina yii, salaye pe, o ti to eeyan mẹẹdogun ti awọn ti doola ẹmi wọn lọwọ ijamba nileẹks naa, ti wọn si ti gbe wọn lọ sile iwosan.
Lọwọ-lọwọ bayii, ọpọ olugbe adugbo naa lo ti n ko ẹru wọn kuro ni adugbo naa, ta si tun kofiri ọkọ ofurufu to n paraaro adugbo ọhun, aibaamọ, isẹlẹ naa le tun fọn ina soju.

Ajọ Lasema ti wa kede pe ohun ti bẹrẹ isẹ idoola ẹmi nibi isẹlẹ naa, paapa lawọn inu ile to fori sọta ọrinrin ibugbamu ọhun.
Òkú ṣùn nínú ìbúgbàmú tó wáyé l'Eko

Saaju la ti sọ fun yin pe iroyin to n ja rainrain to n tẹ wa lọwọ bayii ti kede pe, ọpa epo miran tun ti bẹ lagbegbe Festac, ti ọrinrin rẹ si gbalẹ yika Eko.
Ariwo ti ibugbamu naa mu lọwọ lo gbalẹ kan, ti awọn eeyan si n sa asala fun ẹmi wọn, a ko si ti lee sọ iye ẹmi to ti ba isẹlẹ naa rin.
Nigba to n fidi isẹlẹ naa mulẹ, oludari ajọ to n ri si isẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, Lasema, Oke Ọsanyintolu sọ fun BBC Yoruba pe awọn eeyan to n fọ ọpa epo pẹtiroolu lo se okunfa isẹlẹ naa.
- N kò ní ìjà pẹ̀lú Fayemi, ipò mi bíi aláàbò àṣà Yorùbá ní mó ṣe kọ lẹ́tà sí gómìnà Ekiti - Aláàfin
- Wò ó ọ̀nà láti mú ara rẹ dé ibi tó ga jùlọ nínú ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìlànà Tantra
- Ọ̀sẹ̀ yìí laá gbàwọn ẹ̀sọ́ Amotekun sísẹ́, ìparí oṣù kẹta ni iṣẹ́ yóò bẹ̀rẹ̀ - Akeredolu
- Ìpele tuntun ló kàn nínú ìrìnàjò ayé mi, ń kò pe ẹjọ́ lóri ìrọ̀lóyé - Sanusi
Lasema ni oun ti de ibi isẹlẹ naa, ti ọwọ awọn osisẹ ajọ naa si ti n ka ina yii.
Amọ Ọsanyintolu ko tii lee sọ boya ẹmi kankan ba isẹlẹ naa rin abi iye dukia to ti sofo.

"A ti de sibi isẹlẹ naa, a n sisẹ lọ lati pa ina yii, ọwọ wa si ti n kaa, amọ a ko tii mọ bii ọsẹ to se ti nipa si. A gbọ wipe awọn eeyan to n fọ ọpa epo lo tun se okunfa akọtun ibugbamu ọpa epo yii. Bo ba se n lọ, a mu to ẹyin akọroyin leti."
Amọ ẹnikan ti isẹlẹ naa soju rẹ, amọ to kọ lati foju han lori aworan BBC Yoruba ni, iye awọn eeyan to ku ninu ijamba yii ko lonka, ti wọn ti ha sinu ina ọhun.

A gbọ pe ọpọ adugbo to sun mọ ibi ti ibugbamu naa ti waye, bii Akọta, Festac ati Abule Ado ni ariwo naa rinlẹ de, ti ilẹ mi titi eyi to se ẹru ba ọpọ eeyan.
Lọwọ-lọwọ bayii, wọn ti n gbe awọn eeyan to sese ninu ijamba ibugbamu naa lọ sile iwosan, ninu eyi ti a ti ri sisita ijọ Katoliki kan ati akẹkọ mta.
Ọ̀pá epo rọ̀bí tún bẹ́ pẹ̀lú ìbúgbàmù ńlá l'Eko, àwọn òrùlé ilé ṣí lọ rẹrẹ
Oju opo Twitter ti kun fun ariwo awọn eeyan to gburo ibugbamu naa eyi to se ọsẹ pus fun ọpọ ile.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
A gbọ pe awọn dukia kan ti ba isẹlẹ naa rin, tori ibugbamu naa mu ki awọn orule ile kan si, to fi mọ ibudo ijọsin, lasiko ti awọn eeyan n jọsin lọwọ, ti awọn ile kan si ti dawo pẹlu.

Koda, eefin n ru jade lati agbegbe ti ibugbamu naa ti waye, ti oju ọrun si dudu fun eefin.
Akọroyin BBC to sare de ibi isẹlẹ naa ni ileesẹ panapana ijọba ti wa de sibi isẹ́lẹ́ naa, ti wọn si ti n pa ina naa.
A tiẹ tun gbọ pe ileewe kan ti wo lulẹ nitori ariwo ati ilẹ to mi lasiko ti ibugbamu ọpa epo naa waye.

Bi isẹlẹ yii ba si se n tẹsiwaju, nileesẹ BBC Yoruba yoo maa mu wa fun yin.
















