Amotekun: Akeredolu ní àwọn iléeṣẹ́ aláàbò ni yóò ṣèdánilẹ́kọ̀ọ́ fáwọn ẹ̀sọ́ náà

Alaga awọn gomina lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, Rotimi Akeredolu ti kede pe ọsẹ tuntun taa bẹrẹ yii ni wọn yoo gba awọn ẹsọ alaabo fun ikọ Amotekun sisẹ.
Bakan naa lo fikun pe ki osu kẹta taa wa yii to buse, iks alaabo naa yoo gberasọ, ti yoo si bẹrẹ isẹ.
- Buhari o, tètè ṣètò àtúntò Nàíjíríà ká le è dènà ogun abẹ́lé lẹ́ẹ̀kejì - Obasanjo figbe bọnu
- Ó ṣeéṣe kó má sí ẹ̀ṣọ́ aláàbò Amotekun l‘Eko - Ìjọba Eko
- Ẹ̀yin ẹkùn yókù, ẹ fi ikọ̀ àbò "Amotekun ṣe àwòkọ́ṣe rere - APC
- Ìpínlẹ̀ Oyo, Ogun, Ondo buwọ́lu àbádòfin Àmọ̀tẹ́kùn
- Ẹgbẹ́ kan fún Tinubu ní wákàtí mẹ́rìnlélógún láti sọ èrò rẹ lórí Amọtẹkun
Gomina Akeredolu, ẹni ti olugbani nimọran rẹ feto aabo, Alhaji Jimoh Dojumo gba ẹnu rẹ sọrọ, tun fikun pe gbogbo eto lo ti doju ọgbagade bayii lati ri pe ikọ Amotekun bẹrẹ, eyi ti yoo gbogun ti aifararọ feto aabo nilẹ Yoruba.

"Ọjọ mọkanlelogun ni awọn ẹsọ Amotekun yoo fi gba idanilẹkọ amọ loore koore la maa se idanilẹkọ fun wọn lori eto aabo. Awọn ileesẹ alaabo ni yoo maa se idanilẹkọ fun awọn ẹsọ ta ba gba, igbanisisẹ ati idanilẹkọ yoo si maa lọ ni rọgba-rọgba ni."
Bakan naa ni Dojumo fikun pe awọn n sọrase lati mase se asise lori isọwọ sisẹ ikọ alaabo naa pẹlu afikun pe, o seese ki wọn ma pese asọ isẹ pataki fun ikọ naa bayii, tori ipinnu kankan ko tii waye lori eyi.









