Coronavirus: Afurasí aláàrùn coronavirus ní ìpínlẹ̀ Enugu ti wà ní ìyàsọ́tọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n risi idena ajakalẹ aarun ni Naijiria, NCDC, ti sọ pe alaisan kan wa ni ipinlẹ Enugu, ni apa ila oorun orilẹ-ede Naijiria ti wọn fura si pe o ni aarun coronavirus.
Gẹgẹ bi ikede kan ti ajọ NCDC fi si ori ayelujara Twitter rẹ lọjọ Aiku, wọn ti fi alaisan naa si iyasọtọ, wọn si ti ṣe ayẹwo ara rẹ, esi yoo si jade lọla, ọjọ Aje.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ṣugbọn, ikede wọn naa ko sọ boya ọkunrin tabi obinrin ni alaisan naa.
Ọjọ Ẹti to kọja ni Minisita fun eto ilera ni Naijiria, Ọjọgbọn Osagie Ehanire kede pe ọsẹ yii ni wọn yoo yọnda ọmọ orilẹ-ede Italy to ko aarun naa wọn Naijiria kuro nileewosan.
Bakan naa lo sọ pe alaisan keji to ni aarun naa ni ipinlẹ Ogun ko ni aarun naa mọ lẹyin ayẹwo ti wọn pada ṣe fun. Oun naa yoo ma lọ si ile rẹ.
Oṣu Keji ni Naijiria kọkọ ni akọsilẹ aarun coronavirus.
Gẹgẹ bi akọsilẹ onka agbaye kan, Worldometer, eniyan ti ko din ni ẹgbẹrun maarun o le ẹgbẹrin ati marundinlaadọta eniyan ni aarun naa ti ṣekupa.
Coronavirus dá rúkè-rúdò sílẹ̀ ní pápákọ̀ òfurufú l'Amẹrika, ọ̀pọ̀ ń forí gbárí
Awọn papakọ ofurufu ilẹ Amẹrika ti wa ni idarudapọ bayii nitori eto ayẹwo ilera lori arun Coronavirus to bẹrẹ, fun awọn eniyan to n de lati ilẹ Yuroopu.
N ṣe ni awọn eniyan to bẹẹrẹ bẹ fun ọpọlọpọ wakati lati sẹ ayẹwo ara wọn, ki wọn o to kọja lọdọ awọn ẹsọ aṣọbode.
Ṣaaju asiko yii, Igbakeji Aarẹ, Mike Pence sọ pe, ofin ti wọn fi de awọn arinrinajo lati awọn orilẹ-ede to wa ni ilẹ Yuroopu yoo kan ilẹ United Kingdom ati Ireland lọjọ Iṣẹgun.

Oríṣun àwòrán, Ruth Procopi
Awọn alaṣẹ Amerika ti fofin de awọn arinrinajo lati awọn orilẹ-ede mẹrindinlọgbọn to wa ni ilẹ Yuroopu, ṣugbọn ti ki ṣọmọ ilẹ Amerika.
Aaye wa fun awọn ọmọ ilẹ Amerika lati wọle, ṣugbọn wọn yoo ṣayẹwo oju wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Òṣèré tíátà Yorùbá mẹ́ta gbàmì ẹ̀yẹ pé wọ́n pegedé
- Òkú ṣùn nínú ìbúgbàmú tó wáyé l‘Eko
- Àwọn kókó ohun tó wà nínú lẹ́tà tí Aláàfin kọ sí Fayemi rèé
- N kò ní ìjà pẹ̀lú Fayemi, ipò mi bíi aláàbò àṣà Yorùbá ní mó ṣe kọ lẹ́tà sí gómìnà Ekiti - Aláàfin
- Wò ó ọ̀nà láti mú ara rẹ dé ibi tó ga jùlọ nínú ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìlànà Tantra
- Ọ̀sẹ̀ yìí laá gbàwọn ẹ̀sọ́ Amotekun sísẹ́, ìparí oṣù kẹta ni iṣẹ́ yóò bẹ̀rẹ̀ - Akeredolu
- Ìpele tuntun ló kàn nínú ìrìnàjò ayé mi, ń kò pe ẹjọ́ lóri ìrọ̀lóyé - Sanusi
Eniyan to le ni ẹgbẹrun meji ati ẹẹdẹgbẹrin lo ti ni aarun Coronavirus nilẹ America, ti awọn mẹrinlelaadọta si ti ku.
Awọn akọroyin n sọ pe idarudapọ lo gbalẹ bayii ni America, pẹlu ibẹru pe o ṣeesẹ ki ibusun alaisan o ma to mọ nileewosan, ati itọju awọn ọmọde ti wọn ti le ọpọlọpọ miliọnu wọn wa sile.












