AMVCA7 2020: Funke Akindele, Toyin Abraham áti Yewande Famakin gba àmí ẹ̀yẹ

Ayẹyẹ fifun awọn osere tiata lami ẹyẹ lati fi se koriya fun isẹ ti wọn n se lati ọdun kan sẹyin, eyiti African Magic se agbatẹru rẹ, lo si n ja rainrain nilẹ bayii.
Ayẹyẹ naa ti wọn pe ni AMVCA7 lo waye lọjọ Abamẹta nilu Eko, ti ọpọ awọn ilumọọka osere tiata nilẹ Adulawọ ati loke okun peju si.
Se ni awọn ilumọọka osere naa ko sinu asọ to jẹ oju ni gbese, olowo iyebiye, ti tọkunrin-tobinrin wọn si dun wo loju.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Òkú ṣùn nínú ìbúgbàmú tó wáyé l‘Eko
- Ọọ̀ni Ifẹ̀ la mọ̀ bíi olórí ọba Yorùbá, kí Aláàfin ya ṣo ewé gbéjẹ́ mọ́wọ́ - Ọ́ba Ekiti fárígá
- Àwọn kókó ohun tó wà nínú lẹ́tà tí Aláàfin kọ sí Fayemi rèé
- N kò ní ìjà pẹ̀lú Fayemi, ipò mi bíi aláàbò àṣà Yorùbá ní mó ṣe kọ lẹ́tà sí gómìnà Ekiti - Aláàfin
- Wò ó ọ̀nà láti mú ara rẹ dé ibi tó ga jùlọ nínú ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ìlànà Tantra
- Ọ̀sẹ̀ yìí laá gbàwọn ẹ̀sọ́ Amotekun sísẹ́, ìparí oṣù kẹta ni iṣẹ́ yóò bẹ̀rẹ̀ - Akeredolu
- Ìpele tuntun ló kàn nínú ìrìnàjò ayé mi, ń kò pe ẹjọ́ lóri ìrọ̀lóyé - Sanusi
Nibi ayẹyẹ naa si lawọn ọpọ osere tiata lede oyinbo ati lawọn oniruuru ede miran nilẹ Afirika ti gba ami ẹyẹ, ti awọn osere tiata lede Yoruba naa ko si gbẹyin nibẹ.
Lara awọn osere tiata lede Yoruba to gba ami ẹyẹ ni Yewande Famakin, Toyin Abraham ati Funkẹ Akindele, alaye si ree nipa ami ẹyẹ ti wọn gba ati idi ti wọn se yẹ lati gba ami ẹyẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Realmercyaigbe
Fun iyalẹnu ọpọ eeyan, obinrin ni kikida awọn osere tiata mẹta to gba ami ẹyẹ AMVCA7 naa lọdun yii ni ẹka ede Yoruba, ti ko si si ọkunrin ni aarin wọn.
Toyin Abraham:

Oríṣun àwòrán, Toyin_abraham
Mama Ire, gẹgẹ bi ọpọ eeyan se maa n fi orukọ ọmọ pe Toyin Abraham, jẹ ilumọọka osere tiata lde oyinbo ati Yoruba.
Bi o tilẹ jẹ pe ami ẹyẹ to gba jẹ ti ẹka fiimu oloyinbo, sibẹ eyi kii se igba akọkọ ti yoo gba ami ẹyẹ naa.
Toyin, ti ọkọ rẹ, Kola Ajewọle duro ti lẹgbẹ timọtimọ lati gba ami ẹyẹ ọhun, ni wọn fun ni ami ẹyẹ osere-binrin to dangajia julọ lọdun 2019 .
Fiimu Elevator Baby si lo mu ko gba ami ẹyẹ naa.
Yewande Famakin:

Oríṣun àwòrán, Yewande
Ilumọọka olootu fiimu lobinrin naa lo gba ami ẹyẹ pe oun lo gbe fiimu ede ibilẹ to pegede julọ sita ni ẹka awọn fiimu ti wọn se lede Yoruba fun ọdun 2019 ( Best Indigenous Language Movie/TV Series Yoruba.
Orukọ fiimu to si gbe jade naa ni Alubarika, eyi to mu ko gba ami ẹyẹ pe o pegede julọ eyi ti o jáde ni ọdun 2019.
Yewand ti ṣe fiimu bi maarun láti igba to ti bẹ̀rẹ̀ ere tiata.
Funke Akindele:

Oríṣun àwòrán, funkejenifaakindele
Jenifa baby, gẹgẹ bi ọpọ eeyan se maa n pe Funkẹ Akindele, naa ko gbẹyin ninu awọn oloriire to gba ami ẹyẹ nibi ayẹyẹ ifamiẹyẹ danilọla ti AMVCA7 naa.
Funke, toun naa n kopa ninu sinima oloyinbo ati Yoruba si ni wọn gbe ami ẹyẹ oserebinrin to danagajia julọ, ninu ere apanilẹrin fun.
Fiimu Moms at war si lo mu ki mama ibeji naa, moke laarin awọn akẹẹgbẹ rẹ.
Oun ati ọkọ rẹ, JJC Bello si ni wọn jọ lọ sibi ayẹyẹ awuni lori naa.
BBC Yoruba wa n bawọn oloriire ọhun dawọ idunnu, ta si n gbadura pe wọn yoo ri ẹmi loo.
AMVCA7Award: Yewande Famakin lo gba àmì ẹ̀yẹ sinima èdè ibílẹ̀
MVCA7 Award: Ronke Odusanya, Oyebade Adebimpe, Funke Akindele, Yewande Famakin àti Toyin Abrham tani ami ẹyẹ yoo já mọ lọ́wọ́?

Ayẹyẹ àmì ẹ̀yẹ AMVCA elekeeje irú rẹ ni ti ọdun 2020 yìí, ọ̀pọ̀ àwọn òṣèré Nollywood lo ti péjú sibẹ̀, lára wọ́n ni àwọn adẹ́rin pa òṣónú, àwọn olorin àti awọn oni tiata, olóṣèlu gan kò gbẹ́yin níbẹ̀.
Wọ́n ni oríṣiriṣi sbẹ láàri lọ́jọ́ ikú eerin, oríṣirisi àsọ lo n pe aṣọ ránṣẹ.
Awọn ọmọ ilé igbimọ asofin náà yọju sibi ti ọ̀rẹ yiì, Dino Melaye, Enyinaaya Abaribe, Ike Ekweremadu, awọn adẹrinpòsónú bi Basket Mouth, Funny Bone.
Nínú ayéyé tó n lọ lọ́wọ́ orísi ipele àmi ẹyẹ ni yóò wáye níbẹ̀.
Amin ẹyẹ mẹrindinlọ́gbọ̀n fún ènìyànn mẹrindinlọgbọ̀n
Amin ẹyẹ AMVCA ti ọdun yìí yóò ṣe àgbéjáde orísi ẹbun mẹrindinlọ́gbọ̀n
Méje nínú àwọ̀n ipele yìí ni wọ́n ti gbé sita fún ìdìbò

Best Supporting Actress
Best Supporting Actor
Best short film or online video
Best actor in a comedy
Best actress in a comedy
Best actor in a drama
Best actress in a drama
Best Indeginous Language Movies/TV Series- Yoruba
Ní ti àwọn òṣèré Nollywood yoruba ti wọ́n yàn fún àmì ẹ̀yẹ náà ni
Wumi Olabintan - Intent
Oyebade Adebimpe - Adebimpe Omo Oba
Yewande Famakin- Alukbarika
Ronke Odusanya- Ajoji Godogbo
Àwọn to kù ni
Funke Akindele

Sola Sobowale

Toyin Abraham












