Coronavirus: Èèyàn kan péré ló ní àrùn aṣekúpani náà ní Nàíjíríà báyìí

Oríṣun àwòrán, Others
Ijọba orilẹede Naijiria ti fi lede pe, ẹnikeji to ni Coronavirus lorilẹede Naijiria ti ri iwosan gba.
Minisita fun eto Iwosan, Osagie Ehanire lo fi eyi lede lasiko to n ba awọn eniyan sọrọ lori awọn ohun ti ijọba n ṣe lati koju arun Coronavirus ni Niajiria.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Aṣíwájú ni Nàíjíríà nínú ìdènà Coronavirus, ohun márùn-ún rèé tí àgbáyé ń kọ́ lára wa
- Ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá, DSS, ẹ fún Sanusi lómìnira àti rìn fanda padà - Iléẹjọ́ pàṣẹ
- Ọkùnrin tó bẹ́ sì òdò ọ̀sà pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀, lòun náà fi fẹ́ kú - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- Kò sẹ́ni tó fẹ́ pa Buhari o, ọkùnrin tó pakuru mọ́ ààrẹ kàn fẹ́ bọ̀ọ́ lọ́wọ́ ni - Femi Adesina
- Yorùbá rẹwà, kọ́ nípa àwọn ọ̀rọ̀ tí ìró ẹnu wọn jọra àmọ́ tí ìtumọ̀ wọn yàtọ̀
Pẹlu ikede yii, ẹyọ eniyan kan pere lo ni arun Coronavirus ni Naijiria, to n gbe iwosan ni ile iwosan ajakalẹ arun ni agbeegbe Yaba ni ipinlẹ Eko.
Bakan naa ni wọn fikun pe, gbogbo awọn eniyan ti wọn fi si ipamọ lẹyin ti wọn ni ibaṣepọ pẹlu arakunrin ara ilẹ Italy ohun, ni ara wọn da sakasaka, ti awọn yoo si fi silẹ lati ma a lọ ile wọn lẹyin ọsẹ meji.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọjọ́ Kẹsàn àn, Osu Kẹta ní mínísítà fún ètò ìwòsàn lórilẹ̀èdè Naijiria, Osagie Ehanire kéde ẹnikejì tó ní Coronavirus naa.
Ẹgbẹgbẹrun eniyan lo ti sọ ẹmi wọn nu nitori arun Coronavirus to bẹ silẹ lorilẹede China, lati Osu Kejila, ọdun 2019.
Ẹ má páyà lórí àìsí irinṣẹ́ ìṣègùn nílé ìwòsàn torí Covid19, ìmọ́tótó ara yín ló jà jù - NMA

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ apapọ fun ẹgbẹ awọn onisegun oyinbo nilẹ wa, Dokita Adedayọ Faduyile ti salaye pe irọ to jinna sootọ ni pe awọn eeyan ti n ya wa sawọn ile iwosan abẹle, lati wa gba iwosan.
Faduyile salaye ọrọ naa lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ pẹlu afikun pe oun ko ti mọ ibi ti awọn ileesẹ iroyin kan ti n se akojọpọ akọsilẹ wọn, to si ni akoko to ti koowa yẹ ko joko si adugbo rẹ lati dena kiko arun Coronavirus.
"O yẹ ka ro lootọ pe awọn eeyan to maa n lọ silẹ okeere lọ gba itọju maa fẹ lati joko sile bayii nitori awọn orilẹede ti wọn ti maa n lọ gba itọju lo ti lugbadi Coronavirus."
"Ilẹ Yuroopu ati India to jẹ ibudo ti awọn ọmọ Naijiria ti maa n lọ gba itọju julọ ni Coronavirus ti n ba finra, o si yẹ ki ẹni to ba gbọn tete joko sile."

Oríṣun àwòrán, Others
Nigba to n dahun ibeere lori boya ilọsiwaju ti wa fun ipese awọn ohun eelo eto ilera igbalode lawọn ile iwosan wa gbogbo ni Naijiria, Faduyile ni ipese awọn ohun eelo ilera kọ lo ja ju bikose ka tena itankalẹ arun naa, ko ma wọ Naijiria, ka si seto idanilẹkọ fawọn araalu.
"Ijọba wa ti se gudugudu meje ati ya ya mẹfa, lati dena itankalẹ arun Coronavirus, o si yẹ ka gbe osuba nla fun awọn adari wa lori bi wọn se tete kofiri arun naa, ko to bẹrẹ si ni se ọsẹ fun wa, ti wọn si tun tọpasẹ awọn eeyan to se alabapade ẹni to ni arun naa.
Ẹ má bọwọ́ kí ara yín mọ́, ìkúùkù ni kẹ fi lu àyà torí Coronavirus kọjá bẹ́ẹ̀ - Aregbesola

Oríṣun àwòrán, Bayo Omoboriowo
Minisita fọrọ abẹle lorilẹede naijiria, Rauf Arẹgbẹsọla ti n laago ikilọ tan tan tan fawọn ọmọ Naijiria pe ki wọn mase bọ ara wọn lọwọ lasiko yii nitori arun Coronavirus.
Aregbesola, ẹni to n lọgun pe igbọran san ju ẹbọ ruru lọ lasiko ifilọlẹ ibudo kan nilu Abuja, tun gba awọn araalu nimọran pe ki wọn mase so mọ ara wọn tabi bu ara wọn so lasiko yii, nitori ede ara kii sa fun ara, ti di ọrọ itan.

Oríṣun àwòrán, Ọjọgbọn Akin Ayọbami
"Ẹ mase bọ ẹnikẹni lọwọ, ẹ ma di mọ ẹnikẹni lasiko yii yatọ si mọlẹbi yin nikan, ẹ rin jinna bii ẹsẹ bata mẹta si ẹni to sun mọ yin."
Bakan naa ni minisita fọrọ abẹle tun rọ awọn ọmọ Naijiria lati maa tẹriba fun ara wọn ni, ki wọn si di ikuuku ọwọ mọ aya lati fi ki ara wọn.

O ni Coronavirus ti di ajakalẹ arun yika agbaye, gbogbo aayan si lo yẹ ka sa lati ri pe ko di isoro nla si wa lọrun lorilẹede yii.
"Ẹ jẹ ka sọra se nipa arun naa, ka si sisẹ tọ idaabo bo ara wa nitori ojuse wa ni lati maa fi oju sọri bii alakan.
Coronavirus báwọn lálejò nílé ìjọba Canada, aya olóòtú ilẹ̀ náà ló náwọ́ gán

Oríṣun àwòrán, Reuters
Aya Olootu ijọba ilẹ Canada, Sophie Gregoire Trudeau ni ayẹwo kan ti fihan pe o ti gba alejo kokoro Coronavirus ni agọ ara rẹ.
Atẹjade kan to wa lati ọọfisi olootu ijọba ilẹ Canada ọhun, Justin Trudeau sọ pe obinrin naa yoo si wa labẹ aabo fun akoko kan na, bi o tilẹ jẹ pe saka ni ara rẹ da, to si n gba itọju to yẹ lọwọ, ti ami kokoro naa ko si tii foju han.
Lọwọ lọwọ bayii, oun ati ọkọ rẹ ni wọn dijọ fi si igbele, ti Trudeau si wa ni ilera to peye lai jẹ pe ami kokoro Coronavirus foju han lara rẹ.
Amọ atẹjade naa ni ọjọ mejila gbako ni yoo fi wa ni igbele, ti ko si si aayan lati se ayẹwo rẹ boya o ni arun ọhun.
Ni orilẹede Canada, o ti to eeyan mẹtalelọgọrun ti arun Coronavirus naa ti n ba wọja ija.
Coronavirus tún ti bẹ́ gìjà sí Ghana àti Gabon
Akiri ma dale si arun Corona virus tun ti se ẹ n lẹ n bẹun si wọn lorilẹede Ghana, to si tun fi ẹsẹ kan ya ki wọn nilẹ Garbon, ti gbogbo wọn wa nilẹ Afirika wa niha-hin.

Minisita feto ilera lorilẹede Ghana, Kwaku Agyemang Manu kede pe eeyan meji ti wọn de sorilẹede naa lati ilẹ Norway ati Turkey ni wọn ni kokoro arun naa lara .
Lorilẹede Gabon n tiẹ, ẹni to ni kokoro naa lara jẹ ọmọ orilẹede naa amọ to sẹsẹ de lati orilẹede Faranse.
Wọ̀ kílùú mọ̀! Aṣojú Phillipine ti di ẹni àkọ́kọ́ tó ṣe onígbọ̀wọ́ Coronavirus wọ New York

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ayẹwo ti wọn se fun asoju orilẹede Phillipine ni New York lorilẹede Amẹrika ti fara han pe o ni kokoro arun Coronavirus, eyi tii se akọkọ arun naa ti yoo foju han ni olu ileesẹ ajọ isọkan orilẹede agbaye.
Gẹgẹ bi ileesẹ iroyin AFP ti kede rẹ, asoju naa yọju si ileesẹ ajọ isọkan agbaye lọjọ Aje, to si ba igbimọ kan sisẹ eyi to nii se pẹlu ọrọ ofin.
Awọn osisẹ to to ẹgbẹrun mẹta lo n sisẹ ni ibujoko ajọ isọkan orilẹede agbaye naa to wa nilu New York to si seese ki wọn fi wọn si abẹ ayẹwo pẹlu.













